Gbajúgbajà olórin ẹ̀mí nnì; Bolaji Olanrewaju tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ jẹ́ Big Bolaji ti kí ayé pé ó dìgbà lẹ́ni àádọ́ta ọdún lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ́.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ló túfọ̀ ikú rẹ̀ lónìí pé pẹ̀lú ẹ̀dún ọkàn àti ìbànújẹ́ ni àwọn fi kéde ikú Big Bolaji tó dágbére fáyé láàárọ̀ ọjọ́ àbámẹ́ta ti àsìkò àjíǹde Jesu yìí. Wọ́n ní ọmọ, ọkọ, ẹ̀gbọ́n àti bàbá rere ni Bolaji, ó jẹ́ pásítọ̀ tí Ọlọ́run pè nínú ìjọ ìràpadà ó sì tún jẹ́ olórin ẹ̀mí Ọlọ́run ń gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀.
Títí láí ni wọn yóò máa ṣe ìrántí àwọn ohun rere tó gbé ilé ayé ṣe.
ỌMỌ ÌYÁ MÉJÌ KÚ SÍNÚ KÒTÒ ÌWAKÙSÀ NÍ NASARAWA
Àwọn ọmọ ìyá méjì kan tí wọ́n tẹ̀lé ẹ̀gbọ́n wọn lọ sódò lọ fọ aṣọ ti kú sínú kòtò kan tí wọ́n ti ń wa kùsà tẹ́lẹ̀.
Agbègbè Udege Mbeki ní ìpínlẹ̀ Nasarawa ni èyí ti ṣẹlẹ̀, ọmọ ọdún méje ni Umar Muhammad nígbà tí èkejì rẹ̀; Ibrahim Muhammad jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án.
Ilé iṣẹ́ ìwàkùsà kan tó jẹ́ ti orílẹ̀-ède China tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Kenyang ló ń wa kùsà ní ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, wọ́n pa ibẹ̀ tì wọ́n sì kọ̀ láti dí kòtò náà padà.
lỌ́jọ́bọ tí àwọn ọmọ yìí lọ sí odò kan tó wà níbẹ̀, ojò ti rọ̀ darí omi sì ti kún kòtò náà dẹ́nu, àwọn ọmọ yìí ń ṣeré ní tiwọn bí ẹ̀gbọ́n wọn ṣe ń fọ aṣọ, wọ́n kó sínú kòtò náà wọ́n sì kú sínú rẹ̀.
Àwọn ará abulé Udege bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí àwọn ilé iṣẹ́ ìwàkusà ń hù ní agbègbè náà nípa fífi kòtò tí wọn kò bá lò mọ́ sílẹ̀ láìdí, wọ́n ní èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn èèyàn máa kú sínú àwọn kòtò bẹ́è. Bákan náà ni wọ́n ní àwọ́n olórí ìlú ti ń gbé ilé iṣẹ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ láti ọdún 2021 àmọ́ kò so èso rere kankan.
ỌKỌ KÚ, ÌYÀWÓ FARAPA NÍNÚ ÌJÀM̀BÁ TÓ WÁYÉ NÍ ÒNDÓ.
Tọkọtaya àti àwọn èrò méjì mììràn ló wà nínú kẹ̀kẹ́ márúwá kan tó du ọ̀nà pẹ̀lú ọkọ̀ àjàgbé kan ní Ondo.
Àná, ọjọ́ Ẹtì ni ìjàm̀bá yìí wáyé ní Oke Aro, Akure ní ìpínlẹ̀ Ondo. Àlàyé tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé awakọ̀ ọkò àjàgbé náà kò fún márúwá náà láàyè láti kọjá lọ, onímárúwá náà kò fẹ́ kí ọkọ̀ àjàbé náà ó lọ ṣaájú òun lo bá rún ara rẹ̀ mọ́ ọn, àwọn mẹ́ta tó kó farapa nígbà tí ọkọ arábìnrin kan kú nínú ìjàm̀bá náà.
Awakọ̀ àjàgbé náà fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ nígbà tó rí i pé àwọn èrò ti faraya tí wọ́n sì fẹ́ lù ú, ó sá lọ ó sì lọ fa ara rẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá ní àgọ́ Oke Aro. A gbọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ tí inú ń bí yabo àgọ́ náà láti wọ́ awakọ̀ náà jáde àmọ́ àwọn ọlọ́pàá kò gbà fún wọn.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo; Ọ̀gbẹ́ni Olayinka Ayanlade fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti gbé àwọn tó farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn nígbà tí òkú ìyàwó náà ti wà ní ilé ìgbókùúsí ti ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Akure.
KÌÍ ṢE ỌKỌ̀ AKỌ́WỌ̀Ọ́RÌN AYA ÀÀRẸ LÓ PA ỌMỌ NÁÀ O – ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ .
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ wa ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Òndó tí fèsì sí ẹ̀sùn tí àwọn èèyàn fi kan ìyàwó ààrẹ lórí àwọn ìkànnì ayélujára gbogbo pé ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn rẹ̀ sẹkú pa ọmọdé kan ọmọ ọdún méje ní ìlú Àkúrẹ́ tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Òndó, wọ́n ní irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn yìí nítorí pé ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn aya ààrẹ kọ́ ló pa ọmọ náà o.
Ìyàwó ààrẹ wa; Oluremi Tinubu lọ sí Àkúrẹ́ lỌ́jọ́bọ láti pín àwọn ohun èlò fún àwọn agbẹ̀bí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ẹ̀sùn náà kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, ète àti tàbùkù aya ààrẹ lásán ni.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òndó: Olushola Ayanlade ló fi ọ̀rọ̀ náà léde pé ìkànnì Sahara reporters fi ìròyìn tí kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ náà léde pé ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn aya ààrẹ wa sẹkú pa ọmọdé náà, Olushola wí pé ìwádìí tí àwọn ṣe fi hàn pé ọkọ̀ Lexus kan ló gbá ọmọ náà tó sì sá lọ, wọ́n ní àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tí ó ṣẹlẹ̀ fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé ọkọ̀ Lexus ló pa ọmọ náà kìí ṣe ọ̀kankan nínú àwọn ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn aya ààrẹ.
Olushola tẹ̀síwájú pé ìròyìn òfegèé lásán ni Sahara reporters gbé jáde nitori pé àwọn òbí ọmọ náà gan-an sọ pé ọkọ̀ Lexus ló gbá ọmọ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti ṣe àbẹ̀wò sí àwọn òbí ọmọ náà, àwọn sì ti ṣe ìlérí láti wá awakọ̀ Lexus náà jáde.
ÌRÒYÌN ÒKÈRÈ: ÈÈYÀN MẸ́TÀLÉLÓGÓJE PÀDÉ IKÚ ÒJIJÌ NÍ CONGO.
Ọkọ̀ ojú omi kan tó gbé epo bẹntiróòlú ló dànù tó sì tún gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní orílẹ̀-ède Congo.
Ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọ̀sẹ̀ yìí ni ìjàm̀bá yìí wáyé tó sì mú ẹ̀mí àwọn èèyàn mẹ́tàlélógóje lọ tí ọ̀pọ̀ sì tún wà ní yóókùú-yóóyè.
Ìtòsí Mbandaka nị Equateur ní ibi tí odò Ruki àti Congo ti pàdé ni ìjàm̀bá náà ti wáyé. Òkú mọ́kànléláàdóje ni wọ́n kọ́kọ́ rí lọ́jọ́ náà tí wọ́n sì ń rí síi títí tó fi dé orí mẹtàlélógóje báyìí tí kò sì tún tíì dúró.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ ojú omi tó gbé epo ń lọ ní tirẹ̀ nígbà tí àwọn ọkọ̀ ojú omi tó kó èrò nạ́à ń lọ ní tiwọn, wọ́n ní obìnrin kan tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi akérò ló dá iná oúnjẹ nínú ọkọ̀ náà, bí obìnrin yìí ṣe ń dáná lọ ni afẹ́fẹ́ ìdáná rẹ̀ ń jò síta lábẹ́lẹ̀, afẹ́fẹ́ ìdáná yìí ló ràn mọ́ epo láti ara ọkọ̀ ojú omi tó gbé epo tó sì gbaná lẹ́ẹ̀kan náà, kíá ni iná yìí ti ràn mọ́ àwọn ọkọ̀ ojú omi yòókù.
Ìjọba Congo wí pé àwọn kò tíì le sọ pàtó iye àwọn èèyan tó ṣì kù nínú odò náà yálà láàyè ni tàbí tí wọ́n ti kú nítorí pé ọkọ̀ ojú omi kọ̀ọ̀kan kó èrò tó lé ní ọgọ́rùn-ún.
Discussion about this post