Ìròyìn tó gba àwọn ojú ìwé ìròyìn kan láàárọ̀ yìí ni ikú arábìnrin Agbakaizu; ẹni tó jẹ́ akàròyìn ní ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ìpínlẹ̀ Ogun, OGTV. A gbọ́ pé arábìnrin Agbakaizu ń múra àti lọ ka ìròyìn nínú ilé iṣẹ́ náà ni ó ṣubú lulẹ̀ tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú.
Akọ̀wé àjọ àwọn oníròyìn, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ogun; Ọ̀gbẹ́ni Bunmi Adigun ló túfọ̀ ikú arábìnrin Agbakaizu lálẹ́ àná.
Gbogbo akitiyan láti jíi sáyé kò yọrí sí rere, àwọn dọ́kítà ilé ìwòsàn ìjọba tí wọ́n gbé e lọ wí pé ó ti kú kí wọ́n tó gbé e dé.
Ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta ni arábìnrin Agbakaizu lásìkò ikú rẹ̀, ọmọ méjì àti ìyá ló fi sílẹ̀ sáyé lọ.
Ní ìpínlẹ̀ Èkó:
Ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Dọ́kítà Ibijoke Sanwoolu pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àjọ Orunsii ti ṣètò owó iyebíye fún àwọn ọmọdé tí wọ́n nílò iṣẹ́ abẹ ní ilé ìwòsàn ìjọba mẹ́ta.
Dọ́kítà Ibijoke ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn Odan Marina, Femi Gbajabiamila àti ilé ìwòsàn ìjọba Igando lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọ̀sẹ̀ yìí.
Dọ́kítà Ibijoke Sanwoolu ṣe àlàyé pé ètò iṣẹ́ abẹ ọ̀fẹ́ yìí wà ní ìlànà pẹ̀lú àfojúsùn ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ Gómìnà láti bá àwọn òbí tó kù díẹ̀ káàtó fún gbé ẹrù wọn pàápàá ní abala ìlera. Bákan náà ló ké sí àwọn lájọlájọ láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn aláàárẹ̀ nílé ìwòsàn ìjọba káàkiri.
Kéére ooooooo!
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí bí owó ilé sísan ó ṣe di olóṣooṣù dípò ọlọ́dọọdún tí a ń lò lọ́wọ́.
Wọ́n ní èyí yóò mú ìrọ̀rùn bá àwọn èèyàn pàápàá àwọn tí owó oṣù wọn kò gara láti le máa san owó ilé wọn lóṣooṣù dípò tí wọn ó fi máa sáré níparí ọdún.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ilé; Moruf Akinderu-Fatai ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ níbi àpéjọ àwọn oníròyìn tó wáyé ní ilé iṣẹ́ Gómìnà.
Moruf wí pé àwọn ti ń bá àwọn onílé sọ̀rọ̀ lórí ètò yìí láti jọ jíròrò lórí àdojúkọ tí ètò yìí le mú dání kí wọ́n tó sọ ọ́ di òfin. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ síbi pé ọ̀kan léyìí jẹ́ nínú àwọn ètò máyédẹrùn tí ìjọba ní lọ́kàn fún wa.
Ìdáwò JAMB ọdún yìí.
Látàrí bí ogúnlọ́gọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe fìdí rẹmi nínú ìdánwò àṣewọ-ilé-ìwé gíga JAMB ọdún yìí, àjọ JAMB ti wí pé òun yóò ṣe àtúnwò èsì idánwò náà.
Wọ́n wí pé àpapọ̀ àwọn olùkọ́ ilé ìwé gíga, àwọn lọ́gàálọ́gàá àti gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn ni yóò pejú ṣe àtúnwò náà. Ìdí ni pé àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn òbí ló faju ro sí èsì ìdánwò JAMB ọdún yìí, ọ̀pọ̀ wọn ló fìdí rẹmi.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi ẹ̀sùn kan àjọ JAMB pé kìí ṣe èsì àwọn ni wọ́n gbé jáde nítorí pé ojú òpó kò já geere lọ́jọ́ tí àwọn ṣe ìdánwò náà.
Kódà, níbi àpéjọ tí adarí àjọ JAMB ti kéde èyí tó sì ti tọrọ àforíjì, nịṣe ló bú sẹ́kún níbi ti ọ̀rọ̀ náà káa lára dé. Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ó sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ wọn.
