Wọ́n ti rí Hamdiyyah Sharif ní ilé ìwòsàn ìjọba kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Zamfara. Ipò tó wà burú díẹ̀, kò lajú bẹ́ẹ̀ sì ni kò sọ̀rọ̀, àwọn ọlọ́pàá wí pé àwọn ló gba Hamdiyyah sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó jíi gbé.
A kò tíì le sọ nǹkan kan nípa bó ṣe rìn báyìí àfi bí ó bá lajú tó sì ṣe àlàyé.
Àná la mú ìròyìn wá pé Hamdiyyah di àwátì lẹ́yìn tó lọ ra oúnjẹ ní òpópónà ilé rẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Sokoto. Bó ṣe wá di èrò ilé ìwòsàn ní Zamfara ni kò tíì jẹ́ mímọ̀ báyìí.
Ta ni Hamdiyyah Sharif?
Hamdiyyah jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ní ìgboyà púpọ̀. Ìpínlẹ̀ Sokoto ni wọ́n bíi sí ibẹ̀ náà lò sì dàgbà sí.
Àwọn ohun tó máa ń kọ sí ojú òpó rẹ̀ náà ni ipò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ Sokoto àti àwọn àdojúkọ wọn, pàápàá àwọn obìnrin.
Gbogbo bí àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe máa ń wọ àárín ìlú wá ṣe ọṣẹ́ láìsí ìdíwọ́ kankan fún wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀ ni Hamdiyyah máa ń kọ nígbà mìíràn, a tún fi àwòrán kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.
Ní ọjọ́ kan, Hamdiyya ń bọ̀ láti ibi tó ti lọ gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí àwọn olè dá a lọ́nà, wọ́n lù ú lálùbami kí wọ́n tó tì í bọ́lẹ̀ láti inú kẹ̀kẹ́ maruwa lórí eré lẹ́yìn tí wọ́n ti gba gbogbo ohun tó wà lára rẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló mú kí Hamdiyya ó tún tẹpẹlẹ mọ́ àwọn ohun tó máa ń kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀. Èyí tó kó o sí wàhálà yìí ni fọ́nrán tó ṣe gbẹ̀yìn ní èyí tó ti ké sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ohun tó sọ nínú fọ́nrán náà ni wí pé àwọn agbésùnmọ̀mí ń wọlé jáde láìsí ìdíwọ́ kankan, àrà tó wù wọ́n ni wọ́n ń dá, tọ́sàn tòru sì ni wọ́n fi ń wọ ìlú wá ṣe ọṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Hamdiyya wí pé àwọn obìnrin tí wọ́n ti sọ di aláìlọ́kọ mọ́ ń jìyà kiri abúlé ni, bí wọ́n bá tún wá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí olú ìlú ní àwọn ibùdó aláìnílé, níṣe ni wọ́n ń bá wọn sùn ní tìpátìkúùkú níbẹ̀’
Hamdiyya dárúkọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu nínú fọ́nrán náà pé kó wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Láti ìgbà tó ti ṣe fọ́nrán náà ni ìdààmú ti dé báa. Ilé ẹjọ́ Sharia ni wọ́n kọ́kọ́ gbé e lọ níbi tí ìjìyà rẹ̀ ó ti jẹ́ pípa àmọ́ àwọn lájọlájọ tó dá sí ọ̀rọ̀ náà ni wọ́n fi gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ ìjọba.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Hamdiyya ní ilé ẹjọ́ ìjọba ni pé ó bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Sokoto ní èyí tó tàbùkù ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto. Wọ́n ní ó pe Gómìnà Ahmed Aliyu ní agbésùnmọ̀mí ó sì bà á lórúkọ jẹ́.
Láti inú oṣù Bélú ọdún tó kọjá ni ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní àǹfààní àtilọ ilé. Òní ilé ẹjọ́, ọ̀la ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Hamdiyyah ń kojú láti ọdún tó kọjá.
Àwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn àti agbẹjọ́rò rẹ̀ ṣe àlàyé oríṣìí àdojúkọ tí wọ́n ń kojú lórí ọ̀rọ̀ Hamdiyyah yìí. Agbẹjọ́rò rẹ̀ wí pé oríṣìí ìpè ni òun máa ń gbà tí wọ́n fi ń halẹ̀ mọ́ òun pé kí òun ó jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà, ó wí pé àìmọye ìgbà ni wọ́n ti dá òun lọ́nà tí wọ́n sì ṣe òun báṣubàṣu pé kí òun o jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà.
Pabambarì rẹ̀ ni pé ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto gbé ẹjọ́ náà kúrò ní ìpínlẹ̀ Sokoto lọ sí ìpínlẹ̀ mìíràn ní èyí tó mú kí ó nira fún Hikima tó jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ láti kàn sí i.
Àwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn láti òkè òkun ló dá sí ọ̀rọ̀ náà kí wọ́n tó gba onídùúró rẹ̀ láìpẹ́ yìí.
Àdúrà tí gbogbo abiyamọ ń gbà báyìí ni pé kí ara rẹ̀ ó bọ́ sípò nílé ìwòsàn náà.
Lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí kan náà ni Gómìnà Zulum ti ìpínlẹ̀ Borno ṣe fi èsùn kan àwọn olóṣèlú pé àwọn ni wọ́n ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno; Babangana Zulum ti sọ gudugbẹ ọ̀rọ̀ lónìí nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn News central. Ó fi ẹ̀sùn kan àwọn olóṣèlú pé àwọn ni wọ́n ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ tí wọ́n fi ń ṣe gbogbo àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe náà.
Gómìnà Zulum wí pé kìí ṣe àwọn olóṣèlú nìkan kọ́ ló ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́, àwọn ológun náà ń fún wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn aráàlú. A kò ní fi ààyè gba gbogbo pálapàla yìí mọ́ báyìí, ẹni tí a bá mú yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu. Bí ìjọba bá kò sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí, kò le tó oṣù mẹ́fà tí a ó fi rẹ́yìn wọn àmọ́ ìjọba ti ki òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ náà – Zulum ló sọ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pe ‘ àwọn agbésùnmọ̀mí tí a ti mú tí wọ́n sì ti ronú pìwàdà ń ṣe dáadáa báyìí, wọn kò lọ́wọ́ nínú àwọn ìkọlù tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n ti ronú pìwàdà tí wọ́n sì ti di èèyàn ire láwùjọ. Gómìnà Zulum wí pé ‘ mo gbé oríyìn fún àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ wa lórí gbogbo akitiyan wọn láti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí yìí àmọ́ ìjọba kò pèsè àwọn ohun ìjà tó kúnjú òṣùwọ̀n fún wọn ni wọn kò ṣe le ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Ààrẹ̀ Bola Ahmed Tinubu ní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn ń sọ fún un lórí bí ó ṣe le borí àwọn agbésùnmọ̀mí yìí, kò yẹ kí wọn ó ti òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀mí ṣòfò yìí. Gbogbo àwọn àlàkalẹ̀ tí a ń gbé síwájú ààrẹ ni ó ń fi ọwọ́ gbá dànù, Zulum wí pé àfi kí ààré Bola Ahmed Tinubu ó gbọ́ ti àwọn bí ó bá fẹ́ ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí.
Discussion about this post