Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti yan ọ̀gá àgbà titun fún ilé ìwé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna; Federal University of Applied sciences.
Matthew Kukah; ẹni tó jẹ́ wòlíì ìjọ Àgùdà ti ẹ̀ka Sokoto ló mú oyè náà jẹ kóró.
Olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí; Bayo Onanuga ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lonii.
Nínú rẹ̀ ló ti kọ ọ́ pé Wòlíì Matthew Kukah ni ọ̀gá àgbà titun fún ilé ìwé yìí gẹ́gẹ́ bíi ìyànsípò ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Bí a kò bá gbàgbé, kò tíì ju bí ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lọ tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pàṣẹ kí wọn ó gbẹ́sẹ̀ lé ilé ìwé gíga Nok kí wọn ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Federal University of Applied sciences.
A mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘ Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti pàṣẹ kí ilé ìwé gíga aládàáni Nok ótó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna ó paradà di ti ìjọba àpapọ̀ lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀.
Ìkéde yìí jáde láti ilé iṣẹ́ ààrẹ pé ìlérí tí ààrẹ ṣe ló ti mú ṣẹ yìí o, asọ̀rọ̀ṣẹ kan kò tún gbọdọ̀ máa sọ̀rọ̀ dànù.
Agbègbè Kachia ní Gúúsù ìpínlẹ̀ Kaduna ni ilé ìwé Nok yìí wà. Igbákejì ààrẹ; Kashim Shettima ló kó àwọn ìwé ìgbẹ́sẹ̀lé náà fún àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC ní ààfin ààrẹ tó wà ní Abuja.
Ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní Abuja ló pàṣẹ kí ilé ìwé gíga Nok náà ó di ti ìjọba àpapọ̀, ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi òǹtẹ̀ lùú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ààrẹ pàṣẹ kí wọ́n yí orúkọ ilé ìwé náà padà kúrò ní Nok varsity sí Federal University of Applied sciences lẹ́yẹòsọkà.
Shettima ṣe àfikún àlàyé pé ìṣèjọba tó wà lóde nísìn yìí kò fààyè gba rẹ́dẹrẹ̀dẹ.
Igbákejì ààrẹ kò ṣàì má dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹni bí ẹni èèyàn bí èèyàn tí wọ́n jẹ́ kí àtúntò náà ó wáyé, àwọn náà ni ajagunfẹ̀yìntì Martin Luther Agwai, Alàgbà Matthew Kukah, adájọ́ Kumai Akaahs àti sínétọ̀ Sunday Marshall.
Shettima gbé oríyìn fún àwọn èèyàn náà lórí ipa wọn láti mú kí àlàáfíà ó jọba ní agbègbè náà.
Bákan náà ló ké sí mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ láti mú àṣẹ ààrẹ ṣe nípa ṣísètò àbá ìṣúná fún sáà titun èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Ọ̀wẹ̀wẹ̀ ọdún yìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ tí yóò gbà wọlé.
Ó kù nìbọn ń ró, ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni nínú àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè tí ó ti ṣètò kalẹ̀ fún ìpínlẹ̀ Kaduna. Kódà, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ lórí àwọn títì ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna náà ganu sí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò ṣáà ní fárí lẹ́yìn olórí. Gómìnà Uba Sani dúpẹ́ ribiribi lọ́wọ́ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ilé ìwé gíga titun yìí. Gómìnà Sani wí pé òun dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Shettima fún mímọ̀ rírì iṣẹ́ tí òun ṣe ní ìpínlẹ̀ Kaduna. Ó ṣe àlàyé pé òun yóò tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ọ̀gá ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa, Ọ̀gágun Musa Christopher wí pé òṣùbà ràbàǹdẹ ló yẹ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ìgbésẹ̀ akọni yìí, ó wí pé ilé ìwé yìí kìí ṣe fún àǹfààní àwọn ará Kaduna nìkan, gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni yóò ní anfààní láti kàwé ní ilé ìwé ìjọba yìí.
Ọ̀gágun Musa fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní ìfẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí dọ́kàn, ẹ̀rí kan pàtàkì ni ilé ìwé yìí jẹ́.
Kìí ṣe òní ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti máa ń fi han àwọn ọmọ Nàìjíría pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, kìí sì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n, ìfẹ́ àtọkànwá ni ààrẹ ní sí wa’
Kò sí ìgbà tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ̀rọ̀ tí kò ní fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa dénú dénú, dọ́kàn dọ́kàn. Ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn ìfẹ́ òdodo ni ààrẹ máa ń sọ pé òun ní sí gbogbo ọmọ Nàìjíría, ó sì máa ń bèèrè fún irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ padà lọ́wọ́ wa.
Ààrẹ béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíría kó le tukọ̀ ìlú yìí já sí èbúté ògo, bákan náà ló fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ààyè fún ìwà àjẹbánu lásìkò ìṣèjọba tòun. Ó wí pé gbogbo ọ̀nà lòun yóò gbà latí gbógun ti ìwà àjẹbánu. Bákan náà ló sọ pé yóò ríi dájú pé ìwà àjẹbánu di ohun ìgbàgbé, kò ní sí ààyè fún ìwà jẹgúdújẹrá, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ajeegunjẹran kò ní anfààní nínú ìṣèjọba tó wà lóde nísìn yìí.