Àjọ JAMN (JOINT ADMISSION MATRICULATION EXAMINATION BOARD) ti la àlàkalẹ̀ òfin tó de ètò ìdánwò JAMB ọdún yìí láti wọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ilẹ̀ Nàìjíríà. Àjọ JAMB ní ọjọ́ karùndínlógún oṣù kẹrin ọdún 2025 yìí ni ìdánwò yóò bẹ̀rẹ̀ káàkiri ilé ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà tí a ti yà sọ́tọ̀ fún aṣèdánwò. Òfin tí aṣèdánwò gbọ́dọ̀ gùnlé náà ti wà ní àlàkalẹ̀ báyìí láti gbógun ti ìwà àjẹbánu lásìkò ìdánwò. Mílíọ̀nù méjì ni aṣèdánwò ló ti fi orúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò náà, àjọ JAMB sì ní ẹni tó bá kọ̀ tó tàpá sí òfin yìí yóò di kí a gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò rẹ̀, àmójútó ti wà ní gbogbo CBT wa káàkiri orílẹ̀ èdè yìí. Ìwọ̀nyìí ni òfin tó de àṣedánwò JAMB tọdún yìí:
Aṣèdánwò kò gbọdọ̀ lo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ èyíkèyí nínú gbọ̀gán ìdánwò, aago ọwọ́ tó n lo íntánẹ́ẹ̀tì , ohun èlò ìṣírò kakulétọ̀, ẹ̀rọ̀ ìbọtí àti àwọn nnkan mìíràn tó fara pẹ́ ẹ. Àjọ JAMB ní aṣèdánwò tó bá tàpá sí òfin yìí yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní wàrànṣeṣà. Àjọ JAMB ní ẹ̀rọ baomẹ́ntíríìkì pọndandan fún gbogbo aṣèdánwò ṣáájú ọjọ́ ìdánwò náà kí èyí le è dènà ìwọ-rèé-àbí-ìwọ-kọ́ tí ó le è dá rúgúdù sílẹ̀ lásìkò ìdánwò. Gbogbo aṣèdánwò ló tún gbọ́dọ̀ lọ tẹ̀ka kí ó tó le è wọ inú gbọ̀ngá ìdánwò lọ; Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tẹ ìka kó tó di ọjọ́ ìdánwò kò ní ní ànfaàní láti jókòó ṣe ìdánwò ọdún yìí.
Aṣèdánwò gbọdọ̀ tètè dé sí ààyè ìdánwò lásìkò tó tọ́ tó sì yẹ, A kò ní fi ojú rere wo àwọn Apẹ́lẹ́yìn. Àjọ JAMB tún gba Akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú láti:
Tètè dé bí i wákàtí kan àbọ̀ sí àsìkò ìdánwò;
Ṣe àyẹ̀wò ìwé pélébé ìdánwò tó ní nọ́mbà ìdánimọ̀ wọn wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ kí ó tó tó àsìkò ìdánwò láti mọ̀ bóyá ó ṣe déédé kò sì ní kọ́nú-n-kọ́ọ nínú.
Ìdánwò yóò bẹ̀rẹ̀ ní gbèdéke tó bọ́ sí ti olúkúlùkù aṣèdánwò, kò ní sí àfikún
Àjọ JAMB ní lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni a ó fi ìyà jẹ Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ ṣe màkàrúrù nínú ìdánwò, wọn kò sì gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ tábí jí ẹnikẹ́ni wò bí ìdánwò bá n lọ lọ́wọ́.
Aṣèdánwò gbọ́dọ̀ tẹ̀lé òfin àti àlàkalẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ JAMB bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, wọn kò sì gbọdọ̀ hu ìwà ìfurasí kọkàn. Ẹ̀rọ CCTV àti AI yóò máa darí ètò ìdánwò láti rí i dájú pé ìdánwò lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀.
Àjọ JAMB ní kí aṣèdánwò ṣe àyèwò orúkọ, ọjọ́ ìbí àti àwọn ohun tó ṣe kókó kí wọ́n rí i dájú pé gbogbo rẹ̀ ló ṣe rẹ́gí ṣáájú ọjọ́ ìdánwò, kí àtúnṣe tètè wà tó bá jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ kí ó má máa jẹ́ ìjákulẹ̀ fún Akẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ iwájú.
Àjọ JAMB gba gbogbo Aṣèdánwò ní ìyànjú láti gbájúmọ́ ẹ̀kọ́ kí wọ́n yàgò fún òrìjíò tàbí ọ̀nà ẹ̀bùrú mìíràn lásìkò ìdánwò, wọ́n ní ọ̀nà tó le è mú aṣèdánwò yege jùlọ ní gbígbáradì gidi tí kò ní màkàrúrù nínú; Kí Akẹ́kọ̀ọ́ lo àwọn ìwé atọ́nà tí àjọ JAMB yàn, kí wọ́n yẹ ìbéèrè àtẹ̀yìnwá wò dáradára, kí wọ́n rí i dájú pé ìmọ̀ ẹ̀rọ̀ kọ̀mpútà wọn tawọ́n yọ.
Àjọ JAMB ní kí Aṣèdànwò má ṣe gbọ́nkànlé òrìjìó kankan nítorí sẹpẹ́ báyìí ni gbogbo òṣìṣẹ́ JAMB wà láti fi Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá gbọ̀nà màkàrúrù jófin. Wọ́n tún ní kò sí ààyè fún àwọn arúfin tí adé ìwà ìbàjẹ́ bá ṣí mọ́ lórí bẹ́ẹ̀kọ́ yóò fi ẹnu fẹ́ra bí abẹ̀bẹ̀ yóò sì tún kojú èyíkèyí nínú ìwọ̀nyìí:
– Fífà yọ bí i jìgá kúrò ní iyàrá ìdánwò JAMB
– Àìní ní ànfàaní láti tún ìdánwò kọ lọ́jọ́ iwájú
– Fífi ojú bɛ ilé ẹjọ́.
Ọ̀gá àgbà àjọ JAMB, Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA rọ gbogbo Aṣèdànwò pátàpátá porongodo láti tẹ̀lé òfin àti àlàkalẹ̀, kí wọ́n sì gbáradì fún ìdánwò ọdún yìí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ́n oṣù kẹrin ọdún yìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n ní àsìkò yìí kìí ṣe fún eré bí kò ṣe gbígbájú mọ́ ẹ̀kọ́ kí Aṣèdánwò sì tẹ̀lé òfin tó rọ̀ mọ́ ìdánwò ọdún yìí. Àṣeyè ni alákàn n ṣepo, àṣeyè ni gbogbo Akẹ́kọ̀ọ́ yóò ṣe!
Bákan náà ni JUBRIL OYEDELE tó jẹ́ Akẹ́ kọ̀ọ́ tó pegedé jùlọ tó sì fi gbọ̀ọ̀rọ̀ jẹkà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga IFÁFITÌ ÌBÀDÀN ti sọ pé kíkọ́ àwọn Akẹgbẹ́ òun ní àkọ́túnkọ́ ló túbọ̀ ṣe kóríyá fún àṣeyege òun, ìdí rèé tí òun fi jáwé olúborí. JUBRIL OYEDELE n sọ èyí nígbà tí wọ́n n fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wo láìpẹ́ yìí:
Nnkan nlá, ipa ribiribi ni kí èèyàn jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Ifáfitì Ìbàdán tó gbé oúnjẹ fún ẹgbẹ́, tó sì gba àwo bọ̀ ní ilé ìwé gíga àgàgà ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ CIVIL ENGINEERING. Ìrìnàjò mi náà kún fún ìlapa rere, ìgbìnyànjú Akin àti ìfẹ́ níní sí ẹ̀kọ́. Ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni mí, òṣùbà ràbàndẹ̀ mi lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá mi , Àlájì Ismail fún ìmọ̀ràn àti ọ̀rọ̀ ìyànjú ní gbogbo ìgbà tí mó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Ifáfitì Ìbàdàn, títún àwọn akẹgbẹ́ mi kọ́ lẹ́yìn ojoojúmọ́ náà ṣe okùnfà bí mo ṣe jáwé olúborí. Ipa kékeré kọ́ ni bàbá mi kó nínú ọ̀rọ̀ ayé mi pẹ̀lú ìṣírí tó ní Akin àti ọ̀rọ̀ ìyànjù, mó fi àṣeyọrí sọ orí Àlájì ISMAIL OYEDELE.
Ìwé kíkà ni mo kọ́kọ́ fi ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ mi kà ní ilé ìwé kí n tó wà gbé ìgbésẹ̀ Akin tó nípọn ní ọdún kẹrin tó kádìí ẹ̀kọ́. Mo máa n kàwé ṣáájú ìgbẹ̀kọ́ ní kíláàsì, máa sì fi ẹ̀kọ́ tí kò yé wọn lẹ́yìn ìgbẹ̀kọ́ nínú iyàrá ìkàwé, mo tún máa n gbàdúrá fún àṣeyọrí.
JUBRIL OYEDELE nìkan kọ́ ló ṣàṣeyọrí, ó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mọ́kànlá mìíràn. Ó tún jẹ ẹ̀bùn ó káre ọmọọdọ̀ rere ní ọ̀nà méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mìíràn. JUBRIL OYEDELE ní òun kò ní káàrẹ̀, òun yóò túbọ̀ kàwé dé ipò ọ̀mọ̀wé, òun yóò sì dá iléeṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ̀ sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, òun yóò la ipa rere ní àwùjọ ní àwùjọ rẹ̀.