ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

ỌWỌ́ TẸ ÀWỌN TÓ SẸKÚ PA ALÁBOYÚN TÍ WỌ́N TÚN KUN ÚN WẸ́LẸ́WẸ́LẸ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.

Wọ́n tún pa Fish Magnet ní Anambra kan náà.

by Adeola Olanrewaju
July 30, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, ijamba oko, Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde, Ọ̀rọ̀ Ààbò, Ọ̀rọ̀ ìdílé
0
ỌWỌ́ TẸ ÀWỌN TÓ SẸKÚ PA ALÁBOYÚN TÍ WỌ́N TÚN KUN ÚN WẸ́LẸ́WẸ́LẸ́ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.
0
SHARES
21
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Arábìnrin kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó sì tún lóyún sínú ni àwọn méjì kan ti sẹkú pa báyìí tí wọ́n sì tún kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Chiemere Elobisi; ọ̀dọ́mọkùnrin kan ló tan nọ́ọ̀sì náà wá sí ilé rẹ̀ pé kí ó wá tọ́jú òun, nígbà tí nọ́ọ̀sì yìí dé ilé rẹ̀, Chiemere pa á ó sì kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ sínú àwọn ọ̀rá dúdú.
Lẹ́yìn náà ni ó ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún àwọn oníṣègùn káàkiri. Ìyókù rẹ̀ tó dà sí inú kòtò ìdaminù ni ó mú kí àwọn ọ̀dọ́ ó faraya tí wọ́n sì tọpinpin dé ilé rẹ̀.
Chiemere ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ àmọ́ ọwọ́ tẹ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ; Somtochukwu Nwafor.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni Somtochukwu, ó ṣe àlàyé pé òun kò lọ́wọ́ sí pípa àti kíkun nọ́ọ̀sì náà, òun kàn nu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà tí Chiemere pa á tán ni.
Somtochukwu ló mú àwọn ọlọ́pàá dé ọ̀dọ àwọn oníṣègùn tí Chiemere ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún ọwọ́ sì ti tẹ ọ̀kan nínú wọn.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ ní agbègbè Ogbunike ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyi.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn ti mú Somtochukwu tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin Chiemere nígbà tí Chiemere gan-an ti sá lọ.
Somtochukwu júwe àwọn oníṣègùn tí Chiemere máa ń ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún. Èyí ni wọ́n fi mú Nwafor Chibunna tí wọ́n sì bá ẹ̀yà ara nọ́ọ̀sì yìí àti àwọn mìíràn lákàtà rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń wá àwọn oníbàárà ẹ̀yà ara yòókù àti Chiemere.

Ní ìpínlẹ̀ Anambra yìí kan náà, lọ́sẹ̀ yìí kan náà ni wọ́n ti sẹkú pa ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ ‘Fish Magnet’
Ẹja ni ọkùnrin yìí ń tà ó sì jẹ́ ọmọ kan ṣoṣo tí aṣáájú àwọn obìnrin ẹgbẹ́ òṣèlú APGA bí.
Ikú rẹ̀ dun ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ó sì ń jà ràìnràìn lórí ìkànnì ayélujára.

Ìròyìn ikú Fish Magnet kà báyìí pé:

ADVERTISEMENT

Ìròyìn tó ba ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn nínú jẹ́ ni ìròyìn ikú ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí àwọn ajínigbé dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò ní ìpínlẹ̀ Anambra.
Ifesinachi Onyekere ni orúkọ ọmọkùnrin yìí, òwò ẹja ni ó ń ṣe.
Ní òru ọjọ́ àbámẹ́ta ni àwọn ajínigbé náà ya wọ ilé rẹ̀ ní Ezinifite, wọ́n kó o ní pápámọ́ra, wọ́n yin ìbọn fún un lẹ́sẹ̀ kí wọ́n tó fi ọkọ̀ rẹ̀ gbé e lọ.
Ọjọ́ mẹ́ta ni ó lò ní àkàtà wọn tí wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ ṣeni wọ́n pa á tí wọ́n sì ju òmú rẹ̀ nù sí ẹ̀gbẹ́ títì.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé àwọn ti rí ọkọ̀ Onyekere tí wọ́n fi gbé e lọ àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ikú Fish Magnet yìí mú kí àwọn ọ̀dọ́ ó faraya lórí ètò ààbò ilẹ̀ wa tó mẹ́hẹ àti bí àwọn ajínigbé ṣe ń fi ojoojumọ́ gbilẹ̀ síi.
Vincent Otse; ẹni tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Verydarkman dá sí ọ̀rọ̀ yìí.
Ó ṣe àpèjúwe ikú Fish Magnet gẹ́gẹ́ bíi ohun tó báni lọ́kàn jẹ́, ó wí pé ògo ọ̀la kan tún ni àwọn ajínigbé dá légbodò yìí.

Lórí ìpànìyàn yìí kan náà, ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan láti ìpínlẹ̀ Òndó nípa bí Augustina ṣe sẹkú pa ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Samuel.

A gbọ́ pé:

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ Augustina Mowan ní ìpínlẹ̀ Òndó lórí ẹ̀sùn pé ó sẹkú pa ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀.
Okitipupa ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ lẹ́yìn tí Augustina kojú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nípa ọmọbìnrin mìíràn tó ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́, ọ̀rọ̀ náà dìjà láàrin wọn ní èyí tí Augustina sì fi emuga gún Michael ní ẹsẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òndó; Ọ̀gbẹ́ni Olayinka Ayanlade wí pé àwọn ti mú Augustina sí àhámọ́ lórí ikú tó pa ọ̀rẹ́kùnrin é; Michael.
Ẹnìkan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ rẹ̀ ṣe àlàyé pé Michael àti Augustina jọ ń gbé nínú yàrá kan aládàáni, wọn kò tíì ṣe ìgbéyàwó.
Ó wí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń jà tí Augustina máa ń fi ẹ̀sùn àlè yíyàn kan Michael.
Lọ́jọ́ náà, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ìjà yìí, Augustina bá mú emuga ló bá fi gún Michael ní ẹsẹ̀. Wọ́n gbé é lọ sí ilé ìwòsàn ó sì gba ìtọ́jú.
Lẹ́yìn tó dé ilé ni ẹsẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní wú, ìgbà tí yóò fi padà sí ilé ìwòsàn, ẹlẹ́mìí ti gbà á, Michael dágbére fáyé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò parí ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

ADVERTISEMENT

Bí a ti ń kọ èyí lọ́wọ́ ni ìròyìn kan tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ lórí ìpànìyàn yìí kan náà láti ìpínlẹ̀ Adamawa.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn méjì ni a gba ìròyìn rẹ̀ ní agbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìpínlẹ̀ Adamawa.
Àkọ́kọ́ ni ti ọmọ ìyàwó tó fọ́ igi mọ́ ìyáálé ìyá rẹ̀ lórí.
Èkejì ni ti ọmọ tó gún bàbá rẹ̀ pa nígbà tí wọ́n ń jà.

Ìròyìn tìyàálé tìyàwó kà báyìí pé:
Àwọn ìyàwó Anthony Pallam méjèèjì ni wọ́n ń jà gẹ́gẹ́ bíi ìṣe wọn.
Rhoda ni orúkọ ìyáálé nígbà tí orúkọ ìyàwó ń jẹ́ Victoria. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta ni Rhoda nígbà tí Victoria jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì
Níbi tí àwọn méjèèjì ti ń jà lọ́wọ́ ni ọmọ ìyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ijai ti mú igi tó sì fọ́ ọ mọ́ ìyáálé ìyá rẹ̀ lórí.
Wọ́n du Rhoda dé ilé ìwòsàn Cottage àmọ́ ó padà kú sílé ìwòsàn náà.
Ní báyìí, Victoria àti ọmọ rẹ̀ ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá títí wọn yóò fi fojú ba ilé-ẹjọ́.

Ìròyìn bí Idi Buba ṣe pa bàbá rẹ̀; Buba Jelili náà kà báyìí pé:

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ Idi Buba tó gùn bàbá rẹ̀ lọ́bẹ pa ní agbègbè Fotta ní ìjọba ìbílẹ̀ Gombi, ìpínlẹ̀ Adamawa.
Àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé Idi àti bàbá rẹ̀; Buba Jelili jọ ní gbọ́nmisí-omi-ò-tóo, ẹnu rẹ̀ ni wọ́n wà tí Idi fi yọ ọ̀bẹ tó sì fi gún bàbá rẹ̀ lọ́rùn.
Wọ́n gbé Jelili dé ilé ìwòsàn ìjọba Fotta àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ní báyìí, Idi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá títí yóò fi fojú ba ilé-ẹjọ́.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeedAfojúsùn Iwe Iroyin YorubabreakingnewsdeathIwe Iroyin Yorubanews onlinenewsonlinenewsupdatepoliticstrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
TUFACE ṢE ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA OSAWURU.

TUFACE ṢE ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA OSAWURU.

Recommended

ỌKỌ̀ IṢU TẸ KẸ̀KẸ́ MARUWA NÍ Ẹ̀PẸ́, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ

ỌKỌ̀ IṢU TẸ KẸ̀KẸ́ MARUWA NÍ Ẹ̀PẸ́, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ

3 months ago
TUFACE ṢE ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA OSAWURU.

TUFACE ṢE ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA OSAWURU.

10 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.