Àwọn ọlọ́pàá abẹ́lé NSCDC ti mú àwọn mẹ́fà kan tí wọ́n lọ hú òkú ọjọ́ kejì ní ìpínlẹ̀ Gombe.
Ìjọba ìbílẹ̀ Kwami ní ìpínlẹ̀ Gombe ni èyí ti ṣẹ̀, orúkọ àwọn mẹ́fà náà ni Adamu Umar; ẹni ọdún méjìlélógún, Umar Jibrin Aboki; ẹni ọdún mọ́kànlélógún, Abdullahi Umar Dauda; ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún, Muhammad Issa Chindo; ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, Kawuji Sarki; ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì àti Manu Sale; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún.
Nǹkan bíi aago mẹ́wàá sí mọ́kànlá alẹ́ ọjọ́ kọkànlá, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ wọ́n níbi tí wọ́n ti ń hú òkú náà.
Òkú Mallam Manu Wanzam; ẹni tó kú lẹ́ni ọdún márùndínláàdọ́rùn-ún ni àwọn mẹ́fà yìí lọ hú ní ọjọ́ kẹta tí wọ́n sin ín.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Gombe; Buhari Saad ṣe, Kawuji Sarki ló pe àwọn yòókù mọ́ra pé kí àwọn ó lọ hú òkú náà láti ta àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà ni wọn yóò ta ojú kọ̀ọ̀kan.
Wọ́n ti yọ àwọn ojú òkú náà wọ́n sì ti sin ín padà kí àwọn ọlọ́pàá tó mú wọn.
Márùn-ún ni wọ́n rí mu nígbà tí ọ̀kan na pápá bora.
Jibrin Idris; ẹni tó jẹ́ adarí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Gombe bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó wí pé yàtọ̀ híhú òkú tàpǎ sí òfin orílẹ̀-èdè wa Nàìjíríà ó sì tún tako ẹ̀sìn.
Jibrin ké sí àwọn ará ìpínlẹ̀ Gombe láti fi gbogbo ìrìn tí wọ́n bá fura sí tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Lọ́dún tó kọjá ni a mú ìròyìn tó fara pẹ́ èyí nípa àwọn tó ń hú òkú tà yìí.
A kọ nípa Muyideen Raimi tó lọ hú òkú ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé:
Muyideen Raimi lọ sí sàrê ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Sulaiman Aromokun ní isale Ijebu, Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Inú ọgbà ilé mọ̀lẹ́bí Aromokun ni wọ́n sin ọmọ náà sí kí Raimi ó tó lọ hú u jáde tó sì gé orí rẹ̀ lọ. Ọ̀rẹ́ rẹ̀; Sumaila tí wọ́n jọ hú orí ọmọ náà fẹsẹ̀ fẹ́ẹ nígbà tí àṣírí wọn tú.
Nínú ọdún yìí ni ọwọ́ tẹ Adelani tijani ní Obada:
Adelani Oriyomi; ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ni ọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé ìpínlẹ̀ Ogun So-safe tẹ̀ níbi tó ti hú orí òkú jáde nínú sàrê rẹ̀.
Itẹ́ òkú tó wà ní Kere, Obada oko ní Abeokuta tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun ni ọwọ́ ti tẹ Oriyomi o.
Ní òru ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Ṣẹẹrẹ yìí ni Adelani kó àwọn irin iṣẹ́ rẹ̀ lọ sí itẹ́ náà láti ṣe bíi ìṣe rẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ So-safe kófìrí rẹ̀ wọ́n sì tẹ̀lé e, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ́ sàrê náà, ìgbà tó yá, ó dáwọ́ dúró nítorí ó fura pé àwọn kan ń ṣọ́ òun, nígbà tó ríi pé ilẹ̀ dá ló tẹ̀ síwájú tó sì hú orí òkú náà jáde.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ So-safe jáde síi, lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ.
Adelani ní kí wọn ó má wulẹ̀ làágùn jinna, ẹ̀wọ̀n kìí ṣe àjojì sí òun, bíi ìgbà tí èèyàn lọ sí ẹsìkọ́ṣọ́nù ni ọgbà ẹ̀wọ̀n ṣe jẹ́ fún òun nítorí pé òun ti ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún méjì kan àti ọdún mẹ́fà kan rí lórí pé òun hú orí àwọn òkú yìí kan náà.
