Àwọn ajínigbé tí wọ́n gbé agbẹjọ́rò titun nnì ti kàn sí àwọn ẹbí rẹ̀, ogójì mílíọ̀nù náírà ni wọ́n bèèrè fún owó ìtúsílẹ̀.
Peace Onyesom ni orúkọ agbẹjọ́rò titun yìí, nígbà tí ó ń bọ̀ láti ibi ètò ìsọnidagbẹjọ́rò ni wọ́n jíi gbé ní òpópónà Okene sí Auchi.
Peace àti àbúrò rẹ̀ obìnrin tí wọ́n jọ lọ náà ni àwọn ajínigbé náà palẹ̀ mọ́ lójú ọ̀nà, wọ́n ti wá kàn sí àwọn ẹbí rẹ̀ báyìí pé bí wọ́n bá fẹ́ gbà á sílẹ̀, ogójì ẹgbẹ̀rún náírà ni wọn yóò san.
Àwọn ẹbí Peace rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àpapọ̀ lati ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Adaeze; ẹni tó jẹ́ àbúrò sí Peace ṣe àlá pé Gift ni orúkọ àbúrò tí òun àti Peace jọ lọ àwọn sì ń rí wọn bá sọ̀rọ̀ kó tó di pé wọ́n jí wọn gbé.
Wákàtí kan lẹ́yìn tí wọ́n ti wà lọ́nà ilé ni wọn kò rí wọn bá sọ̀rọ̀ mọ́, ẹnìkan ló gbé aago Gift tó sì wí pé ọlọ́pàá ni òun pé wọ́n ti jí àwọn èrò inú ọkọ̀ náà gbé.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn ajínigbé náà kàn sí àwọn mọ̀lẹ́bí náà pé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ni wọn yóò fi gba àwọn ọmọ náà sílẹ̀, Adaeze wí pé àwọn bẹ̀bẹ̀ títí pé kí wọn ó gba mílíọ̀nù mẹ́ta àmọ́ wọ́n kọ̀, wọ́n tún pè ní ọjọ́ Àìkú pé àwọn yóò gba ogún mílíọ̀nù jálẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan ní èyí tí àwọn méjèèjì yóò jẹ́ ogójì mílíọ̀nù.
Adaeze ṣe àlàyé síwájú síi pé àwọn mọ̀lẹ́bí ti ni gbé ìgbésẹ̀ àti ta àwọn dúkìá kan kí wọn ó le rí owó náà san.
Ní àtakò sí èyí, alukoro àgbà fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá; Benjamin Hundeyin kọ ọ́ sí ojú òpó X rẹ̀ pé àwọn ti gba mẹ́jọ nínú àwọn méjìlá tí wọ́n jí gbé lójú ọ̀nà Okene sí Auchi náà sílẹ̀, ó wí pé àwọn ṣì ń ṣiṣẹ́ lórí bí wọn yóò ṣe gba àwọn ìyókù kalẹ̀.
Ìwádìí ní ibùdókọ̀ tí ọkọ̀ náà ti gbéra fi hàn pé àwọn mẹ́jọ náà ni wọ́n wọ ọkọ̀ náà kìí ṣe méjìlá tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ.
Bákan náà ni àjọ NURTW tako ohun tí Benjamin sọ yìí, ó wí pé irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni, wọn kò gba ẹnìkankan sílẹ̀.
Àjọ àwọn agbẹjọ́rò ilẹ̀ yìí NBA bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi èyí tí kò ṣe é gbọ́ sétí, wọ́n wá rọ àwọn ọlọ́pàá láti ṣe àwárí àwọn ẹni náà.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa gbé akẹ́kọ̀ọ́ tàbí akẹ́kọ̀ọ́gboyè, kódà wọ́n ti gbé àgùnbánirọ̀ rí. Ọ̀kan lára àwọn tó ti ṣe àgbákò irú èyí ni Rofiat Lawal. Nígbà tó dé ló ròyìn pé:
Rofiat Lawal; agùnbánirọ̀ tí àwọn ajínigbé gbé ní Ore ti dé láti àkàtà wọn, ó ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́hùn-ún.
Mílíọ́nù márùn-ún náírà ni wọ́n fi gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi yìí.
