Ní agbègbè Ajowa Akoko ní ìpínlẹ̀ Ondo, nǹkan ò fara rọ fún arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Monday Elela àti àwọn ẹbí rẹ̀. Ọmọ Monday tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Tope ni Monday àti ìyàwó rẹ̀ titun lù pa nítori pé ọmọ náà burú. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni Tope lásìkò ikú rẹ̀ yìí.
Àlàyé tí a rí gbà nípa irú ọmọ tí Tope jẹ́ ni pé ó máa ń fẹ́wọ́ ó sì máa ń jà kiri àdúgbò, ó ti sun àgọ́ ọlọ́pàá àti ìbudó àmọ̀tẹ́kùn lọ́pọ̀ ìgbà.
Lọ́jọ́ tí ó dé láti ibùdó àwọn àmọ̀tẹ́kùn ni bàbá rẹ̀ Monday àti ìyàwó bàbá rẹ̀ lù ú lálùpa tí wọ́n sì sin ín sí ẹ̀yìnkùlé ní ìdájí ọjọ́ kejì kí àwọn ará àdúgbò tó jí.
Lọ́gán tí wọ́n sin ọmọ náà tán ni ìyàwó bàbá rẹ̀ yìí ti sá lọ tèfètèfè. Àlàyé tí Monday ṣe fún àwọn èèyàn ni pé ọmọ náà jẹun ní alẹ́, òun sì fún un ní ìgbátí díẹ̀ nítorí ìwà tó hù àwọn sì wọlé lọ sùn àmọ́ kò jí láàárọ̀.
Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá hú òkú ọmọ náà, àwọn àpá ńlá ńlá tó jinú ló kún ara rẹ̀ láti orí, ní èyí tó tọ́ka sí pé kìí ṣe lílù nìkan ni wọ́n lu ọmọ náà.
Tope ni ọmọ kẹta nínú àwọn ọmọ méje tí bàbá rẹ̀ bí, bàbá rẹ̀ ní òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé òun kò gbèrò àti pa á.
Àjọ tó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé ní ìpínlẹ̀ Òǹdó tako àlàyé tí Monday ṣe yìí, wọ́n ní àwọn àpá ara ọmọ náà fi hàn pé wọ́n ṣe ọmọ náà báṣubàṣu ni ó kọjá ìbọ́mọwí.
Wọ́n ní ìlú tí lílu omọ kò bá ti kí ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀, a kò le fẹ́ irú eléyìí kù nítorí wọn yóò fi ìbáwí kẹ́wọ́ ṣe ọmọ báṣubàṣu.
Bákan náà ni wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn àmọ̀tẹ́kùn fún lílu ọmọ náà tó fi di ẹni tó ní àpá lára, wọ́n ní àwọn àpá kan ti jinná lára rẹ tó sì jẹ́ pé nígbà tí àwọn àmọ̀tẹ́kùn gbé e ni wọ́n fún un láwọn àpá náà.
Àwọn alábàágbé Tope ṣe àlàyé irú ọmọ tó jẹ́, wọ́n ní gbogbo ìgbà ló máa ń rẹ́rìn-ín tí inú rẹ̀ sì má ń dùn, wọ́n ní Tope ló máa ń pọn omi sí ilé wọn kò le má pọn omi láàárọ̀ ojúmọ́ kan àmọ́ kò sí ẹni tó rò pé yóò kú lásìkò yìí.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òǹdó; Wilfred Afolabi ti dá sí ọ̀rọ̀ yìí, ó wí pé àwọn ti da àwọn ọlọ́pàá síta láti wá ìyáwó Monday tí wọ́n jọ pa ọmọ náà síta. Wọ́n sì ti gbé òkú Tope lọ fún àyẹ̀wò, Ó ní òfin yóò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí iṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Àwọn ọmọ ìyá Tope mẹ́fà yòókù ti fọ́nká sí ilé àwọn mọ̀lẹ́bí lásìkò yìí ná.
Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó fara pẹ́ èyí ni ti bàbá kan tó da omi gbígbóná jó ẹsẹ̀ ọmọ rẹ̀ ní Kaduna.
