Ọ̀gágun àgbà ilẹ̀ wa; Christopher Musa ti gbóhùn sókè lórí ọ̀rọ̀ tó sọ níjelòó pé kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó lọ kọ́ ìjà tí wọ́n fi le gba ara wọn kalẹ̀.
Ó wí pé kí àwọn èèyàn ó má ṣi òun gbọ́, òun kò ní kí ẹ lọ ra ìbọn, ìjà ìgbara-ẹnikalẹ̀ ni òun ní kí ẹ lọ kọ́.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí ‘ mo ti ṣe àkíyèsí ìhà tí àwọn èèyàn kọ sí ohun tí mo sọ àti bí wọ́n ṣe ń tan ọ̀rọ̀ náà ká, mi ò sọ pé kí ẹ lọ máa ra ìbọn nítorí ètò ààbò tó mẹ́hẹ, ohun tí mo sọ náà ni pé kí ẹ kọ́ àwọn ìjà ìgbara-ẹnikalẹ̀ bíi Taekwondo kí ẹ le kojú àwọn ajínigbé.
Òfin kò fi ààyè gba kí èèyàn ó ní ìbọn lọ́nà àìtọ́, ẹ má ṣì mí gbọ́’
Ọ̀sẹ̀ yìí ni a mú ìròyìn wá nípa ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí Ọ̀gágun Christopher Musa ṣe lórí ìkànnì ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán Channels níbi tó ti sọ wí pé kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó kọ́ ìjà láti dáàbò bo ara wọn nínú ètò ààbò tó dẹnu kolẹ̀ yìí.
Ìròyìn náà lọ báyìí:
Ọ̀gágun àgbà ilẹ̀ wa; Christopher Musa ti gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nímọ̀ràn pé kí wọn ó kọ́ bí wọ́n ṣe le gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé àti agbésùnmọ̀mí nítorí bí ètò ààbò ilẹ̀ wa ṣe mẹ́hẹ.
Ọ̀gágun Christopher Musa sọ èyí lórí ètò tí wọ́n ti ń sọ ọ̀rọ̀ ààbò ní ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels ní Ọjọ́bọ ọ̀sẹ̀ yìí.
Ó wí pé òun gba àwọn ọmọ Nàìjíríà lámọ̀ràn kí wọn ó kọ́ àwọn ìjà ìgbara-ẹnikalẹ̀ bii Karate, Taekwondo and Judo kí wọn ó le gba ara wọn kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé àti agbésùnmọ̀mí nítorí bíi ọ̀rọ̀ ààbò ìlú yìí ṣe dẹnukọlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ‘bí ìlú tilẹ̀ fara rọ gan-an, àwọn ìmọ̀ báyìí wúlò fún èèyàn nítorí bí yóò bá ṣẹlẹ̀, àwọn ìlú tó tùbà tùṣẹ gan-an kàn án nípá fún àwọn èèyàn wọn láti kọ́ àwọn ìjà yìí.
Mà á tún dá a lábàá kí àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC ó ṣe àfikún kíkọ́ àwọn ìjà yìí sínú ètò wọn kí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́gboyè ó le dá ara wọn gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Ó ṣe pàtàkì kí àwọn èèyàn ó mọ bí wọ́n ṣe le gba ara wọn sílẹ̀, kí wọn ó mọ ọkọ̀ ọ́ wà, kí wọn ó mọ odò ó wẹ̀ nítorí pé ayé tí a wà lásìkò yìí ti gbẹgẹ́.
Àsìkò ti tó fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ní àwọn ìmọ̀ yìí nítorí ọjọ́ ọ̀la. Àwọn èèyàn ibi ti pọ̀ lóde lásìkò yìí, wọ́n le pa èèyàn láìní ìdí kankan, irú àwọn nǹkan báyìí ni a fi le gba ara wa sílẹ̀ lọ́jọ́ ìjà.