Nínú àlàyé rẹ̀ ló ti sọ pé inú igbó ni wọ́n kó àwọn wọ̀, ìrìn àrìnwọ́dìí ni wọ́n rìn ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n fi wà níbẹ̀, gààrí sì ni wọ́n ń fún wọn jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Rofiat wí pé bí wọ́n ṣe lu àwọn yòókù tó, ìwọ̀n ìyà díẹ̀ ni òun jẹ. Ìdí ni pé ọ̀kan nínú wọn fẹ́ràn òun ó sì wí pé òun ó fẹ́ òun lọ sí Sokoto.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àjọ agùnbánirọ̀ pé kí wọn ó fún òun ní àkókò díẹ̀ láti sinmi àti láti gba ìtọ́jú kí òun tó padà sí ẹnu iṣẹ́.
Inú oṣù Ẹrẹ́nà la mú ìròyìn wá pé wọ́n gbé Rofiat Lawal; ẹni tó jẹ́ agùnbánirọ̀ nígbà tó ń padà bọ̀ wá sí Ògbómọ̀ṣọ́ tó ti ń sìnlú pé ‘Àgùnbánirọ̀ ni Rofiat Lawal, ìlú Ogbomosho ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó ti ń sin ilẹ̀ bàbá rẹ̀, Ogbomosho náà ló ń lọ tí àwọn ajínigbé fi gbé e lójú ọ̀nà Benin sí Ìbàdàn.
Rofiat lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo, Ogbomosho níbi tó ti ń sìnlú ló ń padà sí tí àwọn ajínigbé fi gbé e lọ.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agbakwara ṣe àlàyé pé Rofiat pe òun láti àkàtà àwọn ajínigbé náà pé kí òun ó bá òun wá ogún mílíọ̀nù náírà owó ìtúsílẹ̀.
Agbakwara ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn òbí Rofiat kò là bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ṣagbe, ìbo ni kí wọ́n ti rí adúrú owó náà?
Aminat Lawal, ẹni tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Rofiat bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé Rofiat pè lórí aago tó sì ń sunkún pé kí wọn ó bá òun tu owó ìtúsílẹ̀ náà. Ogún mílíọ̀nù náírà ni wọ́n bèèrè fún àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ ti gba sí mílíọ̀nù márùn-ún náírà.
Aminat rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo ọmọ Nàìjíría láti má dá àwọn dá èyí kí wọn ó dákun dábọ̀ fi iye tí wọ́n bá ní ránṣẹ́ kí wọn ó le gba Rofiat kalẹ̀.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé nínú ọ̀rọ̀ tí Rofiat sọ ni wọ́n ti ríi dì mú pé awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajinigbe lọ́wọ́.
Èrò Ìbàdàn ni ọkọ̀ náà kó láti Benin, bó ṣe dé Ore ló dúró tí àwọn ajinigbe ọ̀hún sì jáde láti inú igbó. Fúnra awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajínigbé náà lọ́wọ́ tó sì bá tirẹ̀ lọ.
Aminat ṣe àlàyé pé àwọn ti kàn sí àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ èsì tí àwọn gbà náà ni pé Rofiat kò gba ìyànda tó fi lọ sí ilé, wọ́n ní àwọn ti ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn àgùnbánirọ̀ láti máa gba ìyànda bí wọ́n bá fẹ́ lọ sí ilé tàbí rin ìrìnàjò kankan.
Àjọ àgùnbánirọ̀ wí pé àwọn ti da àwọn ẹ̀ṣọ́ síta láti wá ọmọ náà jáde.
Ìjínigbé kìí ṣe ìròyìn mọ́ lórílẹ̀-ède Nàìjíríà, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbé àwọn èèyàn bí ìgbà tí wọ́n bá gbé ewúrẹ́. Kò fẹ́rẹ̀ sí ibi tí ààbò ti péye mọ́ nílùú yìí, Nàìjíríà wá di kóńkó jabele; kálukú ń ṣe tirẹ̀’
A bá Rofiat Lawal dúpẹ́ a sì bá a yọ̀, kò wọ́pọ̀ ẹni tó ní àǹfààní àtibọ̀, kí Olódùmarè ó jẹ́ kí Peace àti àbúrò rẹ̀ náà ó bọ̀ láyọ̀. Àṣẹ.