Adelani ṣe àlàyé pé àwọn oníbàárà òun ló béèrè fún ọjà ni òun ṣe lọ hú èyí mọ́ èyí tó wà nílẹ̀ láti le tàá fún wọn.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé òun kò mọ iṣẹ́ mìíràn ṣe ju kí òun ó hú orí òkú tà lọ. Ó ti pẹ́ tí ó ti ń ṣe é ó sì ti ta orí bíi mẹ́wàá láàrin ọdún tó kọjá sí ìsìn yìí.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ So-safe ti fa Adelani lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ pẹ̀lú orí òkú tó hú náà, wọ́n ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn onílé láti máa ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí àwọn ayálégbé tí wọ́n bá fẹ́ gbà sílé.
Wọ́n tún wà ní ìlú Ìbàdàn:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ arákùnrin kan tó máa ń hú òkú tà ní ìlú Ìbàdàn:
Àwọn kan ló ta àwọn ọlọ́pàá lólobó tí wọ́n fi lọ ṣe àbẹ̀wò sí ilé rẹ̀ tó wà ní Muslim, oríṣìí nǹkan ni wọ́n bá nílé rẹ̀, wọ́n bá orí obìnrin kan àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrùn ọwọ́ àti àwọn eegun gbígbẹ mìíràn wọ́n bá nínú ike ọ̀dà tó tọ́jú ẹ̀ sí nínú ilé rẹ̀ tó ń gbé náà.
Okùnrin yìí jẹ́wọ́ wí pé òun ṣẹṣẹ̀ hú òkú obìnrin náà ní itẹ́ òkú kan tó wà ní Awa-Ijebu ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Ijebu ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn ọlọ́pàá tẹ̀lé arákùnrin yìí dé itẹ́ òkú náà wọ́n sì ríi pé ibẹ̀ ló ti hú òkú obìnrin náà lóòótọ́.
Bákan náà ló ka èkejì rẹ̀ tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ náà.
Èkejì rẹ̀ yìí náà jẹ́wọ́ pé àwọn jọ ń hú òkú tà ni àwọn sì ní àwọn oníbàárà tó pọ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn aláṣẹ itẹ́ òkú Awa-Ijebu náà láti pèsè ààbò tó nípọn sí ibẹ̀, bákan náà ni wọ́n tari àwọn afurasí méjèèjì náà lọ sí ẹ̀ka tọ́rọ̀ kàn.
Adekola kò le dúró kí èèyàn ó kú kí ó tó tá á ní tirẹ̀:
Nínú oṣù Ògún ni wọ́n tan Adekola Sofiq lọ sí Moniya tí wọ́n sì pá á, wọ́n ta orí àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà fún Rashidat Akanji; ẹni tó ní ìsọ̀ sí ọjà Oje.
Nínú ilé Adekunle ni wọ́n ti bá àwọn ẹ̀yà ara Adekola tó kù níbi tó ṣe é lọ́jọ̀ sí. Adekunle jẹ́wọ́ pé òun ti gíríkì nínú iṣẹ́ apanità tó ṣe pé òun kò mọ nǹkan mìíràn ṣe mọ́.
Lára àwọn oníbàárà rẹ̀ tó dárúkọ ni Muniru Salawudeen, Rashidat Akanji àti Obaleye Sanmi. Wọ́n jẹ́wọ́ pé kọ́sítọ́mà dáadáa ni Adekunle, kò sí ẹ̀yà ara tí àwọn fẹ́ tí kò ní. Nínú oṣù Ògún ni wọ́n tan Adekola Sofiq lọ sí Moniya tí wọ́n sì pá á, wọ́n ta orí àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì ní àádọ́rin ẹgbẹ̀rún náírà fún Rashidat Akanji; ẹni tó ní ìsọ̀ sí ọjà Oje.
Nínú ilé Adekunle ni wọ́n ti bá àwọn ẹ̀yà ara Adekola tó kù níbi tó ṣe é lọ́jọ̀ sí. Adekunle jẹ́wọ́ pé òun ti gíríkì nínú iṣẹ́ apanità tó ṣe pé òun kò mọ nǹkan mìíràn ṣe mọ́.
Lára àwọn oníbàárà rẹ̀ tó dárúkọ ni Muniru Salawudeen, Rashidat Akanji àti Obaleye Sanmi. Wọ́n jẹ́wọ́ pé kọ́sítọ́mà dáadáa ni Adekunle, kò sí ẹ̀yà ara tí àwọn fẹ́ tí kò ní




