Jìnìjìnì bo àwọn ará Idimu ní Èkó láàárọ̀ ọjọ́ Àìkú nígbà tí wọ́n rí òkú àwọn èèyàn méjì tí ọ̀kan kò sì tún ní orí mọ́.
Ìròyìn fi yé w apé òru ọjọ́ àbámẹ́ta ni wọ́n pa àwọn èèyàn náà kí àwọn èèyàn tó jí rí wọn láàarọ̀ ọjọ́ Àìkú.
Lanre Ajao, ẹni tó jẹ́ ará àdúgbò náà wí pé Baba ọjà ni àwọn ń pe ọ̀kan nínú àwọn òkú náà, ìyẹn èyí tí orí rẹ̀ ṣì wà lọ́rùn rẹ̀, ó wí pé ó nira láti dá èkejì tí kò ní orí náà mọ̀.
Lanre wí pé òdú ni bàbá ọjà ní agbègbè náà, àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ aládàáni ló máa ń sọ́nà fún nínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ, wọ́n ní ó ṣì sọ́nà fún ọkọ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.
Jamiu Raji náà bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó wí pé ìṣọwọ́ pa àwọn èèyàn náà tọ́ka sí iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn. O ní kò sí ìjà tàbí fàǹfà kankan ló jẹ́ kí òun ròó bẹ́ẹ̀ àti pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kò ṣẹlẹ̀ rí ní àdúgbò náà. Bákan náà ló ṣe ìdámọ̀ ẹnìkejì bíi ará àdúgbò náà.
Àwọn akọ̀ròyìn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó lé ní wákàtí mẹ́wàá kí àwọn ọlọ́pàá tó dé ibẹ̀, ẹnìkan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ òun wí pé àwọn gba owó lọ́wọ́ àwọn ẹbí àwọn òkú náà kí wọ́n tó jẹ́ kí wọ́n gbé wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò tíì fèsì sí ibéèrè àwọn oníròyin lórí pé ṣé lóòótọ́ ni wọ́n gba owó náà.
Ìròyìn mìíràn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ lọnìí náà ni ti àwọn tí wọ́n ṣe ìwọ́de bèèrè fún ìjẹ́jọ́ Mele Kyari. A gbọ́ pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn afẹ̀hónúhàn ya bo ilé iṣẹ́ ọ̀gá àgbà adájọ́ ilẹ́ yìí; Amòfin àgbà Lateef Fagbemi láti bèèrè fún ìfòfingbé Mele Kyari; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ NNPC tẹ́lẹ̀.
Wọ́n ní kí ìjọba ó fi òfin gbé Mele Kyari kó wá ṣe àlàyé bí ó ṣe sẹ owó àjọ NNPC láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn.
Kabir Matazu ló ṣaajú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà, ó wí pé lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yọ Kyari àti ikọ̀ rẹ̀ nípò, ó yẹ kí wọn ó gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ kó ṣe àlàyé àwọn ẹ̀sùn ìṣowó-mọ́kumòku tí wọ́n fi kàn án.
Lára àwọn ẹ̀sùn náà ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ bílíọ́nù dọ́là ni Kyari fi ṣe àtúnṣe àwọn ilé iṣẹ́ ìfọpọ ìjọba tí kò lábọ̀ di òní. Bákan náà ni àjọ NNPC jẹ ilé iṣẹ́ Matrix ní bílíọ́nù méjì dọ́là ní èyí tí kò ní àlàyé tí wọ́n ń fi epo rọ̀bì sàn lojoojúmọ́.
Matazu wí pé àwọn ọmọ Nàìjíríà gbé oríyìn fún ààrẹ Tinubu nígbà tó yọ Kyari àmọ́ oríyìn náà kò tíì pé àfi bó bá pè é lẹ́jọ.
Matazu àti àwọn afẹ̀hónúhàn ṣe ìlérí pé àwọn ò jí sinmi títí di ìgbà tí ìjọba ó fi pe Mele Kyari lẹ́jọ́.
Lórí àwọn ẹ̀sùn kàbìtì kàbìtì yìí ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe yọ Mele Kyari nípò ọ̀gá àgbà àjọ NNPC tó sì yan Ọ̀gbẹ́ni Bayo Ojulari ní ọ̀gá àgbà titun. A mú ìròyìn ìṣípòpadà náà wá pé:
Àjọ NNPC ní àwọn kò jẹ àgbọ̀nrín èṣí mọ́ lọ́bẹ̀, wọ́n yan adarí titun tí yóò wa ọkọ̀ àjọ náà lọ sí iwájú.
Ọ̀gbẹ́ni Bayo Ojulari ni ẹni náà tí wọ́n yàn pé yóò darí àjọ náà dé èbútè ògo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rẹ́ ò dénú, ìgbàgbọ́ tí ààrẹ ní nínú ọ̀gbẹ́ni Bayo nípọn.
Òwúrọ̀ ọjọ́ náà gan-an ni ààrẹ pàṣẹ kí adarí tẹ́lẹ̀; Mele Kyari ó gbé ọ̀pá àṣẹ àjọ NNPC lé Bayo lọ́wọ́, bákan náà ló tún ṣe àwọn àtúntò kan nínú ikọ̀ tí yóò báa ṣiṣẹ́.
