Ilé alájà méjì kan tó wà ní òpópónà ọ̀rẹ́mẹ́ta ní Ojodu-Berger, Èkó ti dà wó ní àárọ̀ òní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Igbe. Inú ilé yìí ni ilé oúnjẹ ìgbàlódé nnì Equal right wà, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n wà níbẹ̀ lásìkò tó dà wó náà.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ń lọ lù ni ilé náà ṣàdédé bì wó. A rí àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ panápaná tí wọ́n ti ń gbìyànjù láti dóòlà ẹ̀mí àwọn tó há náà.
Akọ̀wé fún ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Èkó; Dọ́kítà Oluwafemi Oke-Osanyintolu ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé èèyàn márùn-ún ni àwọn ti rí yọ láàyè báyìí, wọ́n ní ọgbọ́n ni ọ̀rọ̀ náà gbà àwọn sì ti kó àwọn irin iṣẹ́ ńlá ńlá tí wọn yóò lò dé. Dọ́kítà Oluwafemi wí pé àwọn ń ti igun kan bọ́ sí ìkan ni láti wá àwọn èèyàn tó há náà.
Ní báyìí, ìròyìn ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti rí òkú ẹnìkan nínú èérún ilé náà, ilé iṣẹ́ to ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì wí pé àwọn ko le sọ iye àwọn èèyàn tó há gan-an ní pàtó nítorí pé àwọn èrò pọ̀ nínú ilé oúnjẹ náà lásìkò tó wó. Wọ́n ní àwọn ń tẹ̀síwájú nínú wíwá àwọn èèyàn náà jáde nígbà tí àwọn èèyàn ní ìrètí àtirí ẹbí wọn padà láàyè.
IPÒ WO NI ILÉ TÓ DÀ WÓ NÁÀ WÀ TẸ́LẸ̀?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ́ kan kìí déédé ṣẹ́, àwọn akọ̀ròyìn gbìyànjú láti mọ ipò tí ilé alájà méjì náà wà tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí ó tó dà wó yìí. Ẹnìkan tí ìsọ̀ rẹ̀ wà ní ìtòsí ibẹ̀ àmọ́ tí a kò ní le dárúkọ rẹ̀ ṣe àlàyé pé ilé náà ti kẹ láti ọjọ́ tó ti pẹ́, ó ní òun kìí tilẹ̀ ra oúnjẹ níbẹ̀ nítorí pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ó le dà wó nígbàkúùgbà.
Ẹlòmíràn náà wí pé ó ti pẹ́ tí àwọn ará àdúgbò ti ń ṣe ìkìlọ̀ pé ilé náà le dà wó nítorí pé ó ti kẹ kalẹ̀ àmọ́ kò sí ẹni tó kọbi ara sí ìkìlọ̀ yìí.
Ní báyìí, ó ti dà wó láàárọ̀ òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ló sì ti há sí abẹ́ rẹ̀.
Ilé mìíràn dà wó ní Agarawu, Èkó: ilé alájà mẹ́ta tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ dà wó ní Èkó.
Ilé alájà mẹ́ta tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní òpópónà Agarawu ní Island, Èkó kò jẹ́ tí wọn ó kọ́ òun tán tó fi dà wó lulẹ̀. Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Igbe tí a wà yìí ni ilé náà dà wó lulẹ̀ wìì. Àwọn òṣìṣẹ́ méjì ló farapa yánnayànna.
Nínú ọ̀rọ̀ tí agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin sọ ni a ti ríi dì mú pé nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ni ilé náà bì wó lọ́jọ́ náà, ilé yìí sì farati ilé ìwòsàn ìjọba alábọ́dé primary health center Agarawu ni. Kíá ni wọ́n ti gbé àwọn òṣìṣẹ́ méjì náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Marina fún ìtọ́jú.
Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà dídàwó náà.
ÀWỌN IṢẸ̀LẸ̀ ILÉ DÍDÀWÓ MÌÍRÀN NÍ ÈKÓ.
Ilé dídàwó kò fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìròyìn mọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó, ó ti di ohun tí kò le má ṣẹlẹ̀. Lọ́dún tó kọjá lọ yìí ni ilé kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ dà wó ní agbègbè Maryland. A gbọ́ pé Ilé alájà-mẹ́ta kan dà wó ní Maryland, Èkó:
Ilé alájà-mẹ́ta kan tí wọ́n ṣì ń kọ́ lọ́wọ́ ní òpópónà Wilson Mba, Arowojobe, Maryland ní ìpínlẹ̀ Èkó ló dà wó lulẹ̀ ní nǹkan bí aago mẹ́rin ìdájí ń lọ lù.
Ìpè pàjáwìrì tí àwọn òṣìṣẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì gbà ni wọ́n fi ta mọ́ra dé ibẹ̀ ní wàràǹsesà. Èèyàn mẹ́fà ni wọ́n bá níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ọ̀kunrin ni gbogbo wọn, ibi tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ilé náà lọ́wọ́ ló ti ya bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Mẹ́ta nínú wọn ló farapa yánnayànna nígbà tí àwọn mẹ́ta yòókù ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.
Akọ̀wé àjọ òṣìṣẹ́ pàjáwìrì NEMA; Ọ̀gbẹ́ni Olufemi Oke-Osanyintolu fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó máa n sa ipá rẹ̀ láti ṣe àtúnṣe tàbí wó ilé tó bá ti kẹ kí ó má baà wó fúnra rẹ̀, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé gbogbo akitiyan yìí kò tíì kájú àdojúkọ náà.
Nínú akitiyan àti dèna irú ìjàm̀bá báyìí ni wọ́n ti kéde níjọ́sí pé awọn yóò da ilé kan tó ti kẹ nínụ́ bárékè ọlọ́pàá wó. A gbọ́ pé:
Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti kéde pé àwọn yóò da ilé ìgbé kan tó wà ní bárékè ọlọ́pàá ní Onigbongbo, Ìkẹjà nítorí ipò tí ilé náà wà.
Ilé kẹta nínú bárékè ọlọ́pàá náà ti dẹnu kọlẹ̀ pátápátá, àwọn òpó tó gbé e ró ti tẹ̀ kọkọrọ, ìgbàkúùgbà ni ó le dà wó lulẹ̀.
Kí ó má wá di pé àbámọ̀ yóò ṣẹlẹ̀, ìjọba Èkó ti kéde pé wíwó ni àwọn yóò dàá wó, wọn kò ní dúró dìgbà tí yóò mú ẹ̀mí tàbí pa àwọn olùgbé ibẹ̀ lára.
Akọ̀wé àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Èkó; Dámilọ́lá Oke-Osanyintolu ló fi ọ̀rọ̀ yìí lédè, ó wí pé kí a má ṣe fòyà pé ìjọba Babajide Sanwoolu kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún ohun tó le pa wá lára.
Bí ìjọba ṣe ń gbìyànjú yìí, ó ṣe pàtàkì kí àwa fúnra wa náà ó sa ipá wa, a kò ní wó mọ́lé o. Àṣẹ.
Discussion about this post