Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkìtì ti dájọ́ ikú fún David Isaiah fún ẹ̀sùn ìpànìyàn. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni David, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án ni pé ó jí Comfort James gbé ó sì tún gba ẹ̀mí rẹ̀.
Saviour Daniel tí wọ́n jọ ṣekú pa Comfort ti kú sí àgọ́ ọlọ́pàá kí ìgbẹ́jọ́ tó parí. Adájọ́ pàṣẹ pé kí wọn ó sọ David sí ẹ̀wọn ọdún mọ́kànlélógún fún ẹ̀sùn ìjínigbé kí wọn ó sì so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀ fún ẹ̀sùn ìpànìyàn lẹ́yìn gbogbo atótónu.
Ọ̀kan nínú àwọn gbélépawó ilé ìtura Afrika ni Comfort, lọ́jọ́ náà, Comfort pe àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé ìtura náà pé wọ́n ti jí òun gbé o wọ́n sì ń bèèrè fún ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀run náírà owó ìtúsílẹ̀.
Irona; ẹni tó ni ilé ìtura náà ní àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún òun pé Comfort kò padà dé láti ìgbà tí oníbàárà kan ti gbé e lọ. Irona ní òun fi tó àwọn agbófinró létí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Comfort ni àwọn ọlọ́pàá fi tọpinpin àwọn tó gbé e lọ, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá dé ibi tí wọ́n sọ òkú rẹ̀ sí, ìgbẹ́jọ́ sì bẹ̀rẹ̀.
Àwọn akẹgbẹ́ Comfort mẹ́fà ló jẹ́rìí síi nílé ẹjọ́ pé David ni ẹni tó wá gbé Comfort lọ lọ́jọ́ náà.
Àlàyé tí David fúnra rẹ̀ ṣe kò tako ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí, ó ní lẹ́yìn tí òun àti èkejì òun; Daniel bá Comfort lò pọ̀ tán, àwọn so ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì àwọn sì fi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ pe àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ pé kó bèèrè owó ìtúsílẹ̀. David ní nígbà tí owó kò jáde ti ó sì ti rí ojú àwọn ni àwọn ṣe da ásíìdì lée lórí tó sì kú, lẹ́yìn náà ni àwọn lọ ju òkú rẹ̀ nù.
Adájọ́ Olalekan Olatawura wí pé kò sí àriyànjiyàn mọ́ lórí ẹjọ́ náà, ẹni tó gbé panla ti jẹ́wọ́, ó gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ ó sì gbàá ládùúrà fún un pé kí Ọlọ́run ó ṣe ìdáríjì fún ẹ̀mí rẹ̀.
Nípa Verydarkman.
Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu àti ìṣowóòlúmọ́kumọ̀ku; EFCC ti fèsì sí awuyewuye tí ó ń lọ lórí bí wọ́n ṣe gbé Vincent Otse tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Verydarkman.
Wọ́n sọ̀rọ̀ láti ẹnu ọ̀kan nínú àwọn agbẹnusọ wọn; Dele Oyewale pé àwọn ìfisùn tí àwọn gbà nípa Verydarkman láti ọ̀dọ àwọn ará ìlú ni àwọn torí ẹ̀ gbé e, wọ́n ní àwọn èèyàn fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn pé ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn lórí ìtàkùn ayélujára, dandan sì ni kí àwọn ó dáàbò bo àwọn aráàlú.
Àjọ EFCC wí pé bí ó bá ti ṣètò àtigba onídùúró rẹ̀ náà ni àwọn yóò fi sílẹ̀ àmọ́ àwọn ń gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ láìpẹ́ yìí.
Bákan náà ni wọ́n ní ilé ìfowópamọ́ GT kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú gbígbé tí àwọn gbé Verydarkman yìí.
Ní ìpínlẹ̀ Nasarawa:
Ọkọ̀ kan tí ọ̀gbẹ́ni Abu Agyeme ti patì sínú ọgbà rẹ̀ ni àwọn ọmọdé márùn-ún kan kú sínú rẹ̀, ohun tí àwọn ọlọ́pàá rí dìmú ni pé bóyá wọ́n ń ṣeré nínú ọkọ̀ náà ni ó tì pa mọ́ wọn nítorí pé àyẹ̀wò dọ́kítà fi hàn pé ooru ló pa wọ́n.
Agbègbè Agyaragu ní ìjọba ìbílẹ̀ Obi ní ìpínlẹ̀ Nasarawa ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa; Rahman Nansel ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ láàárọ̀ yìí pé àwọn gba ìpé nípa ikú àwọn ọmọdé márùn-ún tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá lọ.
Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn Aro níbi tí dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ooru ló ṣekú pa àwọn ọmọ náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa; Shetima Jauro-Mohammed ti pàṣẹ kí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ó wáyé lórí ikú àwọn ọmọ náà.
Kọmíṣọ́nà bá àwọn òbí àwọn ọmọ náà kẹ́dùn, ó kí wọn kú àmúmọ́ra.
Ní kété tí dọ́kítà parí àyẹ̀wò ni wọ́n yọ̀ǹda òkú wọn fún àwọn òbí wọn nítorí pé ara wọn ti sè.
Oladipupo ti padà dé o:
Oladipupo Sijuola, akẹ́kọ̀ọ́ ilé iwé Babcock tó wà ní Ilishan ti padà dé o lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ariwo lórí ìtàkùn ayélujára.
Bí ẹ bá ń fi ọkàn bá wa lọ, orí ìtàkùn ayélujára fẹ́rẹ̀ gbiná lọ́sẹ̀ tó lọ yìí nígbà tí gbogbo ojú òpó ń bèèrè fún àwárí Oladipupo. Ìyá rẹ̀; arábìnrin Fijabi Oyindamola Omotayo ló fi omijé wẹ gbogbo ojú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nígbà tí ó ń wá ọmọ rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ṣeni láàánú àwọn èèyàn sì ṣúgbà rẹ̀ láti kojú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, olùbádámọ̀ràn Gómìnà Dapo Abiodun, gbogbo wọn ló ṣe ìlérí àtiṣe àwárí ọmọ náà.
Ní báyìí, Oladipupo ti padà dé, ìyá rẹ̀ ti kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé ó ti dé bẹ́ẹ̀ sì ni a rí fọ́nrán bí wọ́n ṣe fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i gan-an ní pàtó àti ibi tí ó wà fún àwọn ọjọ́ yìí kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Àwọn ọlọ́pàá tún gbé ìṣe wọn dé o
Nínú fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan láàárọ̀ yìí ni a ti rí àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ wa tí wọ́n ki ọ̀dọ́mọkùnrin kan mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì ṣe é bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú.
Ẹnìkan tí ojú òpó rẹ̀ ń jẹ́ General_Somto ló fi fọ́nrán yìí sí orí ìtàkùn ayélujára, nínú rẹ̀ ni a ti rí àwọn ọlọ́pàá méjì kan pẹ̀lú aṣọ lọ́rùn tí wọ́n ń lu ọ̀dọ́mọkùnrin náà tí wọ́n sì ń gbá ìdí ìbọn mọ́ ọn lórí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fèsì sí fọ́nrán yìí pé kí General_Somto ó fi ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tis ̣ẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn kí ó le ran ìwádìí àwọn lọ́wọ́.
A kò tíì le ṣe ìdámọ̀ àwọn ọlọ́pàá inú fọ́nrán náà lásìkò yìí.
Discussion about this post