Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣe ìpàdé ìdákọ̀kọ̀ pẹ̀lú Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tí ó júwe ilé fún; Siminalayi Fubara àti mínísítà fún Olú ìlú wa; Nyesom Wike.
Ìpàdé yìí kò yọ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ìpínlẹ̀ Rivers sílẹ̀, gbogbo wọn ló péjúpésẹ̀.
Kókó ìpàdé náà ni bí wọn yóò ṣe yanjú aáwọ̀ tó wà láàrin Fubara àti Wike.
Ohun tí a gbọ́ ni pé Tinubu bá Fubara ṣe àdéhùn pé òun yóò dáa padà sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers náà bí ó bá gbà láti ṣiṣẹ́ fún òun nínú ìdìbò ọdún 2027. Bákan náà ni pé Wike ni yóò yan àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo, paríparí rẹ̀ ni pé Fubara kò ní díje dupò sáà kejì.
A kò tíì le sọ bí Fubara bá fi ara mọ́ gbogbo nǹkan yìí àmọ́ a rí àwọn àwòrán tí wọ́n jọ yà lẹ́yìn ìpàdé náà.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ gan-an.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ló yọ Siminalayi Fubara nípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tó sì kéde ìpínlẹ̀ náà ní ìpínlẹ̀ pàjáwìrì. Ààrẹ yan Admiral Ibot-Ete Ibas ní Apàṣẹ wàá ìpínlẹ̀ náà.
Oríṣìí nǹkan ló ti ṣẹlẹ̀ láàrín ìgbà náà sí àsìkò yìí.
Ìlú fìgbà kan dá sí méjì nígbà tí àwọn kan ń ṣe ìwọ́de ṣègbè fún Fubara tí àwọn kan sì wí pé ìjọba ológun náà gan-an ni àwọn fẹ́.
Nínú èyí ni Fubara fúnra rẹ̀ ti sọ pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sí ipò náà gan-an mọ́.
Bákan náà ni Olórí àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀.
Ohun tí a gbọ́ ni pé Dọ́kítà George Nwaeke kọ̀wé ìfipòsílẹ̀ ránṣẹ́ sí olórí ìlú titun; Admiral Ibos-Ete Ibas pé òun kò ṣe iṣẹ́ mọ́ o.
Nínú èsì tí Ibas fi ránṣẹ́ síi ni ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àsìkò péréte tó lò pẹ̀lú òun, Ibas kọ ọ́ pé kò dùn mọ́ òun nínú pé ó ń lọ àmọ́ kò sí ohun tí òun le fi dáa dúró. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì ro rere síi fún ọjọ́ iwájú.
Àfi bí ìgbà tí Ibas ń retí kí George ó fipò rẹ̀ sílẹ̀ kó tó yan akọ̀wé ìjọba ni, Lọ́gán ló yan akọ̀wé àgbà ìjọba titun sípò. Ẹni tó yàn náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibibi Worika.
Ibas wí pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò àwọn ìwé ẹ̀rí àti àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, kò sí ẹlòmíràn tó tó ipò náà dì mú ju Ibibi Lucky Worika lọ.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí ààrẹ àti Gómìnà Fubara fi ohùn ránṣẹ́ síra wọn, ààrẹ fi ẹsùn kan Fubara pé òun ló ń fa rúgúdù ìpínlẹ̀ náà, Fubara náà fèsì pé òun kò mọ nǹkan kan nípa àwọn ẹ̀sùn náà.
Àwọn ẹsùn tí ìjọba Tinubu fi kan Fubara ni lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn adàlúrú láti bẹ́ ọ̀pá epo, àìkúnjú òṣùwọ̀n àti ìfẹ́ ara ẹni.
Èsì tí Fubara fọ̀ náà ni pé òun kò ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú tó ń fọ́ ọ̀pá epo káàkiri ìlú náà. Gómínà tí a dá dúró náà sọ láti inú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé rẹ̀; Nelson Chukwudi gbé jáde pé òun kò lọ́wọ́ sí tàbí mọ ohunkóhun nípa bí àwọn jàǹdùkú ṣe ń fọ́ ọ̀pá epo. Ó wí pé ẹ̀sùn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí wọn dáadáa.
Nínú àtẹ̀jáde náà la ti rí i kà pé gbogbo àwọn fọ́nrán tí wọ́n gbé jáde náà níbi tí wọ́n ti fọ́ ọ̀pá epo ló jẹ́ ayédèrú. Fubara wí pé àwọn ará agbègbè náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní agbègbè wọn.
Siminalayi Fubara sọ gbangba gbàǹgbà pé òun k̀ò lọ́wọ́ tàbí mọ ohunkóhun nípa ẹ̀sùn tí ìjọba àpapọ̀ fi kan òun nípa àwọn tí wọ́n ń fọ́ àgbá epo, ó wí pé kí ìjọba ó ṣe ìwádìí rẹ̀ fínní.
Nígbà tí èyí ń lọ lápá kan, dùgbẹ̀ kan tún jábọ́ láti ẹnu ààrẹ wa tẹ́lẹ̀rí; Olusegun Obasanjo ní èyí tó bu epo sí iná tó ń jó.
Kudugbẹ̀ Òótọ́ ọ̀rọ̀ ti jábọ́ látẹnu Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí lórílẹ̀ èdè yìí o. Olóyè Olusegun Obasanjo ti sọ ọ́ pé ẹní gbé pañlá ti jẹ́wọ́ o. Ó ní ọkàn nínú àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin àgbà ti jẹ́wọ́ fóun pé lóòótọ́ ni àwọ́n gba owó ìbọ̀bẹ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́wọ́ Tinubu káwọn tóó fọwọ́ sí òfin ìjọba pajawiri tó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Rivers láìpẹ́ yìí.
Níbi Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn oníròyìn ló ti fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-òfin Ikenga Ugochinyere sẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, Ọbásanjọ́ ní èyí gan-an ló mú kóun fẹ́ẹ́ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀. Ó ní gbogbo ìfun tó wà nínú adìẹ ọ̀rọ̀ náà ni kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ òún ti rí o. Ó ní lára àwọn tó gba owó náà ti jẹ́wọ́ fóun gbañgba. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Olóyè Ọbásanjọ́ ní ohun tó bá wu ẹlẹ́nu ló lè fẹnu rẹ̀ sọ o, àmọ́ òún ti gbọ́ lẹ́nu àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn gbọ̀ngbọ̀n pé òótọ́ làwọ́n tẹ́wọ́ gba owó ìbọ̀bẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là lórí ṣíṣe àtìlẹhìn fún ìjọba pàjáwìrì tí Ààrẹ Tinubu pàșẹ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers.
Ẹ̀sùn tí Ọbásanjọ́ fi kàn yìí wáyé nítorí sísẹ́ tí alága Kọmití fún àbójútó olú ilẹ̀ yìí ní Àbújá sẹ́ pé kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Mukhtar Betara sọ pé kò sóhun tó jọ ọ́ pé àwọ́n gba owó ìbọ̀bẹ́ kankan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni káwọn tó fi àtìlẹhìn wọn hàn sí ìjọba lórí ìjọba pàjáwìrì náà.
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti pe Fubara àti Wike sí ìpàdé. Kí a máa retí ìgbésẹ̀ tó kàn ló kù báyìí.