Ọ̀gágun Christopher Musa gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú rírọ gbogbo àwon ọmọ Nàìjíríà láti mú ọ̀rọ̀ ààbò agbègbè wọn lọ́kùnǹkúndùn kí wọ́n sì máa kíyèsí ojú titun tó bá wọ agbègbè wọn wá.
Ní báyìí, Ọ̀gágun Christopher Musa ti padà wá ṣe àlàyé pé kí a má ṣi òun gbọ́ ọ, òun kò ní kí ẹ ra ìbọn o.
Lórí ọ̀rọ̀ ààbò yìí, ipa wo ni ilé iṣẹ́ ológun ń kó?
Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí kò fi àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́kàn balẹ̀, gbogbo ìgbà ni wọ́n ń fi imú wọn dánrin.
Lára àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe láti kojú wọn náà ni pípa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji.
Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí, ẹ̀ka àwọn jagunjagun ojú òfurufú ti kéde pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ nínú ìkọlù tí àwọn ṣe sí ibùdó wọn.
Bello Turji ni ògbólògbó agbésùnmọ̀mí tó ń da ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara àti Kastina láàmú, gbogbo àwọn ìkọlù tó nípọn tó ń wáyé ní Sokoto àti àwọn ìlú tó yíi ká kò ṣẹ̀yìn rẹ̀, ó ti pẹ́ tí àwọn ológun ti ń lépa Bello Turji tí wọn kò ríi mú.
Àmọ́ báyìí, ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shaudo Alku pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀. Ìbùdó àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní ìtòsí ilé ìwé ìjọba alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Tunfa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.
Shaudo Alku wá sí Sokoto láti ilẹ̀ Nìjéè wá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àṣe Bello Turji. Shaudo ni ó máa ń kó àwọn ohun ìjà olóró wọlé fún Bello láti ilẹ̀ òkèrè.
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn agbésùnmọ̀mí yòókù tó na pápá bora. Wọ́n ní Shaudo tí àwọn pa yìí yóò da ètò àwọn agbésùnmọ̀mí náà rú wọn kò sì ní le rí àwọn ohun ìjà olóró lò mọ́ nítorí pé Shaudo náà ni ó máa ń kó wọn wọlé. Àṣeyọrí ńlá ni ikú Shaudo jẹ́ àmọ́ bí wọn ó bá rí àwọn agbésùnmọ̀mí náà mú délẹ̀, dandan ni kí orílẹ̀-ède Nìjéè àti Chad ó fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà.
Àwọn ará Isa ní Sokoto fèsì sí èyí, wọ́n ní àwọn yóò tilẹ̀ ní ìsinmi lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí pẹ̀lú ikú Shaudo yìí. Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn kò ní sinmi lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Mínísítà fún ètò ààbò; Bello Matawalle ṣe àlàyé pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kò ní fi ààyè gba àwọn agbésùnmọ̀mí nínú ìṣèjọba rẹ̀.
Ó wí pé:
Igba mẹ́rin ni àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn ti pa lásìkò ìṣejọba Tinubu yìí.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn agbékalẹ̀ titun tí ìṣejọba Tinubu gbé kalẹ̀ ni àwọn fi ń kojú àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn sì ń mú wọn balẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ìṣọwọ́ gbógun ti àwọn agbésùnmọ̀mí yìí tó ìdí tí a fi gbọdọ̀ dìbò yan ààrẹ Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le bá àwọn agbésùnmọ̀mí náà kanlẹ̀ pátápátá.
Mínísítà fún ètò ààbò wa wí pé àwọn ti ṣe àgbékalẹ̀ ikọ̀ tí ó ń gbógun ti àwọn ajínigbé tí wọ́n ń fi imú wọn danrin ní èyí tó mú kí ìjínigbé ó di ohun ìgbàgbé báyìí. Bákan náà ni ó wí pé àwọn àlàkalẹ̀ ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò yẹ ní ohun tí ó yẹ kó gba oríyìn fún nítorí pé yàtọ̀ sí àwọn agbésùnmọ̀mí ẹgbẹ̀rin tí àwọn ti pa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró ni àwọn ti rí gbà padà lọ́wọ́ wọn.



