Ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé ní ìpínlẹ̀ Niger ti bá ọ̀nà mìíràn yọ báyìí, ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún òkú èèyàn tí wọ́n ti rí yọ báyìí.
Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń rí òkú èèyàn tó ń lé téńté lórí omi.
Igbákejì Gómìna ìpínlẹ̀ Niger; Yakubu Garba ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Mokwa tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti rinlẹ̀. Àwọn agbègbè tó tún kàn bẹ́ẹ̀ ni Tiffin Maza àti Anguwan Hausawa.
Garba wí pé Gómìnà ìpínlẹ̀ náà ló rán òun wá wo bí nǹkan ṣe rí ní àwọn agbègbè náà, ó wí pé òkú èèyàn tí wọ́n ti rí yọ báyìí ti lé ní ọgọ́rùn-ún.
Àwọn adóòlà ẹ̀mí ṣì ń wá àwọn èèyàn yòókù tí àwọn ẹbí wọn fi sùn pé wọn kò rí mọ́.
Ọ̀rọ̀ Garba tẹ̀síwájú pé kí àwọn èèyàn náà ó ṣe sùúrù fún ìjọba, ó wí pé ìjọba ti ń ṣe ètò àwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn èèyàn náà lásìkò yìí ná. Àwọn èyí tó ti wà nílẹ̀ báyìí yóò jẹ́ pínpín fún àwọn tọ́rọ̀ kàn.
Ó wí pé òun yóò jábọ̀ ipò tí ìlu náà wá fún Gómìnà tó rán òun wá. Bákan náà ló rọ àwọn aráàlú láti yé kọ́ ilé sí ojúdò àti etí odò ní èyí tó le fa irú ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé báyìí.
Ìròyin fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìdílé mẹ́tàlélógún ló ti parun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé yìí.
Ìròyìn nípa àwọn agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ wa:
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ wa tí wọ́n ti ìpínlẹ̀ Kano wá kópa nínú eré ìdárayá tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ogun ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀.
Ìròyìn fi yé wa pé ọgbọ̀n ni àwọn agbábọ́ọ̀lù náà tí wọ́n wá láti Kano, nígbà tí wọ́n ń padà lọ sí Kano ni ọkọ̀ wọn dànù tí ogún sì kú nínú wọn.
Orí afárá Dakatsalle tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Kura ní ìpínlẹ̀ Kano ni ìjàm̀bá náà ti wáyé. Ọkọ̀ wọn náà jábọ́ láti orí afárá náà sílẹ̀ tí ogún sì kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nínú wọn.
Wọ́n ti gbé àwọn mẹ́wàá tó yè náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Kura fún ìtọ́jú.
A kú ìmúra ọdún o!
Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu ti pàṣẹ kí wọn ó san owó oṣù Igbe fún àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ náà. Ó wí pé òun fẹ́ kí gbogbo wọn ó rówó fi ṣe ọdún Iléyá tó ń bọ̀ yìí.
Láti ìlú Mẹ́kà ni Gómìnà ti pàṣẹ náà nítorí pé ó wà ní hájì báyìí. Akọ̀wé rẹ̀; Malam Abubakar Bawa ló fi ọ̀rọ̀ náà léde lówùúrọ̀ yìí pé àwọn yóò san owó oṣù tó ń bọ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì oṣù Igbe.
Èyí ni ìgbà kẹ́ta tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto yóò san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ṣáájú kí oṣù ó tó parí nítorí ọdún.
Gómìnà Ahmed Aliyu wí pé ìrọ̀rùn àwọn ará ìlú òun ló jẹ òun lógún, òun fẹ́ kí gbogbo wọn ó ṣe ọdún ayọ̀ kí wọn ó rówó ṣe ọdún náà.
Ní ìpínlẹ̀ Ogun:
Awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé kan ló pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí ọkọ̀ rẹ̀ dànù. A gbọ́ pé awakọ̀ yìí pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ní ojú ọ̀nà máròsẹ̀ Sagamu sí Ijebu Ode.
Àná, Ọjọ́bọ, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni ìjàm̀bá yìí wàyé tó sì mú ẹ̀mí awakọ̀ náà lọ.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú pópó ìpínlẹ̀ Ogun; Babatunde Akinbiyi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀. Ó wí pé nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ àná ni ìjàm̀bá náà wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Sagamu sí Ijebu Ode.
Awakọ̀ náà gbẹ́mìí mìn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ náà farapa gidi gan-an ni ó sì ti wà ní ilé ìwòsàn ìjọba Ikenne.
Àwọn tí ìjàm̀bá náà ṣojú wọn wí pé awakọ̀ náà sá eré àsápajúdé ló fàá tó fi pàdánù ìjánu rẹ̀.
Ètò ìdìbò sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti àti Ọ̀ṣun:
Kééére o, àjọ tó ń ṣètò ìdìbò nílẹ̀ yìí; INEC ti dájọ́ tí wọn yóò di ibò sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti ìpínlẹ̀ Èkìtì.
Alága àjọ INEC; Mahmood Yakubu ló kéde àwọn ọjọ́ tí ìdìbò náà yóò wáyé lónìí, ó wí pé ìdìbò sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì yóò wáyé lógúnjọ́, oṣù Igbe nígbà ti ti ìpínlẹ̀ Èkìtì yóò wáyé lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù Ògún ọdún 2026.
Ìdìbò abẹ́lé ti inú ẹgbẹ́ òṣèlú yóò wáyé láàrín Ogúnjọ, oṣù Òwàrà sí ọjọ́ kẹwàá, oṣù Bélú ọdún yìí. Ó wí pé gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú gbọ́dọ̀ fi orúkọ olùdíje wọn ránṣẹ́ ní ó pẹ́ tán aago mẹ́fà, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Ọ̀pẹ ọdún 2025 tí a wà nínú rẹ̀ yìí.
Ìpolongo ìbò yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Ṣẹẹrẹ, ọdún 2026 yóò sì parí ní ìdìbò ku ọ̀la.
Gbogbo àlàkalẹ̀ yìí ni Mahmood ṣe àlàyé rẹ̀ níbi ìgbaniwọlé àwọn òṣìṣẹ́ àjọ INEC titun tó wáyé lanaa.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ilé tó dà wó:
Àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrí ti ṣe àwárí àwọn òkú mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan lábẹ́ èérún ilé tó dà wó ní Ota-Ona, Ikorodu. Orúkọ àwọn mọ̀lẹ́bí náà ni Maleek; ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, Ameerah; ọmọ ọdún mẹ́tàlá àti àbúrò bàbá wọn; Bolaji; ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ẹnìkan nínú mọ̀lẹ́bí náà tó wà lókè òkun ló ni ilé náà tí Bolaji sì ń báa mójútó o, lọ́jọ́ tí ilé yìí dà wó, Bolaji kó àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́yìn láti lọ ṣe àbẹ̀wò sí ilé náà kó tó di pé ó dà wó lé wọn lórí tí gbogbo wọn sì kú.
Àwọn èèyàn mẹ́wàá mìíràn tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ni wọ́n rí yọ jáde láàyé àmọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí tó ni ilé náà gan-an ló gbẹ́mìí mìn.




