Ọkọ̀ ojú irin tó kó èrò láti Abuja lọ sí Kaduna ti dànù lójú ọ̀nà láàárọ̀ yìí, ọkọ̀ ojú irin yìí yà bàrà kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ̀; àwọn ọkọ̀ àsomọ́ rẹ̀ fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.
Àwọn èrò inú ọkọ̀ yìí rí fìrífìrí ọ̀run nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà fi ẹgbẹ́ lélẹ̀, àyà wọn já, ìbẹ̀rùbojo sì bá wọn.
Àwọn èrò náà ṣe àlàyé pé òjijì ni ọkọ̀ náà yà bàrà kúrò lójú ọ̀nà rẹ̀ ní èyí tó mú kí àwọn ọkọ̀ àsomọ́ rẹ̀ ó fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, àwọn èrò náà sáré du ara wọn jáde nínú rẹ̀.
Àwọn èèyàn mẹ́fà ni ó fara pa, kò tíì sí ẹni tó kú lásìkò yìí àmọ́ àwọn èèyàn kan ṣì há sínú àwọn ọkọ̀ náà.
Adarí ilé iṣé ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ yìí; Kayode Opeifa fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn , ó ni òun kò tíì le ṣe àlàyé rẹpẹtẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àmọ́ ohun tí òun le fìdí ẹ̀ múlẹ̀ ni pé ọkọ̀ náà dànù lóòótọ́.
A kò tíì le sọ pàtó ohun tó ṣe okùnfà dídànù ọkọ̀ yìí àmọ́ ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin ti ń ṣètò bí wọn yóò ṣe kó àwọn èrò náà padà sí Abuja.
A TI MÚ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ MẸ́RIN TÍ WỌ́N Ń KA OWÓ NÁÀ – ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ DELTA.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta wí pé àwọn ti mú àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tí wọ́n hàn nínú fọ́nrán kan tó gbòde níbi tí wọ́n ti ń ka owó.
Nínú fọ́nrán náà la ti rí àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin náà tí wọ́n ń ka owó nínú ọkọ̀ wọn tí wọ́n sì ń pín owó náà láàárín ara wọn.
Àwọn èèyàn fi ẹ̀sùn kàn wọ́n lórí ìtàkùn ayélujára pé owó tí wọ́n lọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́ gbà lọ́jọ́ náà ni wọ́n ń pín.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ti fèsì báyìí pé àwọn ti mú àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin náà wọ́n sì ti fara hàn níwájú kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta láti ṣe àlàyé bí owó náà ṣe jẹ́.
Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn ọlọ́pàá àgbà méjì tó wà nínú wọn ti gba ìwé ìfisùn nígbà tí àwọn méjì yòókù ti wà ní àhámọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò dé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà àwọn yóò sì fi wọ́n jófin.
OBÌNRIN KAN KÚ SÍLÉ Ọ̀RẸ́KÙNRIN RẸ̀ NÍ ESA-OKE.
Obìnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Bidemi Omole ti kú sí ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tó wà ní Esa-oke, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Bidemi ń lọ sí àìsùn nílé ìjọsìn lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì ló ya ọ̀dọ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, kò pẹ́ tó dé ibẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀fìnkìn tó sì kú.
Ariwo ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ni àwọn ará ilé àti àdúgbò fi sáré dé ibẹ̀ àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró, Bidemi ti dágbére fáyé.
Ará ilé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Taye ṣe àlàyé pé àwọn èrò sáré dé ibẹ̀, òkú Bidemi ni wọ́n bá, wọ́n pe àwọn ọlọ́pàá tó wá mú ọ̀rẹ́kùnrin Bidemi náà lọ.
Abiodun Ojelabi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀, wọ́n gbé Bidemi lọ sí ilé ìwòsàn fún àrídájú wọ́n sì fi òfin mú ọ̀rẹ́kùnrin Bidemi náà.
Àlàyé tí ọ̀rẹ́kùnrin Bidemi ṣe náà ni pé lọ́gán tí Bidemi dé sí ilé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní bì tó sì kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò ṣe àyẹ̀wò òkú Bidemi láti mọ irú ikú tó pa á ní pàtó.
ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ṢE ÀWỌN ÀGÙNBÁNIRỌ̀ NÍṢEKÚṢE.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ Agunechemba ya wọ ilé ìgbé àwọn àgùnbánirọ̀ obìnrin ní ìpínlẹ̀ Anambra, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára tí a mọ̀ sí yàhú ni wọ́n ń ṣe.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí na àwọn àgùnbánirọ̀ náà wọ́n tún já ọ̀kan sí ìhòhò.
Àwọn àgùnbánirọ̀ yìí fi káàdì ìdámọ̀ wọn han àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí àmọ́ wọn kò bìkítà, wọ́n ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú.
Orúkọ àgùnbánirọ̀ tí wọ́n fìyà jẹ jù tí wọ́n tún já sí ìhòhò ni Jennifer Elobor.
Ọjọ́ ìṣẹ́gun ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, fọ́nrán náà gbòde kan ní kíákíá.
Nínú fọ́nrán yìí ni a ti rí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà tí wọ́n jẹ́ mẹ́jọ níye, wọ́n lu àwọn àgùnbánirọ̀ obìnrin yìí lálùbami àmọ́ Jennifer ni wọ́n lù jù.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwuma Soludo ti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó pàṣẹ kí wọn ó gba aṣọ lọ́rùn àwọn mẹ́jọ náà kí wọn ó sì fà wọ́n lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
LADOJA YÓÒ GUN ORÍ ÌTẸ́ OLÚBÀDÀN NÍ OṢÙ ỌWẸ́WẸ̀.
Ọba Rashidi Ladoja; ẹni tí ipò Olúbàdàn kàn yóò jẹ oyè náà ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Ọwẹ́wẹ̀ tó ń bọ̀ yìí.
Olúbàdàn Ladoja ni yóò jẹ́ Olúbàdàn kẹrìnlélógójì báyìí tí yóò jẹ ní ìlú Ìbàdàn.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Seyi Makinde ti fọwọ́ sí kí Ladoja ó gun orí ìtẹ́ náà.
Àwọn afọbajẹ ìlú Ìbàdàn àti àwọn ìgbìmọ̀ tí ọ̀rọ̀ kàn ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ladoja ní ilé rẹ̀ tó wà ní Bódìjà lórí bí gbogbo ètò yóò ṣe tò.
A kí gbogbo ọmọ ìlú Ìbàdàn kú ojúlọ́nà.
ATẸ́GÙN ÒJÒ DA Ọ̀PỌ̀ ILÉ WÓ NÍ ÌPÍNLẸ̀ PLATEAU.
Òjò tó rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Plateau fẹ́ atẹ́gùn tó le débi pé ó da ọ̀pọ̀ ilé wó ó sì tún fa géètì ilé ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Jos ya.
Agbègbè Bukuru ni èyí ti ṣẹ̀ , ọ̀pọ̀ ilé ni atẹ́gùn náà fa òrùlé rẹ̀ yọ tó sì tún dà wó.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Jos, Silas Dung wí pé atẹ́gùn náà le gidi gan-an tó fi yọ igun géètì ilé ìjọba ìbílẹ̀ náà mẹ́rẹ́ẹ̀rin, ó da géètì náà wó lulẹ̀, àwọn òpó tó gbé e ró náà ṣẹ́ lórí òró.
Dung ṣe àbẹ̀wò sí agbègbè náà, ilé mẹ́fà ló wó lulẹ̀ nígbà tí ó yọ òrùlé àwọn yòókù.




