Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ọ̀șun ti kojú ìșòro ńlá tó sì ń fa kò-bà-ò-le lágbo wọn. Ọ̀rọ̀ yìí kò ní nǹkan án ṣe pẹ̀lú Ọ̀gbẹ́ni Arẹ́gbẹ́sola tó ti fínnú-fíndọ̀ fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ láìpẹ́ yìí o. Ìjàgùdù tó ń rú agbo ẹgbẹ́ òṣèlú APC pọ̀ gùdùgùdù báyìí ni àtimọ ẹni tí yóò gbé àpótí díje dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun nínú ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó lórúkọ nínú ẹgbẹ́ náà ni inú wọn kò dùn sí gómìnà àná, Ọ̀gbẹ́ni Adegboyega Oyetọ́lá tó ti du ipò náà lẹ́ẹ̀méjì, àmọ́ tó jẹ lẹ́ẹ̀kan tó tún ń ṣojú bákan-bákan láti tún dù ú lẹ́ẹ̀kẹ́ta. Wọ́n ń gbà á bí ẹní gba igbá ọtí láàárín ara wọn pé níṣe ló yẹ kí Oyetọ́lá fààyè sílẹ̀ fún ẹlòmíràn tó tún kún ojú òṣùwọ̀n láti díje. Bákan náà ni igun mìíràn ń pariwo pé kí wọ́n tún gbé e lọ sí ẹkùn tí kò tí ì ní irú àǹfààní bẹ́ẹ̀. Ẹnìkan kìí ṣáà jẹ kílẹ̀ ó fẹ̀.
Igun kan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí a mọ̀ sí Ẹgbẹ́ ìtẹ̀síwájú Apapọ̀ ìlú Òṣogbo – Òṣogbo Progressive Alliance ( OPA) rọ ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé kó jẹ́ kí wọ́n gbé ìyànsípò náà lọ sí ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn Ọ̀ṣun ( West Senetorial District). Bákan náà ni wọ́n pàrọwà sí alága gbogbo-gbòò ẹgbẹ́, Abdulahi Ganduje àti akọ̀wé àpapọ̀, Ọlọ́lá Ajíbọ́lá Basiru pé kí wọ́n fọwọ́ sí ẹlẹ́kùn-jẹkùn yìí, kí wọ́n sì gbà á wọlé.
Adémọ́lá Kadiri; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ikọ̀ yìí pe ìpàdé àwọn oníròyìn ní Òṣogbo, ó sì sọ pé tí wọ́n bá tẹ̀lé ìmọ̀ràn awon OPA, yóò yanjú àìgúnrégé tó wà nínú ẹgbẹ́ náà ní ìpínlè Ọ̀ṣun. Èyí yóò sì jẹ́ kí ó rọrùn wọ̀ọ̀kù-wọọku fún ẹgbẹ́ APC láti borí ìbò tó ń bọ̀ ní ọdún 2026.
Ikọ̀ yìí tún tẹnu mọ́ ọn pé láti nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ẹkùn tí a ń sọ yìí kò tí ì gbé enikan kalẹ̀ rí sí ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; bẹ́ẹ̀ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ nínú ẹbí APC ni wọ́n. Ó ní títí di àsìkò yìí, ẹgbẹ́ ò tí ì fẹnu kò lórí ẹnìkan pàtó tí wọ́n máa gbé kalẹ̀. Àwọn kan tọ́ka sí àwòrán Oyetọ́lá tí wọ́n ń lẹ̀ káàkiri ìlú Òṣogbo pé kí wọ́n má kà á sí ọ, pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn mọ̀dàrú ni o. Bákan náà ni a tún rí ikọ̀ mìíràn nínú ẹgbẹ́ yìí kan náà – Àpapọ̀ Ikọ̀ Onítẹ̀síwájú ní Ọ̀ṣun náà fara mọ́ kí wón lo ẹlẹ́kùn-jẹkùn láti yan ẹni tí yóò gbégbá gómìnà lórúkọ ẹgbẹ́ APC Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Ẹgbé òṣèlú APC ti wá dàbí ọ̀rọ̀ adìyẹ tó bà lé okùn, ara kò rọ ẹgbẹ́, ara kò rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́, ara kò tún rọ àwọn aráàlú.
Ọjọ́ wo ni El-Rufai ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀? Tó kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ǹjẹ́ ẹ tiẹ̀ gbọ́ ohun tó sọ? El-Rufai mà wí pé Buhari mọ̀ nípa bí òun ṣe kúrò. Ó ṣe àlàyé pé ‘òun ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú SDP níbi tí òun yóò ti ní àǹfààní àti gòkè àgbà.
Ẹ̀sùn tó fi kan ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni pé wọn kọ iyán òun kéré, wọn ò tún fewé bò ó, ó wí pé òun wà lára àwọn tó pilẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun dalẹ́ láì mọ̀ pé ṣe ni wọn yóò já òun kulẹ̀. Ó ní àwọn adarí ẹgbẹ́ náà kò ka àmọ̀ràn òun kún rárá, gbogbo ọ̀rọ̀ òun kò tà létí wọn, ẹ̀yin náà sì mọ̀ pé ìlú tí wọn kò bá ti fẹ́ni, a kìí dárin níbẹ̀. Ìdí rèé tí ó fi yapa lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú SDP pẹ̀lú èrò pé yóò gbe òun.
El-Rufai ṣe ìlérí pé òun yóò kó àwọn èèyàn jọ láti dìbò tako ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti wá fèsì báyìí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò le mu àwọn lómi nítorí pé balùwẹ̀ rẹ̀ tó fẹ́ kún ju odò lọ, irọ́ lásán ni’
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé El-Rufai wí pé Buhari mọ̀ nípa bí òun ṣe kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní èyí tó jẹ́ kí àwọn èèyàn ó wí pé bóyá Buhari náà ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí kò sọ, Buhari fúnra rẹ̀ fèsì pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, ó wí pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lòhun tọ̀kàntara.
Muhammad Buhari wí pé òun kò le kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC láíláí, kò sí ibi tí òun ń lọ, ó ní òun ń gbaradì fún ètò ìdìbò ọdún 2027 ní èyí tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò díje du ipò ààrẹ. Ààrẹ àná; Muhammad Buhari wí pé òun yóò fi gbogbo ara òun jìn fún ìdìbò náà kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ó le jáwé olúborí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ṣetán àti fi ipò sílẹ̀ ní odún 2027, ẹgbẹ́ òṣèlú SDP ń múra láti gba ìṣèjọba, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà ń múra láti yí APC lágbo dà síná, ọ̀rọ̀ wá di fà-n-fà láàrin àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ́ẹ̀ta yìí, ta ni yóò fàgbà han ẹnìkan báyìí?
Ẹgbẹ́ òṣèlú SDP nìkan ló ṣì ń tòrò lásìkò yìí, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò fi taratara fara rọ àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ewé ojú omi àsìkò yìí.
Wàhálà wà ní gbogbo ìpele ìṣèjọba nínú ẹgbẹ́ náà, bí wọ́n ṣe ń fa ti Obasa ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ni wọ́n ń fa ti Oyetola ní ipò Gomina Ọ̀ṣun, àwọn èèkàn kan náà ṣetán láti kojú Tinubu nínú ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà.
Ìlẹ̀kẹ̀ má já sílé má já sóde, ibo lẹ rò pé yóò já sí?