Àkọlé tó gba ojú ìwé ìròyìn kan àti ìbéèrè tí àwọn èèyàn ń bèèrè ni pé kín ni ìdí tí àwọn ológun ibùdó ogun tó wà ní ìtòsí abúlé Zikke kò ṣe kojú àwọn agbésùnmọ̀mí? Wọ́n ní ibùdó àwọn ológun náà farakínra pẹ̀lú abúlé Zikke tí àwọn agbésùnmọ̀mí ń yọ lẹ́nu yìí ni, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti lọ ṣe ìkọlù ní abulé náà láàárín ọ̀sẹ̀ kan tí àwọn ọmọ ológun ibùdó náà kò tilẹ̀ mira rárá.
Àwọn ará abúlé Zikke bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé lọ́jọ́ Ajé àti Ìṣẹ́gun. Ọ̀kan nínú wọ́n wí pé bí èèyàn bá garùn sókè dáádáa ní abúlé Zikke, yóò rí òrùlé ibùdó àwọn ológun Nàìjíríà kẹta lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n ní kò ju òpó márùn-ún lọ sí abúlé náà síbẹ̀, àwọn agbésùnmọ̀mí ń wọlé jáde láìní ìdíwọ́ kankan.
Ìkọlù tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun gba ẹ̀mí àwọn èèyàn mọ́kànléláàdọ́ta nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ní ilé ìwòsàn. Ará abúlé kan fi ẹ̀sùn kan àwọn ológun ibùdó náà pé wọ́n mọ̀ọ́nmọ̀ má wá ni nítorí pé ibùdó náà ko ju ohun tí wọ́n le fi ẹsẹ̀ rìn lọ.
Gbogbo akitiyan àwọn oníròyìn láti kàn sí Ọ̀gágun ibùdó yìí kí ó le tan ìmọ̀lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí kò yọrí sí rere látàrí pé kò gbé ìpè rẹ̀ kò sì tún fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.
BÍ ÌKỌLÙ NÁÀ ṢE LỌ.
Abúlé Zikke gbóná janjan lóru ọjọ́ Ajé mọ́jú ọjọ́ Ìṣẹ́gun nígbà tí àwọn agbébọn bá wọn lálejò. Ìjọba ìbílẹ̀ Bassa ni abúlé Zikke wà ní Jos tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau.
Òru ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ni àwọn agbébọn náà dé sí abúlé Zikke lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n. Wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, wọ́n pa àwọn èèyàn bíi àádọ́ta wọ́n sì tún ṣe ogúnlọ́gọ̀ báṣubàṣu.
Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi ṣe ọṣẹ́ yìí láìsí ìdíwọ́ kankan.
Olórí ọ̀dọ́ abúlé Zikke, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Irigwe; Joseph Chudu bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé wọ́n ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Jos, ipò wọn burú wọ́n sì nílò ẹ̀jẹ̀.
Chudu rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yìí. Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau kò so èso rere nípa pé agbẹnusọ wọn; Alabo Alfred kò gbé ìpè àwọn oníròyìn.
Ìkọlù yìí jẹ́ ọ̀tun lẹ́yìn gbogbo àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau lẹ́nu lọ́lọ́ yìí. Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n fẹ́rẹ̀ run gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Bokko. Àádọ́ta èèyàn ni wọ́n pa lọ́sẹ̀ tó kọjá nìkan tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì tún ṣòfò.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Joyce Renmap wí pé ìkọlù tó gba ìpínlẹ̀ Plateau kan yìí jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́. Joyce wí pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bokko àti Bassa láàrín ọ̀sẹ̀ méjì yìí.
Ọ̀rọ̀ Joyce tẹ̀síwájú pé ìlú tó kún fún ìfẹ́ àti àdùn tẹ́lẹ̀ ti parade di ibi tó kún fún ìkorò àti ìbànújẹ́ látàrí ìkọlù ojoojúmọ́ yìí. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti borí àdojúkọ yìí.
Wàyí o, àwọn ará abúlé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí iná gbà jó wọn. Lancaster Akpa; ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta wí pé ẹbí òun mẹ́sàn-án ló bá ìkọlù náà lọ. Akpa wí pé Jos ni òun wà nígbà tí àbúrò òun pe òunp pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù, ó ní òun kò le sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà, ìgbà tí òun pe aago rẹ̀ tí kò lọ mọ́ ni ara ti ń fu òun kó tó wá di pé òun dé bá òkú rẹ̀, ẹ̀gbọ́n òun àti àwọn ọmọ wọn méje.
Akpa wí pé àwọn tí wọ́n wá ṣe ìkọlù náà wọ aṣọ ológun àmọ́ Fulani ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí òun gbọ́.
Jerry Muwa náà sọ tirẹ̀, ó ní àwọn ọmọọmọ òun mẹ́fẹ́ẹ̀fà ni wọ́n dáná sun mọ́lé nígbà tí wọn kò rí ìlẹ̀kùn já. Ó ní òun rápálá jáde lóru ọjọ́ náà ni pẹ̀lú ọmọ òun tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ náà. Muwa wí pé àwọn ọmọ náà jóná di éérú débi pé kò sí ẹran tàbí eegun tí àwọn le sin, àwọn kan kó éérú wọn jọ sínú sàárè kan ni.
ÀBẸ̀WÒ GÓMÌNÀ.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau; Caleb Mutfwang ṣe àbẹ̀wò sí abúlé Zikke àti Kimakpa tí ọ̀rọ̀ náà ti dunlẹ̀. Ronku Aka; ẹni tó jẹ́ adarí Irigwe dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Caleb fún àbẹ̀wò náà, ó wí pé ó fi hàn pé Gómìnà bìkítà nípa àwọn èèyàn rẹ̀.
ÌLÉRÍ Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ.
Ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá ilẹ̀ yìí; Kayode Egbetokun ṣe ìlérí pé àwọn ẹni náà kò ní lọ láì jìyà. Ó ní gbogbo àwọn tó ṣe ìkọlù náà làwọn ọlọ́pàá yóò ṣà lọ́kọ̀ọ̀kan tí wọn yóò sì fojú ba ilé ẹjọ́. Egbetokun sọ èyí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí Gómìnà Caleb. Ó wí pé àwọn ọlọ́pàá ti kún àwọn abúlé náà fọ́fọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
ÌGBÉSẸ̀ TÍ GÓMÌNÀ GBÉ
Gómìnà Caleb Mutfwang ti pàṣẹ pé bẹ̀rẹ̀ láti òní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, ọṣù Igbe, ọdun yìí, kò gbọdọ̀ sí dída ẹran màlúù ní alẹ́ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọkọ̀ kó màlúù lẹ́yìn aago méje alẹ́. Bákan náà ni ọ̀kadà kò gbọdọ̀ rìn lẹ́yìn aago méje alẹ́ di aago mẹ́fà àárọ̀.
Gómìnà Caleb ṣe ìlérí pé gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù náà ni kò ní mú un jẹ nítorí pé gbogbo wọn ni àwọn yóò ṣà lọ́kọ̀ọ̀kan.
Discussion about this post