Abubakar Sani ni orúkọ ọmọ yìí, ọmọ ọdún méje péré ni. Bàbá rẹ̀ so ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì pọ̀ ó sì da omi gbígbóná tí a sọ̀ kalẹ̀ tààrà láti orí iná jó ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì ó sì tìí mọ́lé fún odidi ogún ọjọ́ láìsí oúnjẹ tàbí omi. Ẹ̀sùn tó fi kan ọmọ náà ni pé ó jí bisikíìtì.
Ẹsẹ̀ Abubakar méjéèjì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹrà débi pé ó ń yọ ìdin síbẹ̀ bàbá rẹ̀ kò ṣíi sílẹ̀, àwọn kòkòrò àìfojúrí ti wọ inú ẹsẹ̀ náà ó sì ti wọ inú egungun débi pé ó wú gelete, gbogbo awọ ẹsẹ̀ náà ti bó, ó kọjá àfẹnuròyìn.
Àwọn ará ilé máa ń gbọ́ igbe rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àmọ́ wọn kò fi ọkàn síi, nígbà tó ti ṣe díẹ̀ tí wọ́n rí ọmọ náà kó jáde síta ni wọ́n bèèrè rẹ̀ àmọ́ bàbá rẹ̀ ní kò sí ohun tó ṣe é. Àwọn ará ilé ló ké sí àwọn agbófinró pé ọmọ kan ti sọnù nínú ilé náà, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé inú ilé náà, wọ́n ní láti já ìlẹ̀kùn yàrá tí wọ́n ti ọmọ náà mọ́, nígbà tí wọ́n gbé e dé ilé ìwòsàn Barzu Dikko, àwọn dọ́kítà wí pé àwọn kòkòrò àìfojúrí ti jẹ àwọn ẹsẹ̀ méjéèjì kọjá àtúnṣe, wọ́n ní láti gé ẹsẹ̀ méjéèjì. Kò tán síbẹ̀ o, ọmọ yìí tún ní àwọn òògùn tí yóò lò láti fọ àwọn kòkòrò náà kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ náà.
Maishago; bàbá Abubakar wí pé kò sí ohun tó burú nínú bí òun ṣe bá ọmọ òun wí fún olè tó jà. Ó ní òun lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ọmọ òun wí bí òun bá ṣe fẹ́, ó ní ómọ náà kìí gbọ́ràn ó sì burú ó tún wá jalè, nítorí náà, kò sí ohun tó burú nínú bí òun ṣe bá a wí nítorí pé ẹ̀sìn òun fi ààyè gba ìbọ́mọwí.
Kọmíṣọ́nà Rabi Salisu wí pé òun kò faramọ́ àwíjàre Maishago yìí, ó ní àwọn yóò jẹ́ kí tiẹ̀ ó jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn òbí yòókù pé kò sí ààyè fún ìṣọmọ báṣubàṣù lábẹ́ bótiwù kó rí.
Bákan náà ni a gbọ́ pé bàbá kan náà lu ọmọ rẹ̀; ọmọ́ ọdún méjì pa ní Bayelsa.
Ìyá rẹ̀ ti kọ bàbá rẹ̀ sílẹ̀, ó fi ọmọ náà sílẹ̀ ti bàbá rẹ̀ nínú yàrá kan. Àwọn ará ilé ní àwọn máa ń gbọ́ igbe ọmọ náà àmọ́ kò sí ẹni tó kọbi ara síi. Gbogbo ìgbà tí inú bá ti bí Vwede ni yóò ki ọmọ náà mọ́lẹ̀ tí yóò sì máa lù ú nílùkilù.
Lọ́jọ́ kan, ó tún ki ọmọ náà mọ́lẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lù ú bí ìṣe rẹ̀, nígbà tó ríi pé kò mí mọ́, ó gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Answer tó wà ní òpópónà Ruthmore àmọ́ wọ́n lọ́mọ náà ti kú kó tó gbé e dé.
Vwede ti sá lọ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ṣì ń wá a.
Discussion about this post