Arábìnrin Fijabi Oyindamola Omotayo ti ké gbàjarè síta lórí ọmọ rẹ̀ tó di àwátì lẹ́yìn tó gbé e lọ sí ilé ìwé.
Ilé ìwé gíga Babcock tó wà ní Ilishan-Remo, ìpínlẹ̀ Ogun ni ọmọ náà ń lọ, Oladipupo Sijuola sì ni orúkọ rẹ̀.
Ìyá rẹ̀ wí pé fúnra òun lòun gbé e lọ sí ilé ìwé náà ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe tó lọ yìí. Ó ní ojú òun ló ṣe wọ inú ọgbà ilé ìwé náà lọ tí òun sì padà sílé.
Arábìnrin Fijabi ní òun pe ọmọ òun lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta àmọ́ kò gbé aago, láti ìgbà náà ni òun kò ti ríi bá sọ̀rọ̀ tí òun kò sì gbúrǒ rẹ̀ títí di àsìkò yìí.
Ìyá Oladipupo ní òun wá a lọ sí ilé ìwé ní àná, ọjọ́ kejì, oṣù Èbìbí àmọ́ wọ́n sọ fún òun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ a máa farasin sínú ọgbà ilé ìwé nígbà mìíràn pé kò sí ohun tó le ṣe ọmọ náà.
Ìyá Oladipupo kò fara mọ́ ohun tí Babcock sọ yìí, ó ní kí wọn ó wá ọmọ òun jáde ni. Bákan náà ló bèèrè pé kín ni ìdí tí wọ́n fi gbé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì tó ríi gbẹ̀yìn; Lampard àti Tobi pamọ́?
Ní èsì sí ọ̀rọ̀ yìí, olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà Dapo Abiodun lórí àtẹ̀jáde; Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Ojo wí pé òun ti kàn sí kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, kọmíṣọ́nà sì ti kàn sí ọ̀gá ilé ìwé náà láti wá bí ọmọ náà ṣe rìn.
Ọ̀gá àgbà ilé ìwé Babcock wí pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni òun sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lé e lórí.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogunlowo náà wí pé àwọn ti gba ìfisùn náà, ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí bí wọn yóò ṣe wá ọmọ náà rí.
Ìròyìn mìíràn tó gbòde ni ti ìdájọ́ awakọ̀ tó ṣekú pa Bamishe Ayanwola tí adájọ́ gbé kalẹ̀ nílé ẹjọ́ gíga Èkó.
Awakọ̀ BRT tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ṣekú pa Oluwabamishe Ayanwola ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkó ti dá ẹjọ́ ikú fún lọ́jọ́ kejì, oṣù Èbìbí.
Andrew Ominikoron ni orúkọ awakọ̀ BRT náà, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án ni pé ó bá Bamishe ní àjoṣepọ̀ tìpátìkúùkú ó sì tún gba ẹ̀mí rẹ̀.
Ẹni ọdún méjìlélógún ni Bamishe, ní ọjọ́ náà lọ́hùn-ún, Bamishe ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ ó sì wọ ọkọ̀ BRT tí Andrew jẹ́ awakọ̀ rẹ̀. Ohùn tó fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípa bí Andrew ṣe gbé àwọn èèyàn kan lọ́nà àti bí ara ṣe fu ú ni ó jẹ́ ẹ̀rí nígbà tí wọ́n rí òkú rẹ̀.
Àti ìgbà náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn obìnrin mìíràn tó ti fipá bá lò pọ̀ sì jáde sọ̀rọ̀.
Adájọ́ Sherifat Sonaike gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà pé Andrew jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Àwọn ẹbí Bamishe dunú sí ìdájọ́ yìí àmọ́ ó kù ni ìbọn ń ró.
Àwọn ẹbí Bamishe Ayanwola bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tí adájọ́ gbé kalẹ̀ lánàá.
Ẹ̀gbọ́n Bamishe tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Onaopemipo Damilola wí pé àwọn dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Adájọ́ Sherifat Sonaike lórí ìdájọ́ òdodo tó gbé kalẹ̀ àmọ́ àwọn tí wọ́n jọ pa Bamishe kò jẹ́jọ́ rárá.
Damilola wí pé àwọn yóò fẹ́ kí àwọn méjì tí wọ́n jọ pa ọmọ náà ó fojú ba ilé-ẹjọ́ kí wọ́n má mu un jẹ.
Ètò ìsìnkú Ayo Adebanjo:
Wọ́n ti ṣe ètò ìsìnkú bàbá Ayo Adebanjo báyìí o. Ayo Adebanjo ni aṣáájú ikọ̀ Afenifere ṣáájú ikú rẹ̀.
Níbi ètò ìsìnkú náà tó wáyé ní òní, ọjọ́ àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹta oṣù Èbìbí ní Isanya Ogbo ní ìjọba ìbílẹ̀ Odogbolu, ìpínlẹ̀ Ogun ni a ti rí Olóyè Olusegun Obasanjo àti Ọ̀mọ̀wé Yemi Osinbajo.
Iná jó ní Sango, Ibadan.
Kò dín ní ìsọ̀ mẹ́ta tí iná ti jó kanlẹ̀ ní Sango, Ìbàdàn lónìí. Ohun tí a gbọ́ ni pé iná náà sẹ́yọ nígbà tí wáyà iná ẹ̀rọ fírísà kan ràn mọ́ ara wọn.
Ẹ̀yìn ilé epo Fart ní Sango ni àwọn ìsọ̀ bíi mẹ́wàá náà wà, nǹkan bíi aago mẹ́rin àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni iná náà sẹ́yọ tó sì mú ìsọ̀ mẹ́
ta balẹ̀ tán gúrúgúrú.
Kò sí ẹni tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àmọ́ àwọn ọjà bíi ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí iye rẹ̀ tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù náírà ni ó jóná gúrúgúrú.
Yemi Akinyinka; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn ta mọ́ra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí àwọn gba ìpè náà, nígbà tí àwọn dé ibẹ̀, iná náà ti wà lórí ìsọ̀ kẹta àmọ́ àwọn kojú rẹ̀ kò sì mú ìsọ̀ mìíràn.
Ìwádìí fi hàn pé iná náà sẹ́yọ láti ara fírísà kan tí okùn rẹ̀ ràn mọ́ iná tó sì yára ràn mọ́ àwọn nǹkan mìíràn.
LASTMA ṣe ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n:
Àjọ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú pópó ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Èkó; LASTMA ti fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ méjìlá wọ́n sì tún rọ àwọn mọ́kàndínlógún mìíràn lóyè lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ṣe aṣemáṣe lẹ́nu iṣẹ́.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún àjọ LASTMA; Adebayo Taofik pé yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n dá dúró àti àwọn tí wọ́n rọ̀ lóyè yìí, àwọn mẹ́tàdínlógún mìíràn ni wọ́n fún ní ìwé ìfanilétí lórí aṣemáṣe yìí kan náà.
Níbi ayẹyẹ ọdún kẹẹ̀dọ́gbọ̀n tí wọ́n ti dá àjọ LASTMA sílẹ̀ ni ọ̀gá àgbà àjọ náà; Ọ̀gbẹ́ni Olalekan Bakare-Oki ti sọ pé àjọ náà kò ní fi ààyè gba ìwà ìbàjẹ́ tàbí ìwàkiwà lábẹ́ ìsàkóso òun.
Discussion about this post