Gómìnà Ademola Adeleke tíí ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kọ orin níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́ JP2025, ìgbéyàwó ọmọ gbajúgbajà òṣèrénìnrin nnì; Iyabo Ojo tó wáyé ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù yìí.
Gbọ̀gán Five Palms tó wà ní Oniru, ìpínlẹ̀ Èkó ni ayẹyẹ ìgbéyàwó náà ti wáyé.
Gbogbo àwọn òṣeré, olórin àti àwọn gbajúmọ̀ ojútópawó ló péjú pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà.
Níbi ayẹyẹ yìí ni Gómìnà Adeleke ti kọ orin fún tọkọtaya Priscilla àti Juma lórí ìtàgé.
Lára àwọn ojú tó pawó tí a rí níbẹ̀ ni Toyin Abraham; ọ̀rẹ́ ìyá ìyàwó tímọ́tímọ́, Wunmi Toriola, Mide Martins àti Ọkọ rẹ̀, Papaya, Enioluwa, Funke Akindele, Eniola Badmus, Sotayo Gaga, Mercy Aigbe àti àwọn òṣeré tíátà mìíràn.
Kamo state ò gbẹ̀yìn, Erekere wà níbẹ̀, Pretty Fola, Cute Abiola, Peller àti Jarvis náà mójú ajé kan onísọ̀.
Ó ṣe pàtàkì láti dárúkọ àwọn olórin tó kọrin níbẹ̀ ni Segun Johnson, 9ice àti Kiss Daniel àti àwọn ìlúmọ̀ọ́nká mìíràn bẹ́ẹ̀.
Ìgbéyàwó náà dùn, a kò le ròyìn rẹ̀ tán lónìí. Kódà, JP2025 yìí ni àwọn èèyàn pè ní ìgbéyàwó ọdún 2025 yìí, wọ́n ní kò sí ìgbéyàwó kan tó tún le dùn ju èyí lọ.
** ** * **** ***** *** *** ***
KÌÍ ṢE ỌKỌ̀ AKỌ́WỌ̀Ọ́RÌN AYA ÀÀRẸ LÓ PA ỌMỌ NÁÀ O – ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ .
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ wa ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Òndó tí fèsì sí ẹ̀sùn tí àwọn èèyàn fi kan ìyàwó ààrẹ lórí àwọn ìkànnì ayélujára gbogbo pé ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn rẹ̀ sẹkú pa ọmọdé kan ọmọ ọdún méje ní ìlú Àkúrẹ́ tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Òndó, wọ́n ní irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn yìí nítorí pé ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn aya ààrẹ kọ́ ló pa ọmọ náà o.
Ìyàwó ààrẹ wa; Oluremi Tinubu lọ sí Àkúrẹ́ lỌ́jọ́bọ láti pín àwọn ohun èlò fún àwọn agbẹ̀bí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ẹ̀sùn náà kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, ète àti tàbùkù aya ààrẹ lásán ni.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òndó: Olushola Ayanlade ló fi ọ̀rọ̀ náà léde pé ìkànnì Sahara reporters fi ìròyìn tí kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ náà léde pé ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn aya ààrẹ wa sẹkú pa ọmọdé náà, Olushola wí pé ìwádìí tí àwọn ṣe fi hàn pé ọkọ̀ Lexus kan ló gbá ọmọ náà tó sì sá lọ, wọ́n ní àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tí ó ṣẹlẹ̀ fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé ọkọ̀ Lexus ló pa ọmọ náà kìí ṣe ọ̀kankan nínú àwọn ọkọ̀ akọ́wọ̀ọ́rìn aya ààrẹ.
Olushola tẹ̀síwájú pé ìròyìn òfegèé lásán ni Sahara reporters gbé jáde nitori pé àwọn òbí ọmọ náà gan-an sọ pé ọkọ̀ Lexus ló gbá ọmọ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti ṣe àbẹ̀wò sí àwọn òbí ọmọ náà, àwọn sì ti ṣe ìlérí láti wá awakọ̀ Lexus náà jáde.
MÍLÍỌ̀NÙ MẸ́WÀÁ NÁÍRÀ NI MO PÀDÁNÙ NÍNÚ CYBEX TÓ FORÍ ṢÁNPỌ́N – TAYE CURRENCY
Gbajúgbajà olórin fujì nnì; Taye Currency kábàámọ̀ lórí ètò sogúndogójì tó forí ṣánpọ́n náà, ó wí pé mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni òun pàdánù sínú rẹ̀.
Taye Currency wí pé ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́ ló fi CYBEX lọ òun, ó ní lọ́jọ́ náà, ìyẹn ọjọ́ kìíní, oṣù Igbe ni Lateef wá sílé òun wá sọ fún òun pé alámòójútó òun ti gba owó tirẹ̀, Alaba àti Small London náà ti rí owó wọn gbà.
Mílíọ̀nù kan ó lé díẹ̀ ni Alaba gbé lé CYBEX, Muka gbé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé e, Sodiq náà gbé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀rín-ó-dín-àádọ́ta náírà lée nígbà tí Lateef gbé mílíọ̀nù kan àti irinwó ẹgbẹ̀rún lée, gbogbo wọn sì ni wọ́n rí owó wọn gbà.
Èyí ló mú kí Taye Currency náà ó fi inú tán CYBEX tó fi gbé mílíọ̀nù mẹ́wàá lée tán tó sì páfúká.
Òfò yìí káa lára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi gbé gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ náà ṣepé pé bí wọ́n bá kúu re wọn ò ní sùn un re nítorí pé jẹ́jẹ́ lòun jókòó tí wọ́n mú CYBEX wá fún òun.
Àjọ JAMB ti gbé èsì ìdánwò aṣegbaradì jáde lónìí.
Àjọ tó ń ṣe ìdánwò àṣewọ ilé ìwé gíga nílẹ̀ yìí JAMB ti fi èsì ìdánwò aṣegbaradì MOCK ọdún yìí léde ní òní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Igbe.
Wọ́n sọ bí àwọn olùkópa náà ó ṣe rí èsì ìdánwò náà nípa fífi nọ́ḿbà tí wọ́n fi ṣe ìforúkọsílẹ̀ tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí nọ́ḿbà àyàsọ́tọ̀.
A TI ṢE ÌDÁMỌ̀ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TÓ GBA OWÓ LỌ́WỌ́ ARÁ CHINA NÁÀ – ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ìdójútì tí àwọn ọlọ́pàá kan hù nínú fọ́nrán kan tó gbòde ní èyí tí ọmọ orílẹ̀-èdè China kan ti ń há owó fún wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé gbogbo àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n hàn nínú fọ́nrán náà ni àwọn ti ṣe ìdámọ̀ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan tí àwọn yóò sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí; Olumuyiwa Adejobi bu ọwọ́ lù la ti kàá pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá jẹ́ ẹ̀ka kan tó ní iyì àti òtítọ́, wọ́n ní àwọn kìí ṣe alábòsí tàbí alábọ̀dè, ìgbẹ̀kẹ̀lé tí àwọn èèyàn ní nínú àwọn kò gbọdọ̀ já sófo.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ọlọ́pàá tí a rí nínu fọ́nrán náà ti lòdì sí ohun tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wà fún, ìwà náà jẹ́ ìwà ìdójútì ńlá nítorí náà, wọn yóò jẹ́ jìyà ohun tí wọ́n ṣe yìí.
Wọ́n ní àwọn ti kó àwọn ọlọ́pàá náà lọ fún ìjìyà wọn báyìí pé èyí yóò jẹ́ kí wọn ó mọ̀ pé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ṣe é tàbùkù. Wọ́n kọ láti sọ irú ìjìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn ọlọ́pàá náà nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bèèrè.
Discussion about this post