Olufemii Soneye; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ NNPC ló sọ èyí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó gbé jáde. Ó wí pé àjọ náà dúpẹ́ gidi lọ́wọ́ Kyari fún ipa rẹ̀ lásìkò tó fi jẹ́ adarí àmọ́ ní báyìí, ààrẹ ti pàṣẹ kó fi àdàgbá ètò rọ̀ kó sì gba ilé rẹ̀ lọ, ó ní àwọn ro ire rò ó lórí àwọn àdáwọ́lé rẹ̀ ọjọ́ iwájú.
Ọjọ́ tí Olúgbongágà bá ta egbò náà níí kan ìlẹ̀pa, ọjọ́ tí ààrẹ pàṣẹ náà ni Kyari yóò gba ilé rẹ̀ lọ tí Bayo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.
Yorùbá bọ̀, wọ́n ní tí a bá mú olè táa ní kó sá tó sá, táa ní kó da tọwọ́ rẹ̀ lẹ̀, ó gbọdọ̀ dàá lẹ̀ ni. Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti mú Kyari lóòótọ́ ó sì ti ní kó sá, ohun tí àwọn afẹ̀hónúhàn yìí ń bèèrè fún náà ni pé kí ó da tọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Ìgbésẹ̀ tí ìjọba yóò gbé lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn yìí ni a ń retí báyìí.
Ká má gbàgbé àti mẹ́nuba ẹ̀sùn mìíràn tí wọ́n fi kan ajọ NNPC nígbà tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Mele Kyari. Wọ́n ní epo bẹntiróòlù NNPC máa ń gbẹ ní kíákíá sí ti ilé iṣé ìfọpo Dangote. Kódà, ọkùnrin kan gbìyànjú láti fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀.
Ọkùnrin yìí lọ sí ilé epo MRS tó wà ní Alápẹ̀rẹ̀, Èkó. Epo láti ilé iṣẹ́ ifọpo Dangote ni wọ́n ń tà níbẹ̀. Ó ra jálá epo kan nílé epo MRS yìí ní okòóléláàdọ́rùn-ún-ó-lé-márùn-ún náírà #925, lẹ́yìn náà ló lọ sí ilé epo NNPC tó wà ní Ojodu-Berger, jálá kan náà ló rà níbẹ̀ ní #945.
Nígbà tó dé ilé, ó da àwọn epo bẹntiróòlù méjéèjì yìí sínú ẹ̀rọ amúnáwá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ó sì tàn wọ́n lásìkò kannáà.
Gbogbo bí ó ṣe ń ṣe èyí ni ó ń ká fọ́nrán rẹ̀ tí àwọn èèyàn sì ń wòó lórí ìtàkùn ayélujára. Ẹ̀rọ amúnáwá tí ó da epo NNPC sí ló kọ́kọ́ paná lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́tàdìnlógún nígbà tí ẹ̀rọ amúnáwá tó lo epo Dangote paná lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́tàlélọ́gbòn. Fọ́nrán yìí ló dúró bíi ẹ̀rí sí ohun tí àwọn èèyàn ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé epo NNPC máa ń yára jó tán.
Ẹ̀sùn yìí gbòdì lára àjọ NNPC, wọ́n yarí kanlẹ̀. Wọ́n ní ìdá àádọ́rùn-ún epo bẹntiróòlù tí àwọn ń tà ló jẹ́ ti ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote. Àjọ NNPC ṣe àlàyé pé epo bẹntiróòlù tí ẹni náà rà jẹ́ ti ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote, wọ́n ní ẹ̀ríkẹ́rìí ni arákùnrin yìí fi múlẹ̀ nítorí pé epo bẹntiróòlù tí ilé iṣẹ́ àwọn ń tà jẹ́ ojúlówó.
Kò tán síbẹ̀ o, àjọ NNPC wí pé ẹ̀rí náà kò fìdí múlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, nítorí náà, òfegèé ni. Wọ́n wá ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo èèyàn láti yàgò fún bíba ọjà ilé iṣẹ́ wọn jẹ́, àjọ NNPC wí pé ẹni tí ó bá sán aṣọ irú rẹ̀ ṣorò yóò fojú winá òfin.
Nígbà tí ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote máà fèsì, ọ̀rọ pèsì jẹ. Wọ́n ní epo tó tètè jó tán náà kìí ṣe ti ilẹ iṣẹ́ àwọn o pé àjọ NNPC ló mọ ibi tó ti rà á.
Ilé iṣẹ́ Dangote wí pé ó ya àwọn lẹ́nu pé àjọ NNPC le sọ pé ọ̀dọ̀ àwọn lọ ti ra epo náà nígbà tó ṣe pé òkè òkun ni wọ́n ti ń ra epo wọn wọlé.
Ẹ̀sùn ojúlówó epo yìí jẹ́ ẹ̀sùn bíńtín nínú àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Mele Kyari tí wọ́n sì ń pè fún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Discussion about this post