Àwọn obìnrin ìlú Ìlàjẹ tú jáde lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó pẹ̀lú oríṣìí àkọlé lọ́wọ́, wọ́n ké sí agbẹnusọ ilé náà ìyẹn Mudashiru Obasa àti àwọn aṣòfin lápapọ̀ láti kìlọ̀ fún àwọn ọba tí wọ́n di ajagungbalẹ̀, wọ́n ní àwọn ọba yìí ń lé àwọn kúrò ní orí ilẹ̀ tí àwọn tẹ̀dó sí wọ́n sì ń ta àwọn ilẹ̀ náà.
Àwọn obìnrin yìí wí pé àwọn yóò ṣe ìwọ́de ní ìhòhò bí èyí kò bá dópin.
Ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ifagbemi bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ṣe àlàyé pé àwọn ni ìran tó tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà láti ìgbà tí aláyé ti dáyé, àwọn ọba tí ó ń jẹ lásìkò yìí ń lé àwọn kúrò lórí ilẹ̀, wọn yóò gbé katakata wá wó ilé wọn nígbà tí wọ́n bá ta ilẹ̀ náà mọ́ wọn lórí.
Orúkọ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní àwọn ọba yìí máa ń dá, wọ́n á ní Tinubu ló pàṣẹ kí wọn ó gba ilẹ̀ náà.
Àwọn obìnrin yìí kóra jọ sí iwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó nínú òjò wẹliwẹli náà, wọ́n ní àwọn mọ̀ pé àwọn ọba yìí kàn ń fi orúkọ Tinubu rẹ́ àwọn jẹ lásán ni òun kọ́ ló rán wọn.
Wọ́n wá fi lé e pé bí èyí kò bá dópin, àwọn yóò ṣe ìwọ́de ní ìhòhò ọmọlúàbí.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ Ìlàjẹ; Rafael Irowainu náà sọ̀rọ̀, ó wí pé orílẹ-èdè Nàìjíríà nìkan ni òfin kò ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, àwọn ọba ń jẹ ayé fàmílétè-n-tutọ́, wọ́n ń gbé ilẹ̀ onílẹ̀ tà kò sì sí oníbàáwí fún wọn.
Iroiwanu wí pé púpọ̀ nínú àwọn ọba yìí kìí ṣe ọmọ Èkó, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Èkìtì ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá tí wọ́n sì fi èèrú dé orí ipò ọba náà.
Wọn yóò kàn gbé katakata dé sínú àdúgbò wọn yóò sì máa wó ilé láìsí ìwé àṣẹ láti ilé ẹjọ́, àwọn èèyàn yóò di aláìnílélórí láìrò tẹ́lẹ̀, wọ́n ní gbogbo èyí tó gẹ́.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn wá láti wá fi ẹ̀dùn ọkàn wọn tó Gómìnà Babajide Sanwoolu létí àti àwọn aṣòfin Èkó kí wọn ó wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà.
Bákan náà ló wí pé wíwó ilé onílé kún ohun tó ń fa ìwà ọ̀daràn nítorí pé àwọn tí kò nílé lórí mọ́ náà yóò padà darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀daràn níbi tí wọ́n bá ti ń wọ̀sùn kiri.
Wole Adewusi tí òun náà jẹ́ olùwọ́de sọ wí pé àwọn obìnrin àti ọmọ ti di asùnta ní Ìlàjẹ látàrí bí àwọn ọba ṣe ń wó ilé yìí, ó ní wọ́n tún ń sun àwọn dúkìá tí wọn kò bá tètè kó, ó ké sí Sanwoolu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn.
Alága ẹgbẹ́ ọmọ Ìlàjẹ; Ọmọba Oluwajimusu bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà yìí, ó wí pé kò sí bí wọn yóò ṣe kọ ìtàn ìpínlẹ̀ Èkó tí wọn kò ní dárúkọ ìran Ìlàjẹ, ìjọba fẹ́ pa orírun Ìlàjẹ run ni gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí.
Oluwajimusu wí pé ṣíṣe àyípadà orúkọ òpópónà Ìlàjẹ tó wà ní Bariga sí Sunny Ade jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí wọ́n fẹ́ gbà pa ìtàn Ìlàjẹ rẹ́.
Lórí ìwọ́de yìí kan náà, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ìwọ́de lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó lórí bí wọ́n ṣe kọ iyán wọn kéré nínú ìyànsípò akọ̀wé, wọ́n tún ní kí wọn ó yọ Faleke nípò.
Báyìí ni ìròyìn náà ṣe lọ:
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ní iwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó.
Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún náà ni ìyọnípò alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó; Pásítọ̀ Corlenius Ojelabi àti Amòfin James Faleke.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n náà ni pé wọ́n ń fi ọwọ́ rọ́ àwọn sẹ́yìn nínú ìṣèjọba àwarawa, wọ́n ń yan àwọn adarí fún àwọn wọ́n sì ń kàn án nípá, wọn kò fún àwọn ní anfààní àti yan ẹni tó wu àwọn sípò.
Àwọn olùwọ́de yìí wí pé àwọn kò ní ẹ̀hónú nípa àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àṣẹ̀ṣẹ̀yàn àmọ́ àwọn lẹ́tọ̀ọ́ àtiyan akọ̀wé àti alákòóso àmọ́ níṣe ni Ojelabi àti Faleke lẹ̀dí àpò pọ̀ tí wọ́n sì yan àwọn akọ̀wé àti alákòóso sípò láì bu àwọn gbọ́.
Oríṣìí akọ̀lé ni wọ́n gbé lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń kọ orin ìfẹ̀hónúhàn.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà pọ̀ bìbà láti ríi pé kò mú rògbòdìyàn dání.
Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Dọ́kítà Obafemi Hamzat wá sí ibi ìfẹ̀hónúhàn náà láti bá wọn sọ̀rọ̀ àmọ́ ó kúrò níbẹ̀ nígbà tí wọn kò fún un láàyè àti sọ̀rọ̀.
Otumba Adetunbosun; ọ̀kan nínú àwọn olùwọ́de náà láti Ikorodu bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀. Ó wí pé èyí tí Ojelabi ṣe nípò alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Èkó ti tó kó kúrò nípò náà. Ogunba fi ẹ̀sùn kan Ojelabi pé ó ń fi ọwọ́ la ilẹ̀ fún àwọn kò fún àwọn ní anfààní àtiyan ẹni tí àwọn fẹ́ sípò.
A kìí ṣe jàǹdùkú, ìjoba àwarawa ni a ń bèèrè fún bíi ti ìgbà Bayo Oshinowo – Adetunbosun ló sọ èyí.
Arábìnrin Babalola aya Balogun láti Àgbàdo Òkè – odò náà sọ̀rọ̀. Ó fi ẹ̀sùn kan àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC pé wọ́n ń kọyán àwọn aráàlú kéré wọn kò sì fi ààyè sílẹ̀ fún ìjọba àwarawa.
Gómìnà Babajide Sanwoolu ní wọn kò gbọdọ̀ yan akọ̀wé ìjọba àti alákòóso fún oṣù mẹ́fà gbáko nitori kí wọn ó le yàn fún àwọn.
Àwa la dìbò fún ààrẹ Tinubu àti Gómìnà Babajide Sanwoolu, kò yẹ kí wọn ó máa wá fi ọwọ́ lalẹ̀ fún wa – Aya Balogun.
Arábìnrin Balogun rọ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti yanjú ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yìí kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ó má bàa wó lulẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Asabi Adejuwon náà sọ̀rọ̀, ó wí pé àwa la ṣe ìpolongo ìbò fún wọn kí wọ́n tó wọlé sípò, wọ́n wọlé tán ni wọ́n dà wá nù bí omi ìṣanwọ́.
Àwọn èèyàn kò fẹ́ dìbò fún àwọn olùdíje wa nítorí pé kò sí oúnjẹ nílùú, kò sówó, wọn kò jẹ anfààní kankan lára ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àwa la bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n fi dìbò fún yín, ẹ wá pa wá tì nísìn yìí. Ibí ni Asabi sọ̀rọ̀ dé tó fi bú sẹ́kún.
Alhaji Talibu Lawal náà ṣe àlàyé pé àsìkò ti tó fún Ojelabi àti Faleke àti Alhaja Akerele láti kúrò ní ipò. Ó fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ti jẹ Ikeja run, bí wọ́n bá ṣì wá nípò, wọn yóò jẹ Èkó run.
Wọ́n ní àwọn yóò kọ ìwé sí Gómìnà Babajide Sanwoolu lórí ohun tí àwọn ń fẹ́ yìí.



