Ọkùnrin kan tí wọ́n fura sí pé ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni wọ́n bá odidi agbárí èèyàn lọ́wọ́ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom.
Pius Pius ni orúkọ ọkùnrin yìí, ẹni ogójì ọdún níí ṣe. Agbègbè Oku Abak ní ìjọba ìbílẹ̀ Abak ni ó ń gbé.
Afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn àti jàǹdùkú ni Pius lágbègbè náà.
Ìfimúfínlẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ ká a mọ́lé ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà tí wọ́n sì tú gbogbo yẹ̀wù rẹ̀ tútú. Wọ́n bá odidi agbárí èèyàn kan, àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀rọ amúnáwá tiransifọ́mà àti àwọn nǹkan mìíràn tó ti sọnù ládùúgbò.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom; Timfon John ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Ó wí pé ní ogúnjọ́, oṣù Agẹmọ ni àwọn lọ ká Pius mọ́lé lórí ìró rẹ̀ tí àwọn ń gbọ́.
Pius kò jiyàn, ó jẹ́wọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Iceland ni òun. Oríṣìí itú ni ẹgbẹ́ òkùnkùn Iceland ti pa ní Abak àti agbègbè rẹ̀.
Timfon wí pé ìwádìí kò tíì parí lórí ọ̀rọ̀ Pius yìí, ní kété tí wọ́n bá parí ìwádìí ni yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́.
Ìròyìn mìíràn tó fara pẹ́ èyí ni ìròyìn arákùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Samuel Eze tí wọ́n bá ọmú àyà obìnrin kan lọ́wọ́ rẹ̀. Kódà ọmú náà ṣì tutù mini nígbà tí ọwọ́ tẹ̀ ẹ́.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Arákùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Samuel Eze ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tí wọ́n bá odidi ọmú obìnrin kan lọ́wọ́ rẹ̀.
A gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ojú pópó tí wọ́n ń yẹ ẹrù àwọn èèyàn wò ló dá Samuel dúró ní ojú ọ̀nà Jude Onyekwere, Awada ní Obosi ìpínlẹ̀ Anambra. Wọ́n tú ẹrù rẹ̀ wọ́n sì bá odidi ọmú òbìnrin kan tó ṣì tutù mini nínú ẹrù rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Samuel, kò rí àlàyé kan ṣe ní pàtó, ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí.
Tochuku Ikenga; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀.
Lórí ìròyìn ẹ̀yà ara èèyàn yìí kan náà,bí ẹ kò bá gbàgbé, ìròyìn AbdulRahman ní ìlú Ilorin tó ṣekú pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀.
Ìròyìn yìí mìlú tìtì ó ṣì wà nílé ẹjọ́ di àsìkò yìí.
A mú ìròyìn náà wá nígbà náà pé:
AbdulRahman ni orúkọ afurasí alápatà yìí, ìlú Ilorin ló tẹ̀dó sí, inú ilé rẹ̀ náà ló sọ di odò ẹran tó ti ń pa á kun ún. Èyí tó bu ú lọ́wọ́ yìí ni ti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó pa, Hafsoh lọ kí AbdulRahman nílé ni kò dé mọ́. Ìtọpipin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú AbdulRahman, ó ti pa ọmọ náà ó sì ti gé e níkèéníkèé sínú ike ọ̀dà ọlọ́mọrí.
Ó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kan níbi tó ti sọ pé òun kò jẹ̀bi, adájọ́ sì sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ síwájú.
Hafsoh ni orúkọ ọmọbìnrin yìí, ọ̀rẹ́bìnrin AbdulRahman níí ṣe.
Lọ́jọ́ tí yóò ṣe àgbákò ikú òjìjì yìí, Hafsoh dágbére fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé òun fẹ́ yára yọjú sí ọ̀rẹ́kùnrin òun. Lílọ tó lọ ni kò dé mọ́ tí àwọn ọlọ́pàá fi bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Láti ìgbà náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀, ní àárín kan, adájọ́ pàṣẹ kí wọn ó yọ̀ǹda òkú Hafsoh fún àwọn ẹbí rẹ̀ kí wọn ó sin ín.
Ìròyìn náà lọ báyìí pé:
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kwara tó fìkàlẹ̀ sí Ilorin ti pàṣẹ kí wọn ó yọ̀ǹda ìyókù Hafsoh fún àwọn òbí rẹ̀ láti lọ sin.
Adájọ́ Hannah Ajayi ló pàṣẹ yìí nìgbà tí agbẹjọ́rò ẹbí Hafsoh bèèrè fún ìyọ̀ǹda ìyókù Hafsoh kí wọn ó sin ín kí ẹ̀mí rẹ̀ ó le sinmi.
Adájọ́ Hannah wí pé òun kò ní àtakò sí ìbéèrè yií, ó wí pé òun bá àwọn ẹbí Hafsoh kẹ́dùn ó sì pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó yọ̀ǹda ìyókù ọmọ náà fún àwọn òbí rẹ̀.
Ìgbẹ́jọ́ ṣì ń tèsíwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, gbogbo èèyàn ló sì ń retí ìdájọ́ òdodo.
Nígbà tí AbdulRahmon tó jẹ́ Àlùfáà sẹkú pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Timilehin náà tó jẹ́ akọrin ẹ̀mí nínú ìjọ kìrìsìtẹ́nì náà sẹkú pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀; Salome Enejo tó sì gé e ní èkìrì sínú ilé rẹ̀.
Àwọn ará ìjọ rẹ̀ ni wọ́n rí i nígbà tí ó ń gbé orí Salome lọ sínú odò kan tí wọ́n sì mú un.
Ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kà báyìí pé:
Ọjọ́ Àìkú ni ọjọ́ yìí, Timilehin gbé orí Salome sínú àpò, ìsìń ṣì ń lọ lọ́wọ́, olùjọ́sìn kan ló fura sí Timilehin pé ìrìn rẹ̀ mú ìfura dání bó ṣe ń lọ sí etídò kan tí kò jìnnà sílé ìjọsìn.
Ẹni yìí pe àwọn èèyàn mọ́ra, wọ́n sì tọ ipasẹ̀ rẹ̀, bí Timilehin ṣe rí wọn ló sọ àpò náà sódò. Wọ́n mú un pé kó yọ àpò náà kó sì tú u, ó feré gée àmọ́ wọ́n lé e mú, títú tí yóò tú àpo yìí, orí àfẹ́sọ́nà rẹ̀; Salome ni wọ́n bá nínú rẹ̀.
Ìdájọ́ ọwọ́ ni wọ́n fẹ́ ṣe fún un àmọ́ àwọn ọlọ́pàá gbà á kalẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n lọ tú ilé rẹ̀ tí wọ́n sì bá àwọn ẹ̀yà ara Salome nínú àpò méji.
Àwọn ẹbí Salome ṣe ìdámọ̀ ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ni Salome, àgùnbánirọ̀ sì ni pẹ̀lú.
Wọ́n ní Timilehin jí ọmọ àwọn gbé ni pé kìí ṣe àfẹ́sọ́nà rẹ̀ bí ó ṣe sọ.
Láti ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ náà ti wà nílé ẹjọ́ tí ìgbẹ́jọ́ sì ń lọ lórí rẹ̀ di àsìkò yìí.
Àwọn apanijayé ti pọ̀ ní àwùjọ wa báyìí,kí Elédùà ó má jẹ́ kí a kó sí wọn lọ́wọ́.





