Ọ̀gágun àgbà ilẹ̀ wa; Christopher Musa ti gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nímọ̀ràn pé kí wọn ó kọ́ bí wọ́n ṣe le gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé àti agbésùnmọ̀mí nítorí bí ètò ààbò ilẹ̀ wa ṣe mẹ́hẹ.
Ọ̀gágun Christopher Musa sọ èyí lórí ètò tí wọ́n ti ń sọ ọ̀rọ̀ ààbò ní ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels ní Ọjọ́bọ ọ̀sẹ̀ yìí.
Ó wí pé òun gba àwọn ọmọ Nàìjíríà lámọ̀ràn kí wọn ó kọ́ àwọn ìjà ìgbara-ẹnikalẹ̀ bii Karate, Taekwondo and Judo kí wọn ó le gba ara wọn kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé àti agbésùnmọ̀mí nítorí bíi ọ̀rọ̀ ààbò ìlú yìí ṣe dẹnukọlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ‘bí ìlú tilẹ̀ fara rọ gan-an, àwọn ìmọ̀ báyìí wúlò fún èèyàn nítorí bí yóò bá ṣẹlẹ̀, àwọn ìlú tó tùbà tùṣẹ gan-an kàn án nípá fún àwọn èèyàn wọn láti kọ́ àwọn ìjà yìí.
Mà á tún dá a lábàá kí àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC ó ṣe àfikún kíkọ́ àwọn ìjà yìí sínú ètò wọn kí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́gboyè ó le dá ara wọn gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Ó ṣe pàtàkì kí àwọn èèyàn ó mọ bí wọ́n ṣe le gba ara wọn sílẹ̀, kí wọn ó mọ ọkọ̀ ọ́ wà, kí wọn ó mọ odò ó wẹ̀ nítorí pé ayé tí a wà lásìkò yìí ti gbẹgẹ́.
Àsìkò ti tó fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ní àwọn ìmọ̀ yìí nítorí ọjọ́ ọ̀la. Àwọn èèyàn ibi ti pọ̀ lóde lásìkò yìí, wọ́n le pa èèyàn láìní ìdí kankan, irú àwọn nǹkan báyìí ni a fi le gba ara wa sílẹ̀ lọ́jọ́ ìjà.
Ọ̀gágun Christopher Musa gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú rírọ gbogbo àwon ọmọ Nàìjíríà láti mú ọ̀rọ̀ ààbò agbègbè wọn lọ́kùnǹkúndùn kí wọ́n sì máa kíyèsí ojú titun tó bá wọ agbègbè wọn wá.
Ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gágun Christopher Musa sọ yìí tako ọ̀rọ̀ tí ààrẹ sọ nípa ipò tí orílẹ-èdè Nàìjíríà wà.
Ààrẹ wí pé Nàìjíríà ti dára pé kò sí ogun tàbí ìfẹ̀míṣòfò mọ́, Ọ̀gágun wí pé àfi ká gbara wa sílẹ̀.
Ká tó mọ ẹni tí a ó gbàgbọ́, ẹ jẹ́ ká ka ohun tí ààrẹ sọ na:
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tí wọ́n jápa lọ sí òkè òkun pé kí wọn darí wálé, àjò kìí dùn bí ilé àti wí pé ilé náà làbọ̀ ìsinmi oko.
Ó wí pé orílẹ-èdè Nàìjíríà ti kúrò ní bí wọ́n ṣe fi sí nígbà tí wọ́n jápa lọ sí òkè òkun, Nàìjíríà ti dára gan-an ni ó sì tún ti gòkè àgbà báyìí.
Ààrẹ sọ èyí níbi àpéjọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ní Yokohama, Japan.
Olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí; Bayo Onanuga ló bu ọwọ́ lu àtẹ̀jáde yìí, nínú rẹ̀ la ti kà á pé ìṣèjọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣe àtúnṣe sí ọrọ̀ ajé tó mẹ́hẹ ṣáájú kí ó tó gorí ipò, ó sì ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn àtúnṣe tí yóò pèsè iṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu, òkòwò ati àwọn ohun amáyédẹrùn.
Ọ̀rọ̀ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tẹ̀síwájú pé ‘Inú mi dùn láti ríi pé àwọn ọmọ Nàìjíríà kọ̀ọ̀kan ti ń darí wálé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan takú sí òkè òkun, a kò le fi ipá gbé wọn wálé nítorí pé òfin fi ààyè gba kí èèyàn ó gbé ibi tó wù ú.
Àmọ́ mo rọ̀ yín, nítorí ọrọ̀ ajé àti ìdàgbàsókè Nàìjíríà, ẹ má takú sí òkè òkun, ẹ padà wá sílé.
Bí ẹ bá kọ̀ látì wá kó ipa yín nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yín, ta ni yóò bá a yín ṣe é?
Ìṣèjọba mi ti pèsè ètò ìlera tó péye láti dẹ́kun lílọ gba ìtọ́jú lókè òkun bẹ́ẹ̀ sì ni ọrọ̀ ajé ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
Ẹ kò le dá ìdàgbàsókè ìlú dá ìjọba nìkan, ẹ máa bọ̀ nílé kí ẹ wá kópa, ẹ fi ẹnu rere sọ ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.
Bí ẹ bá takú sí òkè òkun tí ẹ kò bá wálé wá kópa nínú ìṣèjọba yìí, á jẹ́ pé a kùnà nínú adarí ọjọ́ ọ̀la tí a ní a ń tọ́’ èyí ni àwọn ohun tí ààrẹ sọ.
Lẹ́yìn tí ààrẹ gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ké sí Mínísítà fún ìdásílẹ̀ àti àmójútó àwọn ilé iṣẹ́; Aṣòfin John Enoh àti igbákejì alága ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn ohun amáyédẹrùn; Khalil Suleiman Halilu láti ṣe àlàyé ibi tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu bá iṣẹ́ ìdàgbàsókè Nàìjíríà dé.
Wale Tinubu; ẹni tó jẹ́ àna ààrẹ Tinubu náà ṣe àlàyé bí àtúntò ètò òkòwò tí ààrẹ ṣe ṣe mú àyípadà rere bá ọrọ̀ ajé ilẹ̀ wa tí àwọn oníṣòwò sì ń ti orílẹ-èdè wọn wá ṣòwò ní Nàìjíríà.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Japan; Emeka Ebogota dúpẹ́ lọ́wọ́ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún wọn àti àwọn àgbékalẹ̀ amáyédẹrùn tó ṣètò rẹ̀.
Lẹ́yìn tí a ti ka ohun tí àwọn méjèèjì sọ, ta ni ká gbàgbọ́?
Ààrẹ ní ká má dira pé ìlú tòrò, Ọ̀gágun ní ká dira, ẹ rántí pé Ọ̀gágun ni ààrẹ bẹ̀ nísẹ́ ọ̀rọ̀ ààbò.
Ọ̀rọ̀ ààbò lápá kan, lápá kejì, aya ààrẹ wa; Aṣòfin Oluremi Tinubu ti rọ àwọn olóṣèlú ìpínlẹ̀ Èkó láti fi ìṣọ̀kan ṣe iṣẹ́ wọn kí wọ́n má ṣe fi ti ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe.
A gbọ́ pé:
Aya ààrẹ ilẹ̀ wa; Aṣòfin Oluremi Tinubu bá àwọn olóṣèlú ìpínlẹ̀ Èkó sọ̀rọ̀ pé kí wọn ó fi ọwọ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti tukọ̀ orílẹ-èdè yìí.
Ó wí pé kí wọn ó má ṣe fi ti ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe ìjọba, ó rọ̀ wọ́n láti gbé ti ẹgbẹ́ òṣèlú sọ́tọ kí wọn ó sì fi ìsọ̀kàn ṣe ìjọba.