Ní báyìí, àtúnwò náà ti bẹ̀rẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ti ń rí àtẹ̀jíṣẹ́ pé kí wọn ó wá tún ìdánwò náà kọ. Àtúnṣe yìí wúlò fún àwọn tó wà láyé ni, kò le jí akẹ́kọ̀ọ́ tó ti pa ara rẹ̀ nítorí èsì ìdánwò náà.
Ọmọ wa ò ní sọnù o!
Obìnrin kan tí ó ń tọ́ ọmọ oṣù méjì lọ́wọ́ ló gbé ọmọ náà fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀; ọmọ ọdún méjì ní iwájú ilé rẹ̀ tó sì lọ ra nǹkan páà ní ilé kejì ló ti pariwo síta báyìí nígbà tó dé tí kò rí ọmọ oṣù méjì náà mọ́.
Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó gbé ọmọ náà fún kò le ṣe àlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, ọwọ́ nìkan ló ń nà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ ní ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí ní àdúgbò kan tí wọ́n ń pè ní Gbeleju.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo; Olayinka Alayande fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ pé àwọn gba ìfisùn náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ní ìpínlẹ̀ Kastina:
Ọwọ́ ti tẹ obìnrin kan ẹni ọdún mọ́kànlélógún tó ń kó ìbọn wọ ìpínlẹ̀ Kastina. Láti ìpínlẹ̀ Nasarawa ni Fatima Salisu ti máa ń lọ kó ìbọn fún àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní Kastina. Irinwó ìbọn kékeré àti ọ̀kànlélọ́gọ́rin ìbọn gígùn ni wọ́n bá lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n dáa dúró.
Fatima ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá báyìí títí ìwádìí yóò fi parí.
Ní ìpínlẹ̀ Kwara:
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti ti ilé ìwé girama ìjọba Government High school àti ilé ìwé Government day secondary school tí wọ́n wà ní Adeta, Ìlọrin ní olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.
Ìdí ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé méjéèjì yìí ń ṣe ìkọlù síra wọn, ìjà ojoojúmọ́ àti wàhálà ni wọ́n ń fà, ìjọba Kwara ti pàṣẹ báyìí pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé méjéèjì náà ó wà nílé ti àwọn òbí wọn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe ìdánwò àṣekágbá nìkan ni wọn yóò ní àǹfàáni àti wọ inú ilé ìwé.
Ìkìlọ̀ ni pé akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá mú tí kìí ṣe onídànwò àṣekágbá yóò jìyà lọ́wọ́ ìjọba.
Ó mà ṣe o!
Ìjàmbá ọkọ̀ kan tó wáyé ní òpópónà Trade fair sí Agbara burú jáì. Ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan ló mú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Lexus kan gùn mọ́lẹ̀, èèyàn kan gbẹ́mìí mìn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn méjì mìíràn farapa yánnayànna.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu olùlanilọ́yẹ ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú pópó, ti ìjọba àpapọ̀; Elizabeth Jayeola.
Arábìnrin Elizabeth Jayeola ṣe àlàyé pé àwọn ọkùnrin márùn-ún ló wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà, ọ̀kan kú, méjì farapa nígbà tí àwọn méjì yòókù wà ní àlàáfíà.
Ohun tó ṣe òkùnfà ìjàmbá náà gẹ́gẹ́ bí arábìnrin Elizabeth Jayeola ṣe sọ ni eré àsápajúdé tí awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé náà sá. Bí ọ̀nà náà ṣe tẹ́ tó sì já geere tó, eré tí awakọ̀ náà sá ti pọ̀ jù ló fàá tó fi pàdánù ìjánu rẹ̀.
Ilé ìwòsàn Alimosho ni wọ́n gbé àwọn méjì tó farapa náà lọ, ẹnìkan tó kù náà há sí inú ọkọ̀ náà ni, wọn kò ríi yọ wọ́n sì wọ́ àtòhun àtọkọ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá Ijanikin.
Ilé iṣẹ́ FRSC wí pé ìṣẹ́jú mẹ́rin péré ni àwọn lò tí àwọn fi dé sí ibi ìjàmbá náà, wọ́n sa ipá wọn àmọ́ ọkùnrin tó kú náà há sínú èérún ọkọ̀ náà ni.
FRSC rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé.
Discussion about this post