Lónìí ni Ààrẹ̀ Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà, Àlájì MUHAMMADU SA’AD ABUBAKAR Kéde pé oṣù tuntun ti yọ lẹ́yìn tí wọ́n ti kéde rẹ̀ lórílẹ̀ èdè SAUDI lọ́hùn-ún níbi tí ẹ̀sìn Mùsùlùmí ti ṣẹ̀ wá.
Sọ́ọ́tànù MUHAMMDU SA’AD ABUBAKAR ní àwẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu nítorí wọ́n ti kírun Áṣámú lálẹ́ àná káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ilé ìjọ́sìn àwọn Mùsùlùmí wà. Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà,ÀLÁJÌ MUHAMMADU SA’AD ABUBAKAR III sọ pé ‘kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi àsìkò ìtẹ́nu oṣù àwẹ̀ Ramadan yìí bẹ Allah láti fi àwọn olórí wa mọ̀nà, kí Allah kọ́ wọn mọ̀ ọ́n ṣe àgàgà àwọn olórí tí ìwà ìbàjẹ́ gbilẹ̀ lọ́kàn wọn pàápàá lásìkò tí gbogbo nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ lórílẹ̀ èdè wa. Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà, ÀLÁJÌ MUHAMMADU SA’AD ABUBAKAR III ní kí a bẹ Ọlọ́run fún wọn kí wọ́n lè è yí padà sí rere, ká yé é ṣépè fún wọn.
Ààrẹ ní kí gbogbo ọmọ ilẹ̀ yìí fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba fún ìlọ̀síwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ifáfitì Ìlọrin ní ìpínlẹ̀ Kwara ni Ààrẹ ti sọ èyí níbi ìpàdé pàtàkí tó wáyé láìpẹ́ yìí.
Àwọn gbajú-gbajà ọ̀tọ̀kùlú ló péjú-pésẹ̀ sí ibi ìpàdé náà. Àwọn bí i, ỌMỌỌBA LATEEF FAGBEMI (SAN), Ọ̀jọ́gbọ́n FRANCISCA OLADIP àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ààrẹ tún tẹ̀síwájú pé kí gbogbo àwọn Aṣíwájú ẹ̀sìn Mùsùlùmí máa fọn rere fún àwọn ọmọlẹ́yìn Ànọ́bì Mùọ́mọ̀dú pé kí wọ́n jẹ́ olùfẹ́ orílẹ̀-èdè wọn, kí wọ́n dìrọ̀ mọ́ ìbágbépọ̀ Àlàáfíà àwùjọ orílẹ̀-èdè yìí, kí gbogbo Mùsùlùmí yàgò fún kèéta, èmi-ò-jù-ọ́, ìwọ ò-jù-mí tó le è dá rúgúdù sílẹ̀, a sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Allah kó báwa dáwọ́ rúkèrúdò dúró lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà gbàá ní àdúà pé kí Allah gba gbogbo iṣẹ́ olóore wa, kí a sì rí èrè oṣù lámúlánà jẹ láyé àti lọ́run(ÀMÍN).
Ọ̀kan lára òpó ẹ̀sìn ìsìláàmù ni Àwẹ̀ gbígbà, ọ̀rànọyàn sì ni Allah ṣé é fún gbogbo àwọn Mùsùlùmí òdodo káàkiri gbogbo Àgbáńlá ayé.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ BAUCHI; JALALUDEEN MAINA, lókè ọya ní kí gbogbo ọmọ ilé ìwé gbélé wọn, kò sí ilé ìwé lílọ mọ́ láti ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù yìí títí di Ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹrin ọdún nítorí kí gbogbo olùkọ́ àti Akẹ́kọ̀ọ́ le è fi tọkàn tọkàn àti tara-tara gba àwẹ̀.
Mìnísítà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ BAUCHI; JALALUDEEN MAINA sọ pé èyí ti wà nínú àlàkalẹ̀ bí ètò ẹ̀kọ́ sáà kejì yìí yóò ti ṣe lọ láti ọjọ́ karùn ún oṣù kìíní ọdún yìí. Gbogbo ilé ìwé ìjọba àti Aládàáni bẹ̀rẹ̀ láti kíláàsì alákọ́bẹ̀rẹ̀ dé sẹ́kọ́ndírì títí dé ilé ẹ̀kọ́ gíga tàwọn olùkọ́ni, ilé ẹ̀kọ́ gbogbonṣe àti Ifáfitì.
Apá kejì ètò ẹ̀kọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu lẹ́yìn ọdún ìtunu àwẹ ọdún 2025.
Mínísítà JALALUDEEN MAINA wí pé : ‘Ní ìbẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ sáà kejì tí a bẹ̀rẹ̀ ní 5/1/2025 ni àwọn ti ṣe àlàkalẹ̀ náà sínú ètò ẹ̀kọ́ pé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ dáwọ́ dúró tàbí kí abala àkọ́kọ́ wá sí òpin ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Èrèlé 2025 látàrí oṣù àwẹ̀ tó gbòde báyìí. Ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹrin ọdún 2025 lẹ́yìn tí ọdún ìtunnu àwẹ̀ bá tí kásẹ̀ nílẹ̀ tán pátápátá.
Lánàá òde yìí náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina náà ṣe bí ìjọba BAUCHI ti ṣe lórí ìgbélé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ nínú oṣù àwẹ̀, ìjọba ní gbogbo ilé ẹ̀kọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ilé ìwé Alákọ́bẹ̀rẹ̀, Ṣẹ́kọ́ndírì, Ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni,Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonṣe àti Ifáfitì ni kí ilẹ̀kùn wọn wà ní títì pa kí àwọn ọmọ le è ráàyè fi tọkàn tọkàn àti tẹ̀mí tẹ̀mí kópa nínú oṣù àwẹ̀ Mùsùlùmí tó bẹ̀rẹ̀ lónìí ọjọ́ kínní,oṣù kẹta ọdún 2025.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina ní ìjìyà ń bẹ fún ilé ìwé Aládàání tó bá tàpá sí òfin yìí. Ìjọba tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún gbogbo lẹ́síìnì kéréje kéréje pé òfin yìí kò yọ wọ́n sílẹ̀, ìjọba ni òun kò ní fojú rere wo òbí, akẹ́kọ̀ọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ tó bá tàpá sí òfin ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina.
Ọ̀rọ̀ yìí ti dá awuyewuye sílẹ̀ lorí ẹ̀rọ ayélujára , àwọn kan ní ṣebí àwẹ̀ lẹ́ntì náà ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́, kí ló dé tí àwọn Gómìnà ààrin gbùngbùn tàbí ilẹ̀ íbò náà kò kéde ìsìnmi ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́? Àwọn kan tilẹ̀ ní ìran Hausa tún ti ń bá ẹlẹ́yà-mẹyà bọ níyẹn oooo, wọ́n tún fẹ́ gbé boko haram mìíràn kalẹ̀. Àwọn mìíràn ní abájọ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Hausa kò fi n pegede nínú ìdánwò WASSCE, NECO àti JAMB.
Àwọn kan tún ni ṣé àwọn ọmọ àti ọmọọmọ Gómínà náà wà lára Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ látàrí Àwẹ̀ Ramadan àbí òkè òkun ni wọ́n wà? Òfin ìsọnu yìí kò báwọn wí?

Àwọn kan tún ni ṣé àwọn ọmọ àti ọmọọmọ Gómínà náà wà lára Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ látàrí Àwẹ̀ Ramadan àbí òkè òkun ni wọ́n wà? Òfin ìsọnu yìí kò báwọn wí