Grace Walter; ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta àti ọmọ rẹ̀; Blessing Walter; ẹni ogún ọdún gbìmọ̀pọ̀ ta ọmọ tí Blessing bí ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin náírà. Ọjọ́ kejì tí Blessing bí ọmọ náà ni òun àti ìyá rẹ̀ gbé e tà.
Agbègbè Oron ní ìpínlẹ̀ Awka Ibom ni èyí ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọwọ́ tẹ àwọn tí wọ́n ta ọmọ́ náà fún.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ni wọ́n dá ọkọ̀ àwọn tó ra ọmọ náà dúró ní òpópónà Nsit Atai sí Oron, àwọn mẹ́ta ni wọ́n wà nínú ọkọ̀ náà; ọkùnrin kan tó wa ọkọ̀ náà àti àwọn obìnrin méjì. Àwọn ìdáhùn tí wọ́n fún àwọn ọlọ́pàá lórí bí ọmọ náà ṣe jẹ́ kò gún régé tó ló fàá tí wọ́n fi mú wọn lọ sí àgọ́ wọn fún ìdánilójú.
Àgọ́ ọlọ́pàá ni Naskpo Sonia Labere àti Inemesit Okin Akpan ti jẹ́wọ́ pé wọ́n rán àwọn wá ra ọmọ náà láti Portharcourt ni. Wọ́n ní Wazor Godwin àti Lilian Duru ló rán àwọn wá gba ọmọ náà lọ́wọ́ Grace Inyang ní Oron, Awka Ibom.
Ní báyìí, ọwọ́ ti tẹ Alison Eduno tó ṣọ̀nà rírà àti títa ọmọ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Awka Ibom ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láti ẹnu alukoro wọn; Timfon John láàárọ̀ yìí pé ọwọ́ tẹ àwọn oníṣòwò ọmọ ní agbègbè Oron ní Awka Ibom. Wọ́n ti mú ìyá àti ìyá ìyá ọmọ náà tó ta ọmọ náà, bákan náà ni wọ́n ti mú Lilian tó mú ẹni tó ra ọmọ mọ ẹni tó ta ọmọ. Wọ́n ti gbé ọmọ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń mójútó ọ̀rọ̀ obìnrin tó wà ní Uyo fún ìtọ́jú.
Èyí kìí ṣe ìròyìn àkọ́kọ́ nípa àwọn oníṣòwò ọmọ. Nínú oṣù Ebìbí ọdún yìí ni a kọ ìròyìn nípa Joy tó gbé ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà ní ìpínlẹ̀ Niger. A gbọ́ pé ẹ̀gbọ́n Joy gbé ọmọ rẹ̀, ọmọ ìkókó fún àbúro rẹ̀ pé kí ó bá òun mójútó ọmọ náà kí òun fi dé ọjà. Kí Joy tó dé, àbúro rẹ̀ ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ilé lọ ta ọmọ náà.
Àlàyé náà lọ báyìí pé: Agbègbè Kwamba, Suleja ní ìpínlẹ̀ Niger ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀. Ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni ìyá ọmọ oṣù mẹ́fà yìí fi ọmọ rẹ̀ ti Joy; ẹni tó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ pé òun fẹ́ jáde.
Dídé tí yóò dé lálẹ́, kò bá ọmọ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá Joy tó fi ti ọmọ náà. Kò kọ́kọ́ bìkítà pé bóyá ó sáré jáde ni àmọ́ nígbà tí Joy kò gbé aago tí ilẹ̀ fi ṣú ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́.
Obìnrin yìí kàn sí àwọn ọlọ́pàá Suleja wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ohun tó mú kí ìwádìí náà ó rọrùn ni àwọn ara ilé rẹ̀ méjì tí wọn kò sí nílé láti ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bí ọ̀kan nínú wọn ṣe dé ni àwọn ọlọ́pàá he é bíi ìgbín, òun ló júwe ibi tí Joy àti àwọn méjì yòókù wà.
Agbègbè Kubwa ní Abuja ni wọ́n gbé ọmọ oṣù mẹ́fà náà lọ láti tàá, Emmanuel Ezekiel jẹ́wọ́ pé àwọn ti ń gbìmọ̀pọ̀ tipẹ́ láti jí ọmọ náà gbé pẹ̀lú Joy, nígbà tí àwọn sì rí anfààní láti gbé e ni àwọn ṣe jọ jí ọmọ náà gbé lọ tà.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ Joy àti Favour, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé Patience Obana tí yóò bá wọn ta ọmọ náà, kò tíì rí ọmọ náà tà tí àwọn ọlọ́pàá fi mú un. Àlàáfíà sì ni ọmọ yìí wà.
Wasiu Abiodun; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn mú Joy Nuwa; ẹni ogún ọdún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Nasarawa, Emmanuel Ezekiel; ẹni ọgbọ̀n ọdún tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Niger, Favour James; ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Niger bákan náà àti Patience Obana; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tí òun sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abuja lórí ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé.
Kìí wá ṣe pé ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé nìkan o, ọmọ títà ni iṣẹ́ Patience, Kubwa ní Abuja ló tẹ̀dó sí.
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọmọ náà padà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti gbé e fún ìyá rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Abiodun wí pé àwọn ti kó àwọn afurasí mẹ́rin yìí sí àtìmọ́lé, wọn yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́.
Ó ṣe pàtàkì láti fidí ẹ̀ múlẹ̀ pé kìí ṣe ọmọ ìkókó nìkan ni wọ́n jígbé, àwọn ọmọdé àti àgbà náà kò gbẹ́yìn. Ṣé ẹ rántí Memunat tí wọ́n jí gbé nígbà tí ó ń bọ̀ láti ilé kéú pẹ̀lú ẹgbọ̀n rẹ̀.
A gbọ́ pé ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ẹrẹ́nà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ní Ejigbo, ìpínlẹ̀ Èkó.
Memunat; ọmọ ọdún márùn-ún ń ti ilé kéú bọ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, arákùnrin náà pàdé wọn lọ́nà ó sì ní kí wọ́n máa bọ̀ ní ilé ìtajà kan pé òun fẹ́ ra ìpápánu fún wọn. Ẹ̀gbọ́n Memunat ló kọ́kọ́ wọ inú ilé ìtajà náà, ẹ̀yìn tó máa wò báyìí, ọkùnrin náà ló rí tó ń gbé Memunat sá lọ rẹ rẹ rẹ.
Àwọn òbí ọmọ yìí bèèrè fún fọ́nrán ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ilé ìtajà yìí, inú rẹ̀ ni wọ́n ti rí ojú ọkùnrin náà kedere, ó wọ inú ilé ìtajà náà pẹ̀lú àwọn ọmọ méjéèjì níwájú rẹ̀, ẹ̀ẹ̀kan náà ló ki Memunat mọ́lẹ̀ tó sì bọ́ síta, ẹ̀rọ tó wà níta ilé ìtajà náà tún káa bí ó ṣe wọ kẹ̀kẹ́ maruwa tó sì lọ.
Àwọn òbí Memunat ti fi àwòrán ọmọ wọn àti ti afurasí náà léde pé ẹni tó bá kófìrí rẹ̀ kó kàn sí àwọn. Bákan náà ni àwọn ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.
Ní báyìí, ọ̀gá ọlọ́pàá ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe iṣẹ́ náà bí iṣẹ́, a gbàá ládùrá pé èsì ayọ̀ la ó gbà lórí ọmọ náà.
Discussion about this post