Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ilé Așòfin Èkó ò gba ti Sanwó-olú tí í ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó lórí ipò tí ojú ọ̀nà ìgboro Èkó wà lọ́wọ́lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àkànṣe ojú ọ̀nà ni wọ́n patì tí wọn ò ṣe mọ́. Wọ́n sì wá ń pe ìjọba Sanwó-olú kí ó jí gìrì sí ìpèníjà tó kojú àwọn ará ìlú lórí iṣẹ́ àkànṣe ojú ọ̀nà náà.
Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjíròrò tó fa kíki, wọ́n gbà pé kí àwọn ránṣẹ́ sí Kọmíṣánnà tó wà fún ètò iṣẹ́ àti àwọn kọñgílá tí wọ́n gbé iṣẹ́ ojú ọ̀nà náà fún láti wá to tẹnu wọn lórí ìdí tí àwọn ọ̀nà náà fi di àșepatì bí ejò àìjẹ.
Àwọn aṣòfin náà gba àwọn lájọlájọ tí ọ̀rọ̀ ojú ọ̀nà náà kàn, pé kí wọ́n gbé ìlànà tó gíríkì kalẹ̀ lórí bí wọn ó ṣe parí àwọn àkànṣe iṣẹ́ náà, kí wọ́n sì pèsè ààbò tó péye fún àwọn olùgbé ibi tí ọ̀rọ̀ náà kàn.
Gẹ́gẹ́ bí àfẹnukò wọn, ilé sọ pé kí àwọn kọñgílá tó ti gba àsan-ánlẹ̀ ìdá ọgọ́ta sí ìdá àádọ́rin owó iṣẹ́, kí wọ́n tètè gbé ìlànà kalẹ lórí bí wọn ó ṣe tètè parí iṣẹ́ àwọn àkànṣe náà lójú ọmọ.
Ní àkókò ìjókòó ilé, abẹnugan ilé Așòfin, ìyẹn Mojisola Meranda, pe gómìnà Sanwó-olú láti pàṣẹ fún ilé iṣẹ́ ètò ìrìn à láti tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà lórí òpópónà Bọ́lá Ahmed Tinubu lọ́nà Igbogbo-Baiyeku tí wọ́n ti patì tipẹ́.
Èyí nìkan kọ́, ó tún pàṣẹ fún àwọn aṣòfin pé kí wọ́n padà lọ sí agbègbè wọn, kí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àkójọ pọ̀ àwọn ọ̀nà gbogbo tí wọ́n ti patì ní agbègbè wọn, kí wọ́n sì fi í ṣọwọ́ sí àwọn ilé – iṣẹ́ ìjọba tó bá yẹ láti tètè mú wọn gbé ìgbésẹ̀.