Nítorí owó ilẹ̀ mọ̀lẹ́bí tí wọ́n tà ni Ifeanyi ṣe gún bàbá rẹ̀ lọ́bẹ pa.
Ìròyìn fi yé wa pé ọ̀rọ̀ owó ilẹ̀ náà dìjà láàrin Ifeanyi Odinka àti bàbá rẹ̀; Dennis Odinka.
Níbi tí wọ́n ti ń fà á ni Ifeanyi ti fa ọ̀bẹ yọ tó sì fi gún bàbá rẹ̀ pa.
Ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì ni Ifeanyi nígbà tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin.
Henry Okoye; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀.
Henry ṣe àlàyé pé Ifeanyi ti jẹ́wọ́ pé òun gún bàbá òun pa nítorí pé ó yan òun jẹ nínú owó ilẹ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti tari Ifeanyi lọ sí ẹ̀ka tó ń gbọ́ ti ìpànìyàn.
Ifeanyi kọ́ ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò gún bàbá rẹ̀ lọ́bẹ pa, ní ìpínlẹ̀ Adamawa, Buba náà gún bàbá rẹ̀ lọ́bẹ pa ọ, ìròyìn Buba tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ rèé:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ Idi Buba tó gùn bàbá rẹ̀ lọ́bẹ pa ní agbègbè Fotta ní ìjọba ìbílẹ̀ Gombi, ìpínlẹ̀ Adamawa.
Àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé Idi àti bàbá rẹ̀; Buba Jelili jọ ní gbọ́nmisí-omi-ò-tóo, ẹnu rẹ̀ ni wọ́n wà tí Idi fi yọ ọ̀bẹ tó sì fi gún bàbá rẹ̀ lọ́rùn.
Wọ́n gbé Jelili dé ilé ìwòsàn ìjọba Fotta àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ní báyìí, Idi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá títí yóò fi fojú ba ilé-ẹjọ́.
Ìròyìn mìíràn tó tún fara pẹ́ èyí ni ti ọmọdékùnrin kan ti wọ́n pa ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ìròyìn ikú ọmọ yìí gba omi lójú ọ̀pọ̀ nítorí pé lẹ́yìn tí wọ́n pa á tán ni wọ́n tún gé orí rẹ̀ lọ.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lọ rèé:
Bàbá ọmọdékùnrin kan tí Salawu Omikansola pa nípakúpa ti ṣe àlàyé ikú tó pa ọmọ náà.
Olumide Lawal ni orúkọ bàbá Wahab, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni Wahab lásìkò ikú rẹ̀.
Agbègbè Igbile Ijebu ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀.
Lọ́jọ́ kọkànlélógún, oṣù Agẹmọ ni Wahab sọnù tí kò wá sílé, nígbà tó di ọjọ́ kẹta, wọ́n rí òkú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ títì tí ẹ̀yà ara rẹ̀ kò sì pé mọ́.
Wọ́n ti gé orí àti ọrùnwọ́ rẹ̀ wọ́n sì ti yọ ọkàn àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.
Bàbá Wahab ṣe àlàyé pé Igbile Ijebu ni ìyá ọmọ náà ń gbé nígbà tí òun ń gbé ní Ijebu Ode.
Lọ́jọ́ náà, ìyá Wahab pe bàbá rẹ̀ pé ṣé Wahab wá sí ọ̀dọ rẹ̀ ni nítorí pé wọn kò ríi.
Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń wá a kiri gbogbo Igbile Ijebu àti Ijebu Ode.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta ni àwọn ará àdúgbò wá pe baba Wahab nílé pé wọ́n rí òkú kan lọ́nà oko pẹ̀lú irú asọ Wahab.
Olumide ní òun kò gbàgbọ́ àmọ́ òun tẹ̀lé wọn dé ibẹ̀. Wọ́n bá òkú Wahab nílẹ̀, aṣọ àti bàtà ni wọ́n fi dá a mọ̀ nítorí pé wọ́n ti gé orí rẹ̀, ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ọkàn àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ lọ.
Àwọn ọdẹ àdúgbò ló júwe Salawu Oyinkansola fún wọn pé àwọn pàdé rẹ̀ lóru ọjọ́ tí ọmọ náà sọnù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ lára aṣọ rẹ̀.
Salawu sọ fún àwọn ọdẹ pé òun lọ bá àwọn èèyàn kan pa ajá fún Ògún ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ta sí òun láṣọ, ni wọ́n bá fi sílẹ̀.
Ìtọpinpin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú Salawu Oyinkansola, òun ló dárúkọ Serefusi Agemo.
Salawu ṣe àlàyé pé Serefusi ló ní kí òun ó pa ọmọ náà kí òun ó sì yọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀. Ó ní ẹ̀rù ba òun àmọ́ Serefusi ló ki òun láyà.
Serefusi Agemo ni olórí àwọn Alágẹmọ agbègbè náà. Kò sọ nǹkankan nípa ẹ̀sùn tí Salawu fi kàn án àmọ́ ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Baba Wahab; Olumide Lawal rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti ṣe ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ rẹ̀. Ó wí pé òun gbọ́ pé Serefusi ní igi lẹ́yìn ọgbà tó sì máa ń mú ẹ̀sùn jẹ àti pé àwọn kan ti ń dúnkokò mọ́ òun láti pa ẹjọ́ náà tì.
Olumide ní ohun tí òun ń fẹ́ náà ni ìdájọ́ òdodo kí ọmọ òun má kú gbé.
Ẹni tí kò rí ẹni tí yóò gún un pa tún gún ara rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Delta.
A gbọ́ nípa ThankGod Elufo tó gún ara rẹ̀ pa nílé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wà ní Ajaji.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ni ó ti gún ara rẹ̀ lọ́bẹ pa ní ìpínlẹ̀ Delta báyìí.
ThankGod Elufo ni orúkọ arákùnrin yìí, a gbọ́ pé Ajaji ní Asaba tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Delta ni ThankGod ń gbé pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
Lọ́jọ́ Àbámẹ́ta tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sọ fún un pé kí ó múra àwọn ń lọ sí òde.
Ìròyìn fi yé wa pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń retí kó jáde láti inú yàrá tó ti lọ múra òde, nígbà tí kò ríi ló bá lọ wòó nínú ilé, inú yàrá ìdáná ló ti bá ThankGod àbúrò rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀bẹ níkùn.
Kíá ni ó ti ránṣẹ́ pe olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ agbègbè náà; Ọ̀gbẹ́ni Okolo.
Okolo náà ṣe àlàyé pé òun bá òkú ThankGod nílẹ̀ nínú yàrá ìdáná pẹ̀lú ọ̀bẹ níkùn rẹ̀.
Ó ṣe àlàyé pé ọdún tó kọjá, àwọn kan fún ThankGod ní májèlé jẹ àmọ́ ó yè é. Láti ìgbà náà ni ó ti ń ṣe wọ́nranwọ̀nran tó sì máa ń tẹnu mọ ọn pé àwọn kan fẹ́ pa òun àmọ́ kò sí ẹni tó kọbi ara síi.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú ThankGod lọ sí ilé igbókǔsí.
Bright Edafe; alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀.




