Àwọn ẹbí Moses Mba ti tọ ìjọba ìpínlẹ̀ CrossRiver lọ láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ wọn.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver; Bassey Otu pé àwọn ló lu Moses pa.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Moses Mba; ẹni ọdún mọ́kànlélógún lọ sí ilé Gómìnà Bassey lọ́jọ́ kìíní, oṣù Ògún pé òun fẹ́ jíṣẹ́ Olúwa fún Gómìnà náà.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà lu Moses lálùbami en sì tún yìnbọn fún un.
Ilé ìwòsàn Naval Reference Hospital tó wà ní Calabar ni wọ́n gbé e lọ kí wọ́n tó pe àwọn òbí rẹ̀.
Ìyá Moses ṣe àlàyé síwájú síi pé ọmọ òun jẹ́ ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ Red Cross, àwọn ni wọ́n sì san owó ìtọ́jú rẹ̀ tó fi wá padà kú lọ́jọ́ kẹsàn-án.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey yí ilé ìwòsàn náà po títí tó fi kú wọ́n sì tún gbìyànjú àti gbé òkú rẹ̀ lẹ́yìn tó kú tán.
Ìyá Moses; Victoria wí pé láti ìgbà tí Moses ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ló ti máa ń ríran, iṣẹ́ Olúwa ló fẹ́ jẹ́ fún Gómìnà Bassey tí wọ́n fi pa á yii.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ CrossRiver ṣe tako èyí tí àwọn ẹbí Moses ṣe yìí. Kọ́míṣọ́nà fún ìfitónilétí; Erasmus Ekpang wí pé Moses ní ààrùn ọpọlọ, ó lọ sí ilé tí Gómìnà ń gbé tẹ́lẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò lu àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé náà.
Ekpang wí pé Moses tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà nígbà tí ara rẹ̀ balẹ̀ tán ó sì kúrò níbẹ̀, ó bu ẹnu àtẹ́ lu lílù tí wọ́n lu Moses àti bí wọ́n ṣe yìnbọn fún un àmọ́ ó wí pé kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Gómìnà Bassey.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ CrossRiver náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó wí pé àwọn ti darí ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń gbọ́ ẹjọ́ aráàlú, ohun tí wọ́n bá sọ níbẹ̀ ni àwọn yóò ṣe.
Kò tán síbẹ̀ o, Victoria wí pé ọmọ òun kò ní ààrùn ọpọlọ, ó yege nínú ìdánwò WAEC ó sì gba máàkì mẹ́rìndínnígba nínú ìdánwò JAMB.
Ẹ̀kọ́ nípa òwò ṣíse ni Moses fẹ́ kọ́ ní ilé ìwé gíga Calabar kó tó kú yìí. Bákan náà ló wí pé láti ìgbà tí ọmọ òun ti kú ni àwọn ẹ̀ṣọ́ náà pàápàá Emmanuel Dickson ti ń dùnkokò mọ́ ìdílé òun pé gbogbo wọn ni yóò lọ bá Moses lọ́run bí wọn kò bá pa ẹnu wọn mọ́.
Ní ìpínlẹ̀ Èkó:
Agbẹjọ́rò kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Festus Ogun tó sì tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn ti pe Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu lẹ́jọ́ báyìí.
Ẹ̀sùn tó fi kàn án náà ni pé ó dí òun lójú òpó X rẹ̀ láti ọdún 2021.
Festus ṣe àlàyé pé ìdí tí Sanwoolu fi dí ojú òpó òun lójú òpó rẹ̀ ni pé òun máa ń ṣe ọ̀fintótó ìṣèjọba rẹ̀ pàápàá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé ní ẹnu ìloro Lekki nígbà ìwọ́de Endsars.
Ó wí pé nítorí ìtọpinpin òun lórí Endsars yìí gan-an ni Sanwoolu fi dí ojú òpó láti ọdún náà. Ohun tí Gómìnà Sanwoolu ṣe yìí kò fún òun ní ànfààní láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílé iṣẹ́ Gómìnà èyí sì tàpá bá ẹ̀tọ́ òun nínú ìwé òfin ilẹ̀ yìí.
Ní báyìí, ó ti pe Sanwoolu lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkó lórí ẹ̀sùn yìí.
Ní ìpínlẹ̀ Edo:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo; Monday Okpebohlo dóòlà ẹ̀mí àwọn èèyàn tó ní ìjàmbá ọkọ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Benin sí Auchi nígbà tí ó ń kọjá lọ.
Gómìnà ń lọ nínú ọkọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn rẹ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Benin sí Auchi nígbà tí ó ko súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ lọ́nà, ó sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ nígbà tó ríi pé ìjàmbá ọkọ̀ ló fa súnkẹrẹ náà, àwọn èèyàn tó wà ní itòsí kàn ń wo àwọn ẹni náà níran ni wọn kò ṣe ìrànwọ́ fún wọn.
Gómìnà Monday pàṣẹ kí wọn ó gbé àwọn èèyàn náà lọ sí ilé ìwòsàn pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ rẹ̀ ó sì dúró títí wọ́n fi gbé gbogbo wọn lọ sí ilé ìwòsàn tó wà ní itòsí kó tó tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò rẹ̀
Ká fi ìròyìn òkèrè kásẹ̀ ńlẹ̀:
Equatorial Guinea:
Orílẹ̀-èdè Equatorial Guinea ti sọ Baltasar Egonga sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ lórí ẹ̀sùn pé ó kó owó ìlú jẹ.
Baltasar ni ó di ìlúmọ̀ọ́nká ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí àwọn fọ́nrán bí ó ṣe ń bá àwọn ìyàwó oníyàwó lò pọ̀ tú síta.
Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ gbáko ni ìjọba Guinea sọ Baltasar sí báyìí lórí ẹ̀sùn pé ó kó owó ìlú jẹ, àpò rẹ̀ ló kó àwọn owó tó gbà fún ìlò ìlú sí.
Adájọ́ Hilario Mitogo pàṣẹ lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjare pé kí Baltasar ó lọ gbatẹ́gùn ọdún mẹ́jọ gbáko lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí pé ó jẹ̀bi.
Bákan náà ni a gbọ́ pé ìjọba Guinea ti gbé àkọ́bí Baltasar lórí ẹ̀sùn pé ó ta ọkọ̀ òfurufú ìlú fún ilé iṣẹ́ aládàáni, ìgbẹ́jọ́ tirẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ báyìí.
USA:
Ọkùnrin kan tí àwọn ọlọ́pàá ti ń lépa rẹ̀ báyìí ni ó lọ sí ojú fèrèsé ilé ìjọsìn náà tó sì da ìbọn bo àwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀, méjì ló kú nínú àwọn ọmọ yìí nígbà tí àwọn mẹ́rìnlà mìíràn fara pa.
Ilé ìjọsìn Minneapolis ní Amẹ́ríkà ni èyí ti ṣẹlẹ̀
A gbọ́ pé ilé ìwé wà nínú ọgbà ilé ìjọsìn náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà nínú ilé ìjọsìn láti ṣe ìsìn ìwọlé sáà titun ni ọkùnrin náà yìnbọn fún wọn láti ojú fèrèsé ilé ìjọsìn náà.
Àwọn ọlọ́pàá Minneapolis ti ń lépa afurasí yìí.




