Awakọ̀ BRT tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ṣekú pa Oluwabamishe Ayanwola ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkó ti dá ẹjọ́ ikú fún lónìí, ọjọ́ kejì, oṣù Èbìbí.
Andrew Ominikoron ni orúkọ awakọ̀ BRT náà, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án ni pé ó bá Bamishe ní àjoṣepọ̀ tìpátìkúùkú ó sì tún gba ẹ̀mí rẹ̀.
Ẹni ọdún méjìlélógún ni Bamishe, ní ọjọ́ náà lọ́hùn-ún, Bamishe ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ ó sì wọ ọkọ̀ BRT tí Andrew jẹ́ awakọ̀ rẹ̀. Ohùn tó fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípa bí Andrew ṣe gbé àwọn èèyàn kan lọ́nà àti bí ara ṣe fu ú ni ó jẹ́ ẹ̀rí nígbà tí wọ́n rí òkú rẹ̀.
Àti ìgbà náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn obìnrin mìíràn tó ti fipá bá lò pọ̀ sì jáde sọ̀rọ̀.
Òní ni Adájọ́ Sherifat Sonaike gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà pé Andrew jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
ÌKỌLÙ ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN:
Àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ òkunkùn ṣe ìkọlù síra wọn ní Owode Ajegunle ní ìpínlẹ̀ Èkó. Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan ń ṣígun lọ bá ikọ̀ mìíràn láti gbẹ̀san ikú ọ̀kan lára wọn, ọ̀nà ni wọ́n ti pàdé ikọ̀ mìíràn tí wọ́n sì kọjú ìjà síra wọn, ìkọlù yìí mú ẹ̀mí ọ̀kan lara wọn tí orúkọ ń jẹ́ Sparkle lọ.
Ọ̀kan lára àwọn ará àdúgbò ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé ìjà náà bèrẹ̀ nígbà tí àwọn ikọ̀ Eiye ṣekú pa ọmọ ẹgbẹ́ Buccaneer kan, ẹ̀san èyí ni wọ́n fẹ́ lọ gbà tí wọ́n fi pàdé ikọ̀ Aiye lọ́nà, èébú ni wọ́n kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ kí wọ́n tó sọ ọ́ dìjà nígbà tí ọ̀kan nínú wọn yìnbọn pa Spakle.
Eiye nígbà tí Aiye náà fẹ́ gbẹ̀san lára Buccaneer. Wọ́n ní inú fu àya fu ni àwọn wà nítorí pé ìgbàkúùgbà ni ìkọlù wáyé.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin ní òun kò mọ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Àwọn ará àdúgbò wí pé ìjà náà kò tíì parí nítorí pé ikọ̀ Buccaneer fẹ́ gbẹ̀san lára
NÍ ÌPÍNLẸ̀ BAUCHI: WỌ́N GÚN ÀLÁGA ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ JAMA’ARE TẸ́LẸ̀RÍ PA NÍLÉ ỌMỌ RẸ̀.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Jama’are tẹ́lẹ̀rí; Isa Muhammad Wabi ni àwọn ọ̀rẹ́ ọmọ rẹ̀ ti gún lọ́bẹ pa lóru mọ́jú.
Ìpínlẹ̀ Bauchi ni Jama’are wà, ohun tí a gbọ́ ni pé Isa lọ sí ilé ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, AbdulGafar Isa Muhammad, nígbà tó di nǹkan bíi aago méjìlá òru kọjá díẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ọmọ rẹ̀ méjì wọ́lé wá èdè àìyedè wáyé láàrín wọn ni wọ́n bá fi ọ̀bẹ gún un ní gbobo ọrùn.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi; Ahmed Wakil ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè láti ọ̀dọ ará ilé AbdulGafar pé wọ́n ti pa èèyàn śnú ilé náà. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ó di alága ìjọba ìbílẹ̀ Jama’are tẹ́lẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àpá ọ̀bẹ ní gbogbo ọrùn rẹ̀.
Ilé ìwòsàn Tafawa Balewa ni wọ́n gbé e lọ tó sì padà dákẹ́ sí. Ọwọ́ tẹ àwọn ọ̀rẹ́ ọmọ rẹ̀ méjéèjì náà; Ahmed AbdulKadir àti Faruk malami.
Wọ́n kò bá àwọn ọlọpàá jiyàn rárá, wọ́n láwọn ló gún un lọ́bẹ nígbà tí ọ̀rọ̀ dìjà láàrín wọn. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ní kété tí ìwádìí bá parí ni àwọn yóò fi ojú wọn ba ilé ẹjọ́.
ÌRÒYÌN ÒKÈRÈ:
Nọ́ọ̀sì kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà ni wọ́n rí òkú rẹ̀ nínú yàrá rẹ̀ ní UK. Nnena Miriam ni orúkọ nọ́ọ̀sì yìí, Leeds sì ni ó ń gbé ní UK. Àlàyé tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé Miriam kò lọ sí ibi iṣẹ́ rẹ̀ fún ọjọ́ díẹ̀ kò sì tún gbé ìpè rẹ̀, èyí ló mú kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ó ló fi ẹjọ́ sùn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá pé òun ń wá Miriam, àwọn ọlọ́pàá wáa lọ sí ilé rẹ̀ àmọ́ òkú rẹ̀ ni wọ́n bá nílẹ̀.
Nínú ìwádìí ni wọ́n ti ríi pé Miriam ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sí UK ni lẹ́yìn tó wá ṣe mọ̀mí-n-mọ̀-ọ́ ní Nàìjíríà, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe tó lọ yìí ló yẹ kó ṣe ìgbéyàwó àmọ́ ikú ti ba ọjọ́ náà jẹ́ báyìí.
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe àpèjúwe Miriam gẹ́gẹ́ bíi èèyàn jẹ́jẹ́, oníwà tútù bí àdàbà. Wọ́n bá àwọn òbí rẹ̀ kẹ́dùn àdánù náà.
LÁGBO ÒṢÈRÉ:
Gbajúgbajà olórin tàkasúfèé nnì Micheal Ajere tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Don Jazzy sọ iná sí orí ìtàkùn ayélujára lánàá ọjọ́bọ, ọjọ́ kìíní, oṣù Èbìbí nígbà tó ta obìnrin kan lọ́rẹ mílíọ́nù mẹ́fà náírà.
Obìnrin yìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adeyemi Adejoke Abidemi kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé òun máa ń lá àlá rí Don Jazzy, ó sì kíi kú àmójúbà oṣù titun.
Don jazzy bá fèsì pé kí ó fi òǹkà àpò owó rẹ̀ ránṣẹ́, kíá ni Adejoke ti fi ṣọwọ́ síi tí Don Jazzy sì fi mílíọ́nù kan náírà sínú àpò náà.
Kò tán síbẹ̀ o, Don Jazzy wí pé àpò owó rẹ̀ ń ṣòjòjò nítorí pé náírà mẹ́tàdínláàdọ́rin náírà ló wà nínú àpò owó náà, ló bá tún ṣe àfikún mílíọ́nù márùn-ún náírà fún un, ó wá jẹ́ mílíọ́nù mẹ́fà náírà lápapọ̀.
Arábìnrin Adeyemi Adejoke fi ẹ̀rí mílíọ́nù mẹ́fà náà léde, ó dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Don Jazzy ó sì súre fún un.
Èyí ni àkójọ àwọn ìròyìn tó ń jówọ́ jónu láàárọ̀ yìí, iṣẹ́ wa náà ni láti fi tó o yín létí, ẹ má jìnnà sí ojú òpó wa fún àkọtun ìròyìn.
Discussion about this post