Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ níbi ìpàdé tí àwọn ṣojú Àríwá ilẹ̀ yìí ṣe lánàá, ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹẹdógún, oṣù Okúdù lórí ẹni tí yóò díje du ipò Ààrẹ àti igbákejì ní ọdún 2027.
Nínú fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan ni a ti rí àwọn olóṣèlú tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí wọ́n ń ṣojú Àríwá níbi ìpàdé tó padà di bóòlọ-o-yàgò níbi tí olórí ti gbé ń di orí rẹ̀ mú.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ìpínlẹ̀ Gombe ni ìpàdé yìí ti wáyé ní gbọ̀gán International Conference Centre. Kókó ìpàdé náà ni láti fi ẹnu kò lórí ẹni tí yóò díje du ipò Ààrẹ àti igbákejì ààrẹ nínú ètò ìdìbò ọdún 2027.
Igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ẹ̀kun Àríwá; Mustapha Salihu wí pé àwọn ti fẹnu kò lórí pé kò sí ẹni tí yóò díje tako Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀.
Ó wí pé ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtìlẹyìn fún Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ètò ìdìbò ọdún 2027 nítorí pé ó ti da omi síwájú ó sì di dandan kí ó tẹ ilẹ̀ tútù. Salihu wí pé Ààrẹ ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ olówó iyebíye fún àwọn nínú ìṣejọba rẹ̀ yìí ó sì di dandan kí àwọn ó gbárùkù tìí kí ó le wọlé ìdìbò o.dún 2027 náà.
Nígbà tí Salihu gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì dárúkọ Kashim Shettima ní ẹni tí yóò dije dupò igbákejì ni wàhálà bẹ́ sílẹ̀ tí àwọn èèyàn náà sì fárígá. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo Shettima! Shettima! Shettima! Wọ́n ń ju àga lu Salihu wọ́n sì ń sọ ike àti àwọn nǹkan mìíràn mọ́ ọn.
Nígbà tí ó rọlẹ̀ díẹ̀, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC fúnra rẹ̀; Abdullahi Ganduje sọ̀rọ̀, ohun tó sọ náà ni pé ìbò mílíọ́nù kan àti igba ni àwọn dì fún Ààrẹ Tinubu ní ọdún 2023, ó wí pé ìlọpo mẹ́ta èyí ni àwọn ń rétí ní ọdún 2027.
Ọ̀rọ̀ Ganduje tẹ̀síwájú pé Àríwá ló pèsè igbákejì Tinubu ní èyí tí ó ṣe é mú yangàn láwùjọ.
Nígbà tí Ganduje tún gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì sọ pé Shettima yóò díje du ipò igbákejì, ariwo tún sọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé kò sí Shettima kò síbò! Ni ìjà bá tún bẹ̀rẹ̀.
Wọ́n wí pé kàkà kí àwọn ó gbà fún Tinubu láti yọ Shettima ní igbákejì rẹ̀ nínú ìdìbò tó ń bọ̀, àwọn yóò yà dìbò fún Atiku Abubakar sípò Ààrẹ ni.
Aṣojú ìpínlẹ̀ Adamawa sọ gbangba gbàǹgbà pé òun yóò kó àwọn èèyàn òun lọ dìbò fún Atiku Abubakar ni bí Tinubu bá fi yọ Shettima ní igbákejì rẹ̀.
Báyìí lọ́rọ̀ ṣe rí lọ́dọ̀ àwọn yòókù náà, wọ́n fárí gá pé ọlá Shettima ni àwọn ṣe ṣe ti Tinubu, bí ó bá sì fi ní òun kò fẹ́ Shettima ní igbákejì nínú sáà kejì, á jẹ́ pé àwọn yóò padà lẹ́yìn rẹ̀ nìyẹn.
Kódà, Gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe sọ pé òun kò gba ti Tinubu tẹ́lẹ̀ pé nítorí Shettima ni òun ṣe ṣe àtìlẹyìn fún un, bí ó bá wá kọ Shettima sílẹ̀, á jẹ́ pé kí òun náà ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nìyẹn.
Wọn kò ní àwọn kò ṣe igbákejì alága wọn; Mustapha Salihu léṣe, bí àwọn kan ṣe ń jan àga mọ́ ọn ni àwọn kan ń lẹ ike omi mọ́ ọn, ọgbọọgbọ́n tí àgbà fi ń sá fún màálù ni ó fi kúrò láàrín wọn.
Wàhálà náà pọ̀ gan-an tí ó jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá ní láti fín tajútajú láti fi tú wọn ká, ariwo kò sí Shettima kò síbò ló gba ẹnu wọn kan.
Lára àwọn tó fi àáké kọ́rí ni a ti rí Alhaji Bukar Dalori, ó yarí kanlẹ̀ ó sì fárí gá. Ó wí pé àbùkù ńlá àti ẹ̀gbin ni kí wọn ó yọ Shettima nínú eré ìdíjedupò ọdún 2027. Alhaji Dalori wí pé ọmọ rere ni Shettima jẹ́ lọ́dọ̀ àwọn gbogbo ohun tí àwọn ní ni àwọn yóò fi jà fún un.
Báyìí ni àwọn àgbààgbà òlóṣèlú ilẹ̀ wa ṣe túká níbi ìpádé náà tí ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàgò.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fìdí awuyewuye tó ti ń lọ nígboro tẹ́lẹ̀ múlẹ̀ pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kò fẹ́ fi Shettima ṣe igbákejì rẹ̀ nínú ìdìbò ọdún 2027. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àhesọ ni èyí tẹ́lẹ̀ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé kò rí bẹ́ẹ̀, ó ti ń jọ pé bẹ́ẹ̀ ló rí báyìí.
Dọ́kítà Ijeoma Arodiogu; ẹni tó jẹ́ igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ẹ̀kun Gúùsù ti sọ ṣaájú àkókò yìí pé àhesọ ọ̀rọ̀ lásán tí kò fìdí múlẹ̀ ni pé Tinubu kò fẹ́ Shettima ní ipò igbákejì rẹ̀ nínú ètò ìdìbò ọdún 2027. Ó wí pé ìbáṣepọ̀ tó gún régé ló wà láàrín Tinubu àti Shettima.
Dọ́kítà Ijeoma ṣe àpèjúwe Shettima gẹ́gẹ́ bíi ọlọ́gbọ́n àti olóye tó mọ ètò ìlú tó sì ń fi ọgbọ́n rẹ̀ mú ìgbéga bá orílẹ̀-ède Nàìjíríà. Fún ìdí èyí, kò sí ohun tó le fa kí Tinubu ó ní òun kò fẹ́ ẹ ní sáà kejì.
Bákan náà ni olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí òfin ìfitónilétí; Daniel Bwala sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé òun kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ bí Tinubu fẹ́ yọ Shettima nínú ìdíje sáà kejì bí bẹ́ẹ̀ kọ́.
Lórí rògbodìyàn tó ṣẹlẹ̀ lánàá yìí, alága ẹgbẹ́ òṣèlù APC ti ìpínlẹ̀ Sokoto; Isa Acida kò gbin lórí ìhà tó kọ sí ọ̀rọ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tó jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun wí pé àwọn yóò foríkorí fikùnlukùn láti fi ẹnu kò lórí ẹni tí yóò díje du ipò ní ọdún 2027.
Discussion about